Ọ̀nà 5
Jẹ́ Kí Olúkúlùkù Mọ Iṣẹ́ Táá Máa Ṣe Nínú Ilé
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì? Ẹní bá ti kúrò lọ́mọdé á mọ̀ pé kò sí ni kéèyàn máà níṣẹ́ tá a máa ṣe déédéé nínú ilé. Lára àwọn nǹkan téèyàn ń ṣe déédéé ni iṣẹ́ àti ìjọsìn, kódà eré ìdárayá ò gbẹ́yìn. Bí ìgbà táwọn òbí ń fi ohun tó dáa du àwọn ọmọ wọn ni bí wọn ò bá kọ́ wọn béèyàn ṣe máa ń ṣètò àkókò àti béèyàn ṣe ń lo irú àkókò bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó yẹ. Àmọ́ ṣá o, “ìwádìí ti fi hàn pé bí ọmọ bá ní ìlànà tó ń tẹ̀ lé, tó sì ti ṣètò bí yóò ṣe máa lo àkókò ẹ̀, ọkàn irú ọmọ bẹ́ẹ̀ á balẹ̀, á ní ìkóra ẹni níjàánu, kò sì ní máa wo aago aláago ṣiṣẹ́,” gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé Laurence Steinberg, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìrònú òun ìhùwà ṣe sọ.
Ìṣòro tó wà ńbẹ̀: Kìràkìtà nilé ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn òbí máa ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, nítorí náà, ó lè jẹ́ pé àkókò díẹ̀ ló máa ń ṣẹ́ kù tí wọ́n máa ń rí lò déédéé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Báwọn òbí bá ń gbé ìlànà kalẹ̀ nípa iṣẹ́ táwọn ọmọ á máa ṣe déédéé nínú ilé, wọn ò gbọ́dọ̀ gba gbẹ̀rẹ́, wọ́n sì ní láti múra tán láti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ nítorí pé ó lè máà kọ́kọ́ rọrùn fún wọn láti máa kọ́wọ́ ti irú ìṣètò bẹ́ẹ̀.
Ohun tó lè ràn yín lọ́wọ́: Fi ìlànà tó wà nínú ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò pé ká jẹ́ “kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́ríńtì 14:40) Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọmọ bá ṣì kéré, ó ní àkókò pàtó táwọn òbí wọn máa ń fẹ́ kí wọ́n lọ sùn. Àmọ́, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ tìpá tìkúùkù. Màmá àwọn ọmọbìnrin méjì kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Gíríìsì, ìyẹn Tatiana, sọ pé: “Táwọn ọmọ bá ti wà lórí ibùsùn, mo máa ń fọwọ́ pa wọ́n lára mo sì máa ń sọ ohun tí mò ń ṣe nílé lásìkò tí wọ́n wà nílé ìwé fún wọn. Lẹ́yìn náà ni màá wá sọ pé káwọn náà sọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nílé ìwé fún mi. Ara wọn á balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Wọ́n sì sábà máa ń sọ tinú wọn fún mi.”
Bàbá àwọn ọmọbìnrin náà, Kostas, máa ń ka ìtàn fún wọn. Ó sọ pé: “Wọ́n máa ń sọ èrò wọn nípa ìtàn náà, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni ìjíròrò wa máa ń sún kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ lọ sórí ohun tó ń dùn wọ́n lọ́kàn. Kì í yá wọn lára láti sọ tinú wọn bí mo bá wulẹ̀ ní kí wọ́n sọ ohun tó ń dùn wọ́n lọ́kàn fún mi.” Àmọ́ ṣá o, báwọn ọmọ bá ṣe ń dàgbà sí i, á dára kẹ́ ẹ yí àkókò tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa sùn padà séyìí tó bá ọjọ́ orí wọn mu. Síbẹ̀ náà, bẹ́ ò bá yé wà pẹ̀lú wọn bí wọ́n bá fẹ́ lọ sùn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣì máa bá a nìṣó láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún yín.
Láfikún sí ìyẹn, ó bọ́gbọ́n mu kí tọkọtaya àtàwọn ọmọ máa jẹun pa pọ̀, ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́. Láti fìdí àṣà yìí múlẹ̀, ó ṣeé ṣe kí àkókò tẹ́ ẹ̀ ń jẹun máa yí padà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Charles, tó jẹ́ bàbá àwọn ọmọbìnrin méjì, sọ pé: “Ìgbà míì wà tí mo máa ń pẹ́ dé látibi iṣẹ́. Ìyàwó mi lè ti báwọn ọmọ wá nǹkan tí wọ́n á máa fi panu kí n tó dé, àmọ́ ó máa ń rí i pé kò séyìí tó tíì sùn nínú wọn ká bàa lè jẹun pà pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. A máa ń sọ̀rọ̀ nípa bí iṣẹ́ ṣe lọ sí, a máa ń yẹ ẹsẹ ìwé ojoojúmọ́ wò, lẹ́yìn náà la ó sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá bá pàdé, tá a ó sì jọ rẹ́rìn-ín pa pọ̀. Ẹnu mi ò ní gbàròyìn bí mo bá ní kí n máa sọ bí ìṣètò yìí ṣe mú kí ìdílé wa jẹ́ ilé aláyọ̀ tó.”
Kí ìgbésẹ̀ yìí bàa lè mọ́ ẹ lára, má ṣe jẹ́ kí lílé àwọn nǹkan tara dí ẹ lọ́wọ́ láti máa wà pẹ̀lú ìdílé ẹ déédéé. Fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sọ́kàn “pé kí ẹ lè máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.
Kí tún làwọn òbí lè ṣe káwọn àtàwọn ọmọ lè túbọ̀ máa jùmọ̀ sọ̀rọ̀ déédéé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]
“Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́ríńtì 14:40