Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Gbígba Ohun Asán Gbọ́ Bá Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Mu?
AKỌ̀RÒYÌN kan kọ̀ láti wọkọ̀ òfuurufú fún ọdún kan gbáko torí pé ẹnì kan tó ń woṣẹ́ ti sọ fún un pé ó máa kú sínú jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú. Onírúurú èèyàn lágbàáyé tí ipò wọn yàtọ̀ síra, tó fi mọ́ àwọn olóṣèlú, oníṣòwò, òṣèré, eléré ìdárayá, àtàwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga, ló gba ọ̀kan-ò-jọ̀kan ohun asán gbọ́. Bó bá wá di pé wọn ò mọ èwo ni ṣíṣe mọ́, tí ìdààmú ọkàn bá wọn tàbí tí wọ́n ń ṣàníyàn, wọ́n máa ń rò pé gbígbà táwọn gba ohun asán gbọ́ máa dáàbò bo àwọn kúrò lọ́wọ́ ewu tàbí kó jẹ́ kọ́wọ́ àwọn tẹ ohun táwọn ń fẹ́.
Ọ̀pọ̀ ohun asán làwọn èèyàn gbà pó máa ń dáni lọ́kàn le tàbí kí wọ́n rí i bí ọ̀nà tí kò burú téèyàn lè gbà fira ẹ̀ lọ́kàn balẹ̀. Olóògbé Margaret Mead, tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá èèyàn sọ pé: “Ìgbàgbọ́ táwọn èèyàn ní nínú ohun asán yìí ló jẹ́ ká mọ̀ pé ńṣe ni ẹ̀dá máa ń fẹ́ kí nǹkan rí bóun ṣe fẹ́, tàbí pé ẹ̀dá kì í fẹ́ kí láburú ṣẹlẹ̀ sí òun. Bí ìgbàgbọ́ yìí ò tiẹ̀ fi taratara tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n ṣì gbà pé ó ń fàwọn lọ́kàn balẹ̀, kì í sì í ṣe òun ló ń darí ayé àwọn.” Síbẹ̀, àwọn tó bá fẹ́ láti máa ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí gbọ́dọ̀ bi ara wọn pé, ‘Ṣó yẹ káwọn Kristẹni gba ohun asán gbọ́?
Bí Gbígba Ohun Asán Gbọ́ Ṣe Bẹ̀rẹ̀
Inú ìbẹ̀rù ni gbogbo aráyé ń gbé. Díẹ̀ lára ohun tí wọ́n máa ń bẹ̀rù ni ikú, àjálù àìròtẹ́lẹ̀ àti ohun táwọn èèyàn máa ń pè ní Àtúnwáyé. Sátánì, ọlọ̀tẹ̀ tó ta ko Ọlọ́run, ti pinnu láti mú àwọn èèyàn lẹ́rú, ó sì ti ń lo irọ́ tó kún fún ìtànjẹ yìí láti fìdí irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ múlẹ̀ lọ́kàn àwọn èèyàn. (Jòhánù 8:44; Ìṣípayá 12:9) Sátánì nìkan kọ́ ló ń sapá láti tan àwọn èèyàn jẹ kí wọ́n lè kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì pe Sátánì ní “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Mátíù 12:24-27) Àwọn wo làwọn ẹ̀mí èṣù yìí? Nígbà tí Nóà wà láyé, àwọn áńgẹ́lì kan dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n sì sọ ara wọn di ẹ̀mí èṣù. Látìgbà náà wá ni wọ́n ti ń gbìyànjú láti máa darí ìrònú àwọn èèyàn. Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán sì jẹ́ ọ̀kan lára irin iṣẹ́ wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2; Lúùkù 8:2, 30; Júdà 6.
