Ọjọ́ Ti Pẹ́ Táwọn Èèyàn Ti Mọ Orúkọ Ọlọ́run
DÁFÍDÌ, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù tó wà nínú Bíbélì, kọ ọ́ lórin pé: “Ṣe ni èmi yóò máa fi orin yin orúkọ Ọlọ́run.” Dáfídì mọ orúkọ Ọlọ́run dájú, ó sì wá fi orin yìn ín pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà . . . Ìbùkún sì ni fún orúkọ rẹ̀ ológo.” (Sáàmù 69:30; 72:18, 19) Jèhófà lọ̀pọ̀ mọ orúkọ Ọlọ́run sí lédè Yorùbá. Ọ̀rọ̀ Hébérù kan, ìyẹn יהוה, ni wọ́n tú sí Jèhófà, ó sì fara hàn ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [7,000] ìgbà nínú Bíbélì.
Láwọn ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan sẹ́yìn, orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn láwọn ibòmíì yàtọ̀ sínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, fún ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ lédè Látìn, ìyẹn Benedictus Sit Iehova Deus, tó túmọ̀ sí “Ògo Ni fún Jèhófà Ọlọ́run,” ti wà lára àwọn owó ẹyọ tí wọ́n ń ná lórílẹ̀-èdè Switzerland [1]. Kódà, láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ó ju ẹgbẹ̀rún ìgbà lọ tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn lédè Hébérù àti Látìn lára onírúurú owó ẹyọ, àwọn nǹkan míì tí wọ́n ń lò bí owó, àtàwọn àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n ń gbà nígbà ìdíje.
Tó o bá wo àwọn àpẹẹrẹ owó ẹyọ tá a tò sójú ìwé yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, wàá rí i pé ọ̀pọ̀ ló ti ń lo orúkọ Ọlọ́run. Kí ló jẹ́ kí orúkọ Ọlọ́run di nǹkan tí gbogbo èèyàn wá mọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta báyìí?
Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ń Lo Orúkọ Ọlọ́run?
Ìjà ẹ̀sìn tó wáyé ní nǹkan bí irínwó [400] ọdún sẹ́yìn láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì àtàwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì tàn dé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù. Díẹ̀ lára àwọn tó ń gbé láwọn ìpínlẹ̀ kan tó wà lábẹ́ orílẹ̀-èdè Sípéènì sá lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ìjà ẹ̀sìn yìí dogun abẹ́lé. Ohun tí wọ́n bá kọ sára owó ẹyọ àtàwọn àwòrán míì ni wọ́n fi ń sọ ẹ̀yìn ẹni tí Ọlọ́run wà fúnra wọn.
Bí Wọ́n Ṣe Lo Orúkọ Ọlọ́run
Àwọn alágbẹ̀dẹ tó ń kọ nǹkan sára owó ẹyọ nígbà yẹn máa ń lo àwọn lẹ́tà Hébérù mẹ́rin fún orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà. JHVH tàbí YHWH ni wọ́n lò fáwọn lẹ́tà náà lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́ ní gbogbo àgbègbè náà kò sẹ́ni tó lè ka èdè Hébérù, àwọn alágbẹ̀dẹ tó ń kọ nǹkan sára owó ẹyọ pàápàá ò lè kà á. Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàdàkọ àwọn lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run yìí ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ọ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà.
Nígbà tó fi máa di ọdún 1568, Ìjọba Sweden ti yọ́ orúkọ Ọlọ́run sára owó ẹyọ wọn [2], ìjọba Scotland náà sì ṣe bíi tiwọn lọ́dún 1591. Nígbà tó máa fi di ọdún 1600, Ọba Charles Kẹsàn-án ti ìlú Sweden ti kọ orúkọ Ọlọ́run lóríṣiríṣi ọ̀nà sára àwọn owó ẹyọ ìlú náà, irú bí Ihehova, Iehova, àti Iehovah [3]. Ó mú kí wọ́n fi góòlù ṣe ọ̀kan lára àwọn owó ẹyọ náà. Owó náà níye lórí débi pé ó ju owó tí lébìrà tó bá ṣiṣẹ́ fóṣù mẹ́rin ń gbà lọ!
