Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Báwo Ló Ṣe Gbilẹ̀ Tó Lónìí?
IBI gbogbo ló ti ń ṣẹlẹ̀—níbi iṣẹ́, nílé ìwé, nínú mọ́tò èrò, àti lójú pópó. Tóo bá sín, àwọn èèyàn tóò mọ̀ rí, tí wọ́n kàn ń kọjá lọ, á sọ pé: “Wàá yè é.” Ọ̀pọ̀ èdè ló ní àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ èyí. Ní èdè Jámánì, wọ́n á sọ pé, “Gesundheit.” Àwọn Lárúbáwá á sọ pé, “Yarhamak Allah,” àwọn ará Polynesia ní Gúúsù Pàsífíìkì á sọ pé, “Tihei mauri ora.”
Gbígbàgbọ́ pé èyí wulẹ̀ jẹ́ ìkíni lásán lè máà mú kí o ronú jinlẹ̀ nípa ìdí tí àwọn èèyàn fi ń pèdè yẹn. Ṣùgbọ́n, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ni gbòǹgbò ọ̀rọ̀ náà. Moira Smith, tó jẹ́ alábòójútó ibi ìkówèésí ti Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ìtàn Ìṣẹ̀ǹbáyé ní Yunifásítì Indiana nílùú Bloomington, Indiana, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ nípa ọ̀rọ̀ náà pé: “Ó wá láti inú èrò pé bóo ṣe sín yẹn lọkàn ẹ jáde kúrò lára ẹ.” Tí a bá wá sọ pé, “Wàá yè é,” ìyẹn túmọ̀ sí pé a ń bẹ Ọlọ́run láti dá a padà sáyè rẹ̀.
Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn lè gbà pé kò bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé ọkàn èèyàn ń jáde kúrò lára rẹ̀ tó bá sín. Ìdí nìyẹn tí ò fi yani lẹ́nu nígbà tí ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary túmọ̀ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán bí “ìgbàgbọ́ tàbí àṣà tí èèyàn ń tẹ̀ lé nítorí àìmọ̀kan, ìbẹ̀rù ohun tí a kò mọ̀, gbígba idán tàbí àkọsẹ̀bá gbọ́, tàbí èròǹgbà èké nípa ohun tó ń fa ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí.”
Abájọ tí oníṣègùn kan ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún fi pe àwọn ìgbàgbọ́ asán táwọn èèyàn ń tẹ̀ lé ní “àṣìṣe àwọn gbáàtúù” tí kò kàwé. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí ẹ̀dá ènìyàn wọ ọ̀rúndún ogún tòun ti àwọn àṣeyọrí nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica ti ọdún 1910 sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé àkókò ń bọ̀ tí “ipò ọ̀làjú máa tú aṣọ lójú eégún ìgbàgbọ́ nínú ohun asán.”
Ó Gbilẹ̀ Gan-an Bíi Ti Tẹ́lẹ̀
Èrò pé nǹkan yóò dára tó wáyé ní ọgọ́rin ọdún sẹ́yìn yẹn kò fẹsẹ̀ rinlẹ̀, nítorí ó jọ pé mìmì kan ò kúkú mi ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Bí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ṣe máa ń pẹ́ nílẹ̀ nìyẹn. Gbólóhùn náà, “ìgbàgbọ́ nínú ohun asán” wá láti inú àwọn ọ̀rọ̀ èdè Látìn náà super, tó túmọ̀ sí “lékè,” àti stare, tó túmọ̀ sí “láti dúró.” Ìdí nìyẹn tí wọ́n ṣe máa ń pe àwọn jagunjagun tó togun bọ̀ ní superstites, nítorí pé wọn ò kú sógun bíi tàwọn jagunjagun ẹgbẹ́ wọn, lọ́nà olówuuru, ó túmọ̀ sí pé wọ́n “lékè” àwọn yòókù. Ìwé tó ń jẹ́ Superstitions sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí pé: “Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ṣì wà lónìí, ó ti lékè bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún la ti gbìyànjú láti pa á run.” Gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ohun asán tí ènìyàn gbà gbọ́ tí kò kásẹ̀ ńlẹ̀.