Ọ̀kan lára àwọn irọ́ tí Sátánì pa ni ìgbàgbọ́ nínú ohun asán dá lé lórí. Irọ́ yẹn sì ni pé ohun kan tí kò ṣeé fojú rí máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn téèyàn bá ti kú, ó sì lè padà wá yọ àwọn tó wà láàyè lẹ́nu tàbí kó ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Ó sọ síwájú sí i pé “kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n” kankan lẹ́yìn téèyàn bá ti kú.—Oníwàásù 9:5, 10.
“Ohun Ìṣe-Họ́ọ̀-sí Lójú Jèhófà”
Ọ̀pọ̀ èèyàn ti yàn láti gba irọ́ Sátánì gbọ́. Síbẹ̀, ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run fún àwọn èèyàn rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ní ìtọ́ni tó ṣe kedere lórí ọ̀ràn yìí. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni . . . tí ń woṣẹ́, pidánpidán kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí ẹni tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú. Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.”—Diutarónómì 18:10-12.
Ó ṣeni láàánú pé gbogbo ìgbà kọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń tẹ̀ lé ìkìlọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ọjọ́ wòlíì Aísáyà, àwọn kan gbà gbọ́ pé kí àgbẹ̀ tó lè kórè ohun tó pọ̀, àfi kó wá ẹ̀yọ́nú “ọlọ́run Oríire,” èyí tó jẹ́ ìgbàgbọ́ asán tí kì í yọrí síbi tó dáa. Wọ́n pàdánù ojú rere Jèhófà àti ìbùkún rẹ̀.—Aísáyà 65:11, 12.
Kódà, nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni dé, ojú tí Jèhófà fi ń wo ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ó tíì yí padà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará ìlú Lísírà tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú ohun asán pé kí wọ́n “yí padà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti gbogbo ohun tí ń bẹ nínú wọn.”—Ìṣe 14:15.
Béèyàn Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Ohun Asán
Ohun asán táwọn èèyàn gbà gbọ́ ò lóǹkà, ohun tó sì wá wọ́pọ̀ jù lọ ni pé wọn kì í rí àlàyé tó mọ́gbọ́n dání ṣe nípa wọn. Báwọn èèyàn bá gba ohun asán gbọ́, ó lè mú kí wọ́n máa rò pé àkóbá ni ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀ sáwọn dípò kí wọ́n gbà pé àwọn ṣe àṣìṣe, kí wọ́n sì ṣe àtúnṣe.
A láyọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ti jáwọ́ kúrò nínú gbígba ohun asán gbọ́. Jésù sọ pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Ọmọ orílẹ̀-èdè Brazil kan tó ń jẹ́ Clementina, tó ti fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣe iṣẹ́ woṣẹ́woṣẹ́, sọ pé: “Iṣẹ́ woṣẹ́woṣẹ́ nìkan ni mo máa ń ṣe jẹun. Àmọ́, òtítọ́ Bíbélì ló gbà mí lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán.” Ká sòótọ́, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé àti gbígbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run látọkàn wá, lè ràn wá lọ́wọ́ ká bàa lè máa ṣe ohun tó tọ́. Èyí lè mú kí ìrònú wa pa pọ̀ sọ́nà kan, a ó sì lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, tí kò ní jẹ́ kí àjálù bá wa, tá á sì dín àníyàn wa kù.—Fílípì 4:6, 7, 13.
Bíbélì béèrè pé: “Àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? . . . Síwájú sí i, ìbáramu wo ni ó wà láàárín Kristi àti Bélíálì [Sátánì]?” Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ ò gbọ́dọ̀ máa gba ohun asán gbọ́.—2 Kọ́ríńtì 6:14-16.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Dípò káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n gba ohun asán gbọ́ gba Ọlọ́run gbọ́, ta ni wọ́n gbà gbọ́ nígbà ayé Aísáyà?—Aísáyà 65:11, 12.
◼ Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará Lísírà tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán láti ṣe?—Ìṣe 14:15.
◼ Ṣó yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ gba ohun asán gbọ́?—2 Kọ́ríńtì 6:14-16.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán máa ń fọkàn àwọn èèyàn balẹ̀ lórí òfo