Láàárín ọdún 1588 sí ọdún 1648 tí Christian Kẹrin fi jọba nílùú Denmark àti Norway, nǹkan tó ju ọgọ́ta oríṣiríṣi owó ẹyọ tó ní orúkọ Ọlọ́run lára làwọn èèyàn ń pè ní owó ẹyọ Jèhófà. Nígbà tó máa fi di nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, owó tí wọ́n ń pè ní “owó ẹyọ Jèhófà” ti wà lára owó ẹyọ tí wọ́n ń ná nílùú Poland àti Switzerland. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ná an nílùú Jámánì pẹ̀lú.
Kí ìjà ẹ̀sìn tó wá di ogun abẹ́lé, èyí tí wọ́n jà fún ọgbọ̀n ọdún nílùú Yúróòpù, tó parí lọ́dún 1648 àwọn owó ẹyọ tí wọ́n ń pè ní “owó ẹyọ Jèhófà” ti wá di nǹkan tó gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta. Nígbà tí Ọba Gustav Kejì Adolph ti ilẹ̀ Sweden borí nínú ìjà ẹ̀sìn tó wáyé lábúlé Breitenfeld, nílùú Jámánì lọ́dún 1631, ó pàṣẹ pé kí wọ́n yọ́ lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run yẹn sára àwọn owó ẹyọ kan [4]. Ìlú Erfurt, Fürth, Mainz àti Würzburg ni wọ́n sì ti ń ṣe àwọn owó wọ̀nyí. Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn ìlú tó fara mọ́ ọba ilẹ̀ Sweden náà bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ orúkọ Ọlọ́run sára àwọn owó ẹyọ tiwọn náà.
Fún nǹkan bí àádọ́jọ [150] ọdún lẹ́yìn ogun tí wọ́n fi ọgbọ̀n ọdún jà yẹn, orúkọ Ọlọ́run ò kúrò lára àwọn owó ẹyọ, àtàwọn àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n fi ń yẹ́ni sí nígbà ìdíje. Wọ́n ṣe irú àwọn owó ẹyọ bẹ́ẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè bí Austria, Faransé, Mẹ́síkò, Rọ́ṣíà àtàwọn orílẹ̀-èdè míì. Àmọ́, nígbà tó fi máa tó ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ogun yẹn, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ yọ́ orúkọ Ọlọ́run sára àwọn owó ẹyọ mọ́. Nígbà tó yá, ó dàwátì lára àwọn òǹtẹ̀ tí wọ́n ń lò.
Sísọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, a lè máà rí orúkọ Ọlọ́run mọ́ lára àwọn owó tá à ń ná báyìí, kò sí àní àní pé àwọn èèyàn ti ń lò ó ju tìgbà kígbà rí lọ. Tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti yan àwọn tó máa jọ́sìn rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, . . . èmi sì ni Ọlọ́run.” (Aísáyà 43:12) Kò sí owó ẹyọ èyíkèyí tó lè ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí. Kódà, kò séyìí tó sòótọ́ nípa Ọlọ́run nínú àwọn tó yọ́ orúkọ ẹ̀ sára àwọn owó ẹyọ wọn, torí gbogbo wọn ló ń sọ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn ogun ìkà táwọn ń jà. Àmọ́ lóde òní, àwọn kan wà tó ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀ lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà lójú ẹ̀.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rọ̀ ẹ́ pé kó o wá mọ púpọ̀ sí i nípa irú ẹni tí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́, kó o sì mọ ohun tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù tó wà nínú Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18) Ọmọ Ọlọ́run olùfẹ́ ọ̀wọ́n, sọ bí ìmọ̀ nípa Jèhófà ṣe ṣeyebíye tó nígbà tó gbàdúrà pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
Irin iṣẹ́ àwọn alágbẹ̀dẹ tó ń yọ́ nǹkan sára owó ẹyọ
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
Owó ẹyọ 1 àtàwọn ohun èlò: Hans-Peter-Marquardt.net; owó ẹyọ 2: Mit freundlicher Genehmigung Sammlung Julius Hagander
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]
Owó ẹyọ 3 àti 4: Mit freundlicher Genehmigung Sammlung Julius Hagander