“Ọ̀sán Dòru!”
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BENIN
“ÈYÍ MÀ GA O! Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ṣe Kàyéfì Lọ́jọ́ Tí Òṣùpá Ṣíji Bo Ìmọ́lẹ̀ Oòrùn,” nigbe tí ìwé ìròyìn Daily Graphic ti ilẹ̀ Gánà fi bọnu lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹta, ọdún 2006, ọjọ́ kejì ọjọ́ tí òṣùpá ṣíji bo ìmọ́lẹ̀ oòrùn. Ìtòsí ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Brazil ni wọ́n ti kọ́kọ́ rí i, kò sì pẹ́ tó fi hàn lórí agbami òkun Àtìláńtíììkì, kó tún tó hàn láwọn orílẹ̀-èdè etíkun bíi Gánà, Tógò àti Benin lọ́wọ́ agogo mẹ́jọ òwúrọ̀, torí pé ó yára nígbà mẹ́rìndínlógún ju ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó ń rìn lórí títì márosẹ̀ lọ. Báwo ló ṣe máa rí láwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ná?
Ọdún 1947 ni òṣùpá ṣíji bo ìmọ́lẹ̀ oòrùn bámúbámú gbẹ̀yìn lórílẹ̀-èdè Gánà. Ọ̀gbẹ́ni Theodore, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nígbà náà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò rí i kí òṣùpá ṣíji bo ìmọ́lẹ̀ oòrùn bẹ́ẹ̀ rí, bí àlá ló jọ lójú wọn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé báwọn èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n á ní ‘ọ̀sán dòru!’”
Kéku Ilé Gbọ́ Kó Sọ fún Toko
Àwọn aláṣẹ ti kìlọ̀ fáwọn ará ìlú nílé, lóko, lẹ́yìn odi pé kí wọ́n má ṣe wo oòrùn láìlo awò ojú. Àwọn àkọlé fara hàn gàdàgbà gàdàgbà nílùú Tógò tí wọ́n fi ń ṣèkìlọ̀ fáwọn èèyàn pé: “A kì í rójú rà lọ́jà o! Béèyàn bá fojú lásán wo oòrùn, ó lè sọni di afọ́jú!”
Ohun àkọ́kọ́ táwọn agbèfọ́ba tẹnu mọ́ ni pé káwọn èèyàn dúró sílé, kí wọ́n sì wo ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu náà lórí tẹlifíṣọ̀n. Èkejì ni pé bí wọ́n bá wà níta gbangba, kí wọ́n fi awò àkànṣe sójú. Ro-ro-ro ni àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ èèyàn tẹjú mọ́ tẹlifíṣọ̀n àti kọ̀ǹpútà kí wọ́n lè fojú ara wọn rí àwọn àwòrán rírẹwà náà. Àmọ́, tẹlifíṣọ̀n àti kọ̀ǹpútà ò lè jẹ́ kéèyàn rí ìháragàgà àti ariwo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ àwọn èèyàn tí ara wọn wà lọ́nà ṣáájú àti lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Bọ́rọ̀ ọ̀hún ṣe rí rèé.
Ara Àwọn Èèyàn Wà Lọ́nà
Bí ojúmọ́ ṣe máa ń mọ́ ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà náà ló ṣe mọ́ lọ́jọ́ náà. Oòrùn ń tàn yanran, ojú ọ̀run sì mọ́ kedere. Ǹjẹ́ ọ̀sán máa dòru lónìí yìí? Bí àkókò tí wọ́n kéde pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa wáyé ṣe ń tó lọ, ńṣe làwọn tó dúró sí gbangba gbé awò wọn sójú tí wọ́n sì ń wo ojú ọ̀run. Àwọn kan gbé tẹlifóònù alágbèéká sétí, láti béèrè ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ wọn lápá ibòmíì rí.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òǹwòran ò kọ́kọ́ rí òṣùpá, ó wà níbi tó jìn tó ẹgbàá márùndínlọ́gọ́sàn-án [350,000] kìlómítà, tó rọra ń yí lọ síbi tó ti máa ṣíji bo ìmọ́lẹ̀ oòrùn. Ṣàdédé ló fara hàn bí ohun dúdú tóńtóló kan, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣíji bo ìmọ́lẹ̀ oòrùn. Báwọn òǹwòran tára wọn wà lọ́nà ti ń rí i báyìí ni wọ́n ń hó yèè.
