Bó o Ṣe Lè Wá Ìsìn Tòótọ́ Rí
Àwọn kan máa ń béèrè pé, ‘bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni òtítọ́ kan wà tí Ọlọ́run fẹ́ kéèyàn mọ̀, kí nìdí tí màá fi máa wá a kiri?’ ‘Bí ohun pàtàkì kan bá sì wà tí Ọlọ́run fẹ́ kí aráyé mọ̀, kí ló dé tí kò sọ ọ́ di mímọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere kí gbogbo èèyàn lè tètè lóye rẹ̀, láì ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣèwádìí?’
DÁJÚDÁJÚ, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò kọjá ohun tí Ọlọ́run lè ṣe. Àmọ́, ṣé ọ̀nà tó fẹ́ gbà sọ òtítọ́ di mímọ̀ nìyẹn?
Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Sọ Òtítọ́ Di Mímọ̀
Òótọ́ ni pé Ọlọ́run máa ń sọ ohun tó bá fẹ́ ká mọ̀ fún wa lọ́nà táwọn tó ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́ kiri á fi ṣàwárí ẹ̀. (Sáàmù 14:2) Ìwọ ṣàyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán wòlíì rẹ̀ Jeremáyà ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn. Ọlọ́run ní kó sọ fún àwọn èèyàn òun tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ pé àwọn ará Bábílónì ń bọ̀ wá pa Jerúsálẹ́mù run.—Jeremáyà 25:8-11; 52:12-14.
Síbẹ̀, nígbà tí Jeremáyà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ tiẹ̀ lọ́wọ́ a tún ráwọn wòlíì míì tí wọ́n sọ pé iṣẹ́ Ọlọ́run làwọn náà ń jẹ́. Hananáyà sàsọtẹ́lẹ̀ pé àlàáfíà máa jọba nílùú Jerúsálẹ́mù. Ìyẹn sì yàtọ̀ pátápátá sí iṣẹ́ tí Jeremáyà jẹ́ fún wọn. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ta ni káwọn èèyàn wọ̀nyẹn gbà gbọ́ báyìí, Jeremáyà ni àbí àwọn tó sọ ohun tó yàtọ̀ sí tiẹ̀?—Jeremáyà 23:16, 17; 28:1, 2, 10-17.
Káwọn Júù tí òtítọ́ ń jẹ lọ́kàn tó lè mọ ẹni tọ́rọ̀ ẹ̀ jóòótọ́ láàárín wọn, àfi kí wọ́n mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Wọ́n gbọ́dọ̀ lóye àwọn òfin àtàwọn ìlànà rẹ̀, tó fi mọ́ ojú tó fi ń wo ìwà àìtọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ló lè mú kí wọ́n gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run gbẹnu Jeremáyà sọ pé “kò sí ènìyàn kankan tí ó ronú pìwà dà lórí ìwà búburú rẹ̀.” (Jeremáyà 8:5-7) Síwájú sí i, wọn ì bá ti fòye mọ̀ pé báwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù ṣe kùnà láti ronú pìwà dà yìí ò lè bímọọre.—Diutarónómì 28:15-68; Jeremáyà 52:4-14.
Àwọn ohun tí Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jerúsálẹ́mù ní ìmúṣẹ. Àwọn ará Bábílónì pa ìlú náà run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti sàsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa yọrí sí tí wọ́n bá ṣàìgbọràn, ó gba ìsapá kí wọ́n tó lè mọ̀ pé àkókò ẹ̀san látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló dé bá àwọn.
Òtítọ́ Tí Kristi Fi Kọ́ni Wá Ńkọ́?
Òtítọ́ tí Jésù Kristi wàásù rẹ̀ ńkọ́? Ṣé gbogbo èèyàn ló gbà pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an ló jẹ́ fáráyé? Rárá o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níbẹ̀ ni Jésù wà tó ti ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, tó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ ò fòye mọ̀ pé òun la sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa jẹ́ Mèsáyà, ìyẹn Kristi tàbí Ẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn.
