ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/08 ojú ìwé 30
  • Ẹ̀kọ́ Èké àbí Òótọ́ Pọ́ńbélé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Èké àbí Òótọ́ Pọ́ńbélé?
  • Jí!—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Irọ́ Ni Àbí Òótọ́?—Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ẹ̀kọ́ Èké Kìíní: Ẹ̀mí Èèyàn Kì Í Kú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Bá Ohun Tí Bíbélì Sọ Mu?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣẹ́ni Gidi ni Ádámù àti Éfà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 1/08 ojú ìwé 30

Ẹ̀kọ́ Èké àbí Òótọ́ Pọ́ńbélé?

Tímótì, tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ, fún àwọn tó fẹ́ máa sin Ọlọ́run tòótọ́ nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n má ṣe máa fetí sí “àwọn àsé ọ̀rọ̀” àti “àwọn ìtàn àròsọ.” (1 Tímótì 1:3, 4, ìtumọ̀ Byington) Ṣé irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣì wúlò lónìí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni, ìdí ni pé àwọn èrò tí kò tọ̀nà nípa Bíbélì àti nípa àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ ń gbilẹ̀ lóde òní, èyí ò sì jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ mọ́. Díẹ̀ rèé lára èrò èké tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa Bíbélì. Bí ìwọ fúnra rẹ bá kíyè sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, wàá mọ èyí tó jẹ́ ẹ̀kọ́ èké àtèyí tó jẹ́ òótọ́ pọ́ńbélé.

◼ Ẹ̀kọ́ Èké: Àwọn iṣẹ́ ìyanu tó wà nínú Bíbélì ò lè ṣeé ṣe.

Òótọ́ Pọ́ńbélé: Ọ̀pọ̀ nǹkan làwa ẹ̀dá èèyàn ò tíì mọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Kò sí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó lè ṣàlàyé gbogbo ohun tó fà á tó fi jẹ́ pé tá a bá ju ohunkóhun sókè, ó máa pàpà wálẹ̀. Wọn ò tiẹ̀ lè ṣàlàyé ohun tó para pọ̀ di àwọn nǹkan tín-tìn-tín tí wọ́n ń pè ní átọ́ọ̀mù, ká máà ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ohun tó mú ká máa ka àkókò lọ́nà tá à ń gbà kà á báyìí. “Ìwọ ha lè rídìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, tàbí ìwọ ha lè rídìí ààlà ìpẹ̀kun Olódùmarè?” (Jóòbù 11:7) Níwọ̀n bí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ti jẹ́ àwámáridìí, àwọn tó ti mọṣẹ́ sáyẹ́ǹsì dójú àmì kì í fẹ́ sọ pé ohun kan ò ṣeé ṣe.

◼ Ẹ̀kọ́ Èké: Ẹ̀sìn ló yàtọ̀, Ọlọ́run kan náà ni gbogbo wa ń sìn.

Òótọ́ Pọ́ńbélé: Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:31, 32) Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kan náà ni gbogbo ẹlẹ́sìn ń ké pè, ó dájú pé kò sẹ́ni tó máa nílò ìtúsílẹ̀. Kódà, Jésù kọ́ni pé àwọn tó wà ní “ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè” ò tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ tó ń gba ọ̀nà gbígbòòrò.—Mátíù 7:13, 14.

◼ Ẹ̀kọ́ Èké: Gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sọ́run.

Òótọ́ Pọ́ńbélé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà. Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀. Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 37:11, 29, 34) Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] olóòótọ́ èèyàn nìkan ló ń lọ sọ́run. Ọlọ́run ti yàn wọ́n láti “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 4.

◼ Ẹ̀kọ́ Èké: “Májẹ̀mú Láéláé” ò wúlò fáwọn Kristẹni mọ́.

Òótọ́ Pọ́ńbélé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.” (2 Tímótì 3:16, 17) “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Ìsọfúnni tó jíire nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ṣèlérí wà nínú “Májẹ̀mú Láéláé,” ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, èyí ló sì jẹ́ ká gba àwọn ohun tó wà nínú “Májẹ̀mú Tuntun,” ìyẹn Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì gbọ́.

◼ Ẹ̀kọ́ Èké: Ìtándòwe ni púpọ̀ nínú àwọn ohun tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì títí kan ìtàn Ádámù àti Éfà.

Òótọ́ Pọ́ńbélé: Nígbà tí Lúùkù máa kọ ìtàn ìlà ìdílé tí Jésù ti wá sínú ìwé Ìhìn Rere, orí Ádámù ló ti bẹ̀rẹ̀. (Lúùkù 3:23-38) Tó bá jẹ́ òótọ́ ni pé ìtándòwe ló wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, ibo gan-an ni Lúùkù parí títo orúkọ àwọn tó ti gbé ayé rí lóòótọ́ sí, ibo ló sì ti wá bẹ̀rẹ̀ sí í to orúkọ àwọn ẹni inú ìtándòwe? Jésù tó tiẹ̀ ti wà lọ́run kó tó wá sáyé pàápàá gba ohun tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì gbọ́, ó sì gbà pé òótọ́ ni ìtàn Ádámù àti Éfà tó wà níbẹ̀. (Mátíù 19:4-6) Nígbà náà, tá a bá sọ pé ìtándòwe ló wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, a jẹ́ pé a ò gba Jésù àti ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kọ Bíbélì gbọ́ nìyẹn.—1 Kíróníkà 1:1; 1 Kọ́ríńtì 15:22; Júúdà 14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́