ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 11/1 ojú ìwé 4
  • Ẹ̀kọ́ Èké Kìíní: Ẹ̀mí Èèyàn Kì Í Kú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Èké Kìíní: Ẹ̀mí Èèyàn Kì Í Kú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ọkàn?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ọkàn Gẹ́gẹ́ Bí Bíbélì Ṣe Fi Í Hàn
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ọkàn
    Jí!—2016
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 11/1 ojú ìwé 4

Ẹ̀kọ́ Èké Kìíní: Ẹ̀mí Èèyàn Kì Í Kú

Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Ìwé The New Encyclopædia Britannica (1988), ìdìpọ̀ 11 sọ lójú ìwé 25 pé, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí gbà pẹ̀lú àwọn ará Gíríìkì pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú, wọ́n sì sọ pé Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí yìí sí ara èèyàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Kí ni Bíbélì sọ? ‘Ó pa dà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.’​—Orin Dáfídì 146:4, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Ṣé àwa èèyàn ní “ẹ̀mí” tó máa ń wà láàyè lẹ́yìn tí ara wa bá ti kú? Bíbélì kọ́ni pé Ọlọ́run fi ipá ìwàláàyè tàbí ẹ̀mí sínú èèyàn àti ẹranko, èémí ló sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí lè máa ṣiṣẹ́. Ẹ̀mí yìí ló ń gbé ara ró. Àmọ́ tí ara èèyàn tàbí ti ẹranko kò bá mí mọ́, tí kò sì lè mú kí ẹ̀mí tí Ọlọ́run fi sínú rẹ̀ máa ṣiṣẹ́, èyí á yọrí sí ikú. Wọn kò sì ní mọ ohunkóhun mọ́.​—Jẹ́nẹ́sísì 3:​19; Oníwàásù 3:​19-​21; 9:5.

Látìgbà tí àwọn èèyàn ti gbà gbọ́ pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú ni onírúurú ìbéèrè ti ń jẹ yọ, lára irú ìbéèré yìí ni: Ibo ni ẹ̀mí tó kúrò ní ara èèyàn máa ń lọ lẹ́yìn tí onítọ̀hún bá kú? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn burúkú lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kú? Nígbà tí àwọn tó ń pera wọn ní Kristẹni gba ẹ̀kọ́ èké yìí gbọ́ pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú, èyí mú kí wọ́n gba ẹ̀kọ́ èké míì láyè, ìyẹn sì ni ẹ̀kọ́ nípa iná ọ̀run àpáàdì.

Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Oníwàásù 3:19; Mátíù 10:28; Ìṣe 3:23

ÒKODORO ÒTÍTỌ́:

Bí èèyàn bá ti kú, onítọ̀hún ti ṣaláìsí nìyẹn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́