Ní ti àwọn Farisí tí wọ́n ní kí Jésù sọ ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa dé fáwọn, ó dá wọn lóhùn pé: “Ìjọba Ọlọ́run kì yóò wá pẹ̀lú ṣíṣeérí tí ń pàfiyèsí.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín.” (Lúùkù 17:20, 21) Jésù, tó jẹ́ Alákòóso tí Ọlọ́run yàn, wà láàárín wọn níbẹ̀! Àmọ́, àwọn Farisí yẹn kọ̀ láti kíyè sí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ń ní ìmúṣẹ ń jẹ́rìí sí i ní kedere pé Jésù ni Mèsáyà, wọ́n sì kọ̀ láti gbà á gẹ́gẹ́ bíi “Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”—Mátíù 16:16.
Báwọn èèyàn ṣe ṣe náà nìyẹn nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi polongo òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn ní ọ̀rúndún kìíní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ìyanu táwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ṣe fi hàn pé Ọlọ́run ń tì wọ́n lẹ́yìn, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà ò lóye òtítọ́ lọ́nà tó ṣe kedere. (Ìṣe 8:1-8; 9:32-41) Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn” nípa kíkọ́ wọn. Nítorí pé àwọn tó ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́ kiri tẹ́tí sílẹ̀ tí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́, àwọn náà sì di onígbàgbọ́.—Mátíù 28:19; Ìṣe 5:42; 17:2-4, 32-34.
Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí. À ń wàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù náà kò fi dandan jẹ́ lọ́nà “ṣíṣeérí tí ń pàfiyèsí,” ìyẹn ni pé, lọ́nà ṣíṣe kedere tí gbogbo olùgbé ayé á fi mọ̀ pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wa là ń jẹ́ fún wọn, síbẹ̀, kò ṣòro láti dá òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ̀. Báwọn tó fẹ́ sin Ọlọ́run tọkàntọkàn àti lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà bá sì gbọ́ ọ, kíá ló máa ń tètè yé wọn.—Jòhánù 10:4, 27.
Kíkà tó ò ń ka ìwé ìròyìn tó ṣàlàyé Bíbélì yìí pàápàá fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó o jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń fẹ́ láti lóye òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́. Ọ̀nà wo lo lè gbà mọ ẹ̀sìn tó ń fi irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ni?
Bó O Ṣe Lè Mọ Ẹ̀sìn Tòótọ́
A rí lára àwọn tó gbé nílùú Bèróà ní ọ̀rúndún kìíní tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún nítorí ohun tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tó ti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wọn. Wọn ò tètè gbà pé òótọ́ lohun tí Pọ́ọ̀lù sọ; síbẹ̀, wọ́n fetí sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ohun táwọn ará Bèróà ṣe lẹ́yìn tí wọ́n tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù.
Àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé nìyí: “Wàyí o, àwọn tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yìí [àwọn ará Bèróà] ní ọkàn-rere ju àwọn ti Tẹsalóníkà lọ, nítorí pé wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí. Látàrí èyí, ọ̀pọ̀ nínú wọ́n di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 17:10-12) Torí náà, ìwádìí oréfèé kọ́ ni wọ́n ṣe. Wọn ò wulẹ̀ rò pé gbogbo nǹkan á ti yé àwọn lẹ́yìn táwọn bá ti ní ìjíròrò ṣókí kan tàbí méjì pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù.
Tún kíyè sí i pé àwọn ará Bèróà “gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú.” Èyí jẹ́ ká lóye ohun kan nípa ọwọ́ tí wọ́n fi mú ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ látinú Ìwé Mímọ́. Wọn kì í ṣe ẹni tó wulẹ̀ ń gba nǹkan gbọ́ láìjanpata, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò rí òtítọ́ nílẹ̀ kí wọ́n korí bọgbó. Wọn ò ṣe àríwísí sí gbogbo àlàyé tí Pọ́ọ̀lù, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣojú Ọlọ́run, ṣe fún wọn.
Tún gba èyí yẹ̀ wò: Àwọn ará Bèróà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́ nípa ẹ̀sìn Kristẹni ni. Ohun tí wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀ dùn mọ́ wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè dà bí èyí tó ṣòro láti gbà gbọ́. Àmọ́, dípò kí wọ́n kọ ohun tí wọ́n gbọ́, wọ́n fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́, wọ́n ń wò ó ‘yálà àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù sọ rí bẹ́ẹ̀ tàbí wọn kò rí bẹ́ẹ̀.’ Tún kíyè sí i pé àwọn tó sapá láti wádìí òkodoro òtítọ́ lára àwọn ará Bèróà àtàwọn ará Tẹsalóníkà di onígbàgbọ́. (Ìṣe 17:4, 12) Wọn ò jáwọ́ nínú ìwádìí tí wọ́n ń ṣe kí wọ́n wá fèrò tì sórí pé èèyàn ò lè ṣàwárí òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Wọ́n wá ẹ̀sìn tòótọ́ rí.