◻ Lẹ́yìn tí ikú òjijì pa gómìnà ìlú pàtàkì kan ní Éṣíà, òṣìṣẹ́ kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ nílé gómìnà kó ṣìọ̀ṣìọ̀ bá gba gómìnà tó fẹ́ bọ́ sórí àléfà nímọ̀ràn láti lọ woṣẹ́ lọ́dọ̀ abẹ́mìílò kan tó gbówọ́, ìyẹn wá sọ pé kí wọ́n pa ọwọ́ nǹkan mélòó kan dà nínú àti láyìíká ilé náà. Òṣìṣẹ́ náà ronú pé àwọn ìyípadà náà kò ní jẹ́ kí nǹkan ibi ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ mọ́.
◻ Ààrẹ ilé iṣẹ́ kan tí ń pa ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ owó ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kì í rìn láìmú àkànṣe òkúta kan báyìí dání. Láti ìgbà àkọ́kọ́ tóbìnrin yìí ti ṣàṣeyọrí nígbà ìpàtẹ ọjà kan báyìí, kò jẹ́ jáde láìmú un dání.
◻ Kí àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ ní Éṣíà tó gba iṣẹ́ ńlá, wọ́n sábà máa ń lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀.
◻ Eléré ìdárayá kan wà tó jẹ́ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ gidigidi ní ìmúrasílẹ̀ fún eré, ó sábà máa ń sọ pé aṣọ kan báyìí ló ń jẹ́ kí òun borí nínú ìdíje. Nítorí náà, ńṣe ló máa ń wọ aṣọ náà láìfọ̀ ọ́ nínú gbogbo ìdíje tó ń ṣe lẹ́yìn náà.
◻ Akẹ́kọ̀ọ́ kan fi bírò kan ṣe ìdánwò, ó sì páàsì ìdánwò náà. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí ka bírò náà sí nǹkan tó ń mú “oríire” wá.
◻ Lọ́jọ́ tí wọ́n ń gbé ọmọbìnrin kan níyàwó, ó fara balẹ̀ ṣe aṣọ rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, ara nǹkan tó fi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ ni “nǹkan tó ti gbó, nǹkan tó tuntun, nǹkan tó lọ yá, àti nǹkan aláwọ̀ búlúù.”
◻ Ẹnì kan báyìí ṣí Bíbélì síbì kan, ó sì ka ẹsẹ tó kọ́kọ́ rí, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé ohun tí òun kà níbẹ̀ yóò fún òun ní ìtọ́sọ́nà tí òun nílò lákòókò yẹn.
◻ Bí ọkọ̀ òfuurufú ńlá kan tó ń kó èrò ti ń sáré lọ láti gbéra, àwọn èrò mélòó kan nínú rẹ̀ ṣe àmì àgbélébùú. Ẹlòmíràn ń fọwọ́ pa ère àwòrán Christopher “Mímọ́” bí ọkọ̀ òfuurufú náà ṣe ń fò lọ lókè.
Ó hàn kedere pé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán gbilẹ̀ gan-an lóde òní pàápàá. Ní gidi, Stuart A. Vyse, igbá kejì ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìrònú òun ìhùwà ẹ̀dá ní Yunifásítì Connecticut, sọ nínú ìwé tó kọ náà, Believing in Magic—The Psychology of Superstition, pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń gbé láwùjọ tó ti lọ jìnnà nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ṣì gbilẹ̀ gan-an bíi ti tẹ́lẹ̀.”
Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán fẹsẹ̀ rinlẹ̀ gan-an lóde òní débi pé ńṣe ni gbogbo ìsapá ẹ̀dá láti fòpin sí i ń forí ṣánpọ́n. Èé ṣe tó fi rí bẹ́ẹ̀?