ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w02 8/1 ojú ìwé 3
  • Bí Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ṣe Ń Darí Ìgbésí Ayé Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ṣe Ń Darí Ìgbésí Ayé Èèyàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Kí Ló Dé Tí Ò Kásẹ̀ Ńlẹ̀?
    Jí!—1999
  • Ǹjẹ́ Gbígba Ohun Asán Gbọ́ Bá Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Mu?
    Jí!—2008
  • Ṣé Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Báwo Ló Ṣe Gbilẹ̀ Tó Lónìí?
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
w02 8/1 ojú ìwé 3

Bí Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ṣe Ń Darí Ìgbésí Ayé Èèyàn

ÌWỌ àti ẹnì kan kọ lu ara yín bí o ṣe ń jáde láti inú ilé rẹ. O dédé fẹsẹ̀ kọ. Irú ẹyẹ kan báyìí máa ń ké lóru. Ò ń lá irú àlá kan náà léraléra. Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí kò nítumọ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́ àmì, tàbí àpẹẹrẹ, tàbí ìsọfúnni láti ilẹ̀ ẹ̀mí làwọn kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà máa ń ka irú nǹkan wọ̀nyí sí. Wọ́n gbà pé ohun rere tàbí ohun búburú kan ló fẹ́ ṣẹlẹ̀, ìyẹn sì sinmi lórí irú àmì tí wọ́n rí àti bí wọ́n ṣe túmọ̀ rẹ̀.

Àmọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tún wà láwọn ibòmíràn yàtọ̀ sí ilẹ̀ Áfíríkà o. Àní láìfi ọ̀pọ̀ ọdún pè, èyí táwọn ará China àtàwọn tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Soviet Union tẹ́lẹ̀ ti fi gbà pé kò sí Ọlọ́run, àwọn tó pọ̀ gan-an lára wọn ṣì rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ọ̀pọ̀ ló máa ń yẹ ìràwọ̀ ọjọ́ ìbí wọn wò, tí wọ́n ka Friday tó bá bọ́ sí ọjọ́ kẹtàlá oṣù sí ọjọ́ burúkú, tí wọn kì í sì í fẹ́ rí ológbò dúdú sójú. Àwọn kan tó wà ní Ìhà Àríwá Jíjìnnà Réré ilẹ̀ ayé ka ìmọ́lẹ̀ ọ̀yẹ̀ sí àmì pé ogun àti àjàkálẹ̀ àrùn ń bọ̀. Ní Íńdíà, àwọn awakọ̀ ló sábà máa ń kó àrùn éèdì ran àwọn èèyàn, nítorí wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ kí ara wọn lè silẹ̀ láwọn ọjọ́ tí ooru bá mú. Nílẹ̀ Japan, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà abẹ́lẹ̀ gbà gbọ́ pé àmì pé ohun búburú máa ṣẹlẹ̀ ni kí obìnrin gba ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà kọjá kí wọ́n tó parí iṣẹ́ ibẹ̀. Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tún gbòde kan nínú àwọn eré ìdárayá. Kódà, ẹnì kan tó ń gbá irú bọ́ọ̀lù kan tí wọ́n ń pé ní volley gbà gbọ́ pé ìgbà tóun bá wọ ìbọ̀sẹ̀ dúdú dípò ìbọ̀sẹ̀ funfun lòun máa ń borí. Àwọn nǹkan wọ̀nyí pọ̀ lọ jàra.

Ìwọ náà ńkọ́? Ṣé o ní ohun kan tí kò ṣeé ṣàlàyé tó ń bà ọ́ lẹ́rù? Ǹjẹ́ ohun kan wà tó o “gbà gbọ́ tàbí tí o kò fi gbogbo ara gbà gbọ́ tàbí àṣà kan tí kò ṣeé ṣàlàyé, tó ń nípa lórí rẹ”? Ìdáhùn rẹ lè fi irú ẹni tó o jẹ́ hàn, nítorí pé ọ̀nà tí ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ gbà túmọ̀ “ìgbàgbọ́ nínú ohun asán” nìyẹn.

Ẹni tó bá ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán nípa lórí ìpinnu òun àtàwọn ohun tóun ń ṣe lójoojúmọ́ ń jẹ́ kí ohun tí òun ò lóye rẹ̀ jọba lórí òun nìyẹn. Ǹjẹ́ èyí mọ́gbọ́n dání? Ǹjẹ́ ó yẹ ká yọ̀ǹda ara wa fún irú ohun asán, tó lè nípa búburú léèyàn lórí bẹ́ẹ̀? Ṣé ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe bàbàrà ni ìgbàgbọ́ nínú ohun asán jẹ́ tàbí nǹkan eléwu?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́