Bí Òtítọ́ Ṣe Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́
Béèyàn bá wá òtítọ́ rí, bíi tàwọn ará Bèróà, á máa yá a lára láti sọ ọ́ fáwọn ẹlòmíì. Inú àwọn míì lè má dùn pó ò ń sọ òtítọ́ tó o mọ̀ fáwọn èèyàn, torí pé lójú tiwọn ohun tó fìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn jù lọ ni pé kéèyàn gbà pé Ọlọ́run kan náà là ń sìn, ẹ̀sìn ló kàn yàtọ̀ síra. Àmọ́ ṣá o, ibi tí òtítọ́ Bíbélì dáa sí ni pé béèyàn bá ti mọ̀ ọ́n báyìí, ó máa ń dá èèyàn lójú gbangba ni. Èèyàn ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣiyè méjì bóyá òun lè lóye òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí bóyá èèyàn lè tipasẹ̀ gbogbo ẹ̀sìn jogún ìyè. Àmọ́, kéèyàn tó lè rí òtítọ́, ó gbọ́dọ̀ fi tọkàntọkàn ṣèwádìí, èyí tó ń béèrè pé kó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe irú ìwádìí bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbà pé àwọn ti rí ẹ̀sìn tòótọ́. Wọ́n sì ń ké sí ẹ pé kí ìwọ náà wá inú Ìwé Mímọ́ kó o bàa lè mọ àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ lákòókò tá a wà yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tó wé mọ́ ìwádìí náà ju kéèyàn wulẹ̀ yẹ àwọn kókó mélòó kan wò lọ, ìsọfúnni nípa àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, èyí tó o máa rí nínú àpótí tó wà ní ojú ìwé yìí, lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí náà.
Bó o bá jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé rẹ, wàá lè ṣèwádìí tó jinlẹ̀ nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. Èyí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dẹni tó mọ ẹ̀sìn tòótọ́.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn Ohun Tí Ìsìn Tòótọ́ Ń Kọ́ni
Ṣàyẹ̀wò ìwà àti ẹ̀kọ́ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní:
◼ Wọ́n ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tọ́ àwọn sọ́nà.—2 Tímótì 3:16; 2 Pétérù 1:21.
◼ Wọ́n kọ́ àwọn èèyàn pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, kò bá Ọlọ́run dọ́gba, ó sì rẹlẹ̀ sí I. —1 Kọ́ríńtì 11:3; 1 Pétérù 1:3.
◼ Wọ́n kọ́ni pé àwọn òkú máa padà wà láàyè nípasẹ̀ àjíǹde tó ń bọ̀.—Ìṣe 24:15.
◼ Àwọn èèyàn mọ̀ wọ́n mọ ìfẹ́ tó gbilẹ̀ láàárín wọn.—Jòhánù 13:34, 35.
◼ Olúkúlùkù wọn kì í dá ẹ̀sìn tirẹ̀ ṣe, àmọ́ a ṣètò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjọ, wọ́n sì wà níṣọ̀kan lábẹ́ ìdarí àwọn alábòójútó àti ìgbìmọ̀ alàgbà kan ṣoṣo tó ń wo Jésù gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú wọn. —Ìṣe 14:21-23; 15:1-31; Éfésù 1:22; 1 Tímótì 3:1-13.
◼ Wọ́n ń fìtara wàásù Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo fún aráyé. —Mátíù 24:14; 28:19, 20; Ìṣe 1:8.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Báwo làwọn èèyàn ṣe lè mọ̀ pé wòlíì tòótọ́ ni Jeremáyà, nígbà táwọn míì sọ ohun tó yàtọ̀ sí tiẹ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Àwọn ará Bèróà ọ̀rúndún kìíní fetí sí Pọ́ọ̀lù àmọ́ wọ́n yẹ Ìwé Mímọ́ wò lẹ́yìn náà láti rí i dájú bóyá òótọ́ lohun tó sọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Bó o bá fẹ̀sọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ẹ̀kọ́ tó jóòótọ́