Fífìyà Jẹ Àwọn Obìnrin Ti Di Ìṣòro Tó Kárí Ayé
WỌ́N ti ya ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá ọdún sọ́tọ̀ lágbàáyé gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìfòpin sí fífìyà jẹ àwọn obìnrin. Ìgbìmọ̀ Gbogbo Gbòò ti Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fọwọ́ sí ọjọ́ pàtàkì yìí lọ́dún 1999 láti lè fi ké gbàjarè sétí aráyé pé àwọn kan ń tẹ ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin lójú. Kí ló mú kírú ọjọ́ bẹ́ẹ̀ di ohun tí wọ́n fẹ́ máa rántí lọ́dọọdún?
Àwọn kan wà tó jẹ́ àṣà ìbílẹ̀ wọn pé kí wọ́n máa fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn obìnrin tàbí kí wọ́n máa tẹ̀ wọ́n mẹ́rẹ̀. Kékeré kọ́ ni ẹ̀tanú tí wọ́n ní sí wọn. Ilẹ̀ ọjọ́ kan ò mọ́ ká máà ráwọn tó ń fìyà jẹ obìnrin, ìyẹn ò sì yọ àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà sílẹ̀. Ọ̀gá Àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè tẹ́lẹ̀ rí, Kofi Annan tiẹ̀ sọ pé, “kò síbi táwọn èèyàn kì í ti í fìyà jẹ obìnrin lágbàáyé, kò sí àwùjọ tá a ti lè fẹ́ irú ẹ̀ kù, kò sì sí àṣà ìbílẹ̀ tó lòdì sí i. Ìfìyàjẹni náà ò yọ obìnrin kankan sílẹ̀, láìka ìran tàbí ẹ̀yà rẹ̀ sí, ì báà jẹ́ òtòṣì tàbí ẹni tó tilé ọlá wá, ì báà jẹ́ ọmọ ọlọ́rọ̀ tàbí ọmọ tí wọ́n fìṣẹ́ wò, ipò yòówù tí ì báà wà láwùjọ.”
Aṣojú àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀rí kan tó wà lára ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti ọ̀ràn àwọn tó ń fìyà jẹ obìnrin, ìyáàfin Radhika Coomaraswamy, sọ pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn obìnrin ló ka fífìyà jẹ obìnrin sí “àrí-ì-gbọ́dọ̀-wí àti ìwà ìtìjú tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ, tétí kejì ò gbọ́dọ̀ báni gbọ́.” Àbájáde ìwádìí tí àjọ tó ń rí sí ọ̀ràn àwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ gbé jáde lórílẹ̀-èdè Holland fi hàn pé lórílẹ̀-èdè kan báyìí ní Amẹ́ríkà Gúúsù, bá a bá kó ọgọ́rùn-ún obìnrin jọ, mẹ́tàlélógún nínú wọn, ìyẹn bí ẹyọ kan nínú mẹ́rin, ló ń rún ìyà mọ́ra lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ wọn. Àjọ tó ń rí sí ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù pẹ̀lú fojú bù ú pé ẹyọ kan lára obìnrin mẹ́rin nílẹ̀ Yúróòpù ló ń rún ìyà mọ́ra lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ wọn ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. Iléeṣẹ́ Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń bójú tó ọ̀ràn abẹ́lé sọ pé, lọ́dún kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí nílẹ̀ England àti Wales, ó tó obìnrin méjì tí ọkọ wọn tàbí ẹni tó ti fẹ́ wọn rí ń pa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìwé ìròyìn India Today International sọ pé, “ní tàwọn obìnrin tí wọ́n ń gbé jákèjádò ilẹ̀ Íńdíà, ṣe ni wọ́n ń jí tí wọ́n sì ń sùn nínú ìbẹ̀rù, ìgbàkigbà lẹnì kan lè yọ sí wọn kó sì fipá bá wọn lò pọ̀, lọ́nà oko, lọ́nà odò, lójú ọ̀nà, nílé ọtí, tàbí nílé oúnjẹ.” Àjọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lágbàáyé ṣàpèjúwe fífìyà jẹ àwọn obìnrin gẹ́gẹ́ bí “ọ̀ràn nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn táwọn èèyàn ń kọminú sí níbi tó pọ̀ jù lọ.”
Ǹjẹ́ àbájáde ìwádìí tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká rí ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn obìnrin? Ìbéèrè tí ìjíròrò wa máa dá lé lórí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn gan-an nìyẹn.