Nígbà tí gbogbo rẹ̀ kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, àwọn òǹwòran ò fi bẹ́ẹ̀ rí ìyàtọ̀ kan dà bí alárà. Àmọ́, bí òṣùpá ti rọra ń ṣíji bo ìmọ́lẹ̀ oòrùn, lojú ọjọ́ ń yí pa dà. Ojú ọ̀run tó ti ṣú bí aró tẹ́lẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣókùnkùn. Ojú ọjọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ gbóná mọ́. Àwọn iná ìgbàlódé tó máa ń tàn bí òkùnkùn bá ṣú sì bẹ̀rẹ̀ sí í tàn. Ojú pópó wá dá páro. Àwọn ọlọ́jà tilẹ̀kùn. Àwọn ẹyẹ ò ké ṣíoṣío mọ́, àwọn ẹranko sì ń múra àti lọ sùn. Ìgbà tó yá lòkùnkùn bolẹ̀ bámúbámú, tí kẹ́kẹ́ sì pa mọ́ kóówá lẹ́nu.
Mánigbàgbé Lọ̀rọ̀ Òkùnkùn Tó Bolẹ̀ Bámúbámú Náà
Ìràwọ̀ ò mọ́lẹ̀ rokoṣo mọ́. Ìtànṣán oòrùn tó rẹwà lọ́nà kíkọyọyọ wá tàn yíká eteetí òṣùpá dúdú mìnìjọ̀ náà bí òrùka tó funfun báláú. Ìmọ́lẹ̀ títàn yanran tí wọ́n ń pè ní Ìlẹ̀kẹ̀ Bailya bẹ̀rẹ̀ sí í tàn ní eteetí òṣùpá bí ìtànṣán oòrùn tó ń balẹ̀ sára òṣùpá ṣe ń hàn níbẹ̀. Èyí sì mú kí ibi tí ìmọ́lẹ̀ ti ń tàn náà máa dán logólogó bíi wúrà. Bẹ́ẹ̀ sì tún làwọn àwọ̀ ìyeyè àti pupa rẹ́súrẹ́sú ń ta wíríwírí lára òṣùpá. Ọ̀kan lára àwọn òǹwòran náà sọ pé: “Mi ò róhun tó rẹwà tó báyìí rí. Áà, Ọlọ́run tóbi lọ́ba!”
Kò ju ìṣẹ́jú mẹ́ta lọ tí ọ̀sán fi dòru. Lẹ́yìn náà ni oòrùn tún bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn. Inú ọ̀pọ̀ òǹwòran dùn, wọ́n sì hó yèè. Ojú ọ̀run mọ́ kedere, a ò sì rí àwọn ìràwọ̀ mọ́. Bí òkùnkùn tó mójú ọjọ́ dá gùdẹ̀ náà ṣe para dà lọ́gán nìyẹn, bí ìgbà tí oòrùn bá lá ìrì òwúrọ̀ gbẹ.
“Ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé ní sánmà” gbáà ni òṣùpá jẹ́ lójú òfuurufú. Nítorí èyí, a lè ṣírò ìgbà tí ọ̀sán máa dòru ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú. (Sáàmù 89:37) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́ta [60] ọdún táwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ti ń wọ̀nà fún èyí tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Ó sì di ọdún 2081 kírú ẹ̀ tún tó wáyé ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Bóyá wàá láǹfààní láti rí i kí ọ̀sán dòru lágbègbè ibi tó ò ń gbé kó tó dìgbà yẹn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà, Francis Baily, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ni wọ́n fi sọ ìrísí tó dà bí ìlẹ̀kẹ̀ náà. Òun ló kọ́kọ́ ṣàkọsílẹ̀ ìrísí náà nígbà tó fara hàn lọ́dún 1836 tí òṣùpá ṣíji bo ìmọ́lẹ̀ oòrùn.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ǹjẹ́ Ọ̀sán Dòru Lọ́jọ́ Tí Jésù Kú?
Àkọsílẹ̀ Máàkù 15:33 kà pé: “Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn kan ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà títí di wákàtí kẹsàn-án.” Ohun àràmàǹdà gbáà ni òkùnkùn tó ṣú fún wákàtí mẹ́ta gbáko láti aago méjìlá ọ̀sán títí di agogo mẹ́ta ọ̀sán yìí. Kò dájú pé ọ̀sán ló dòru lásìkò náà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó tíì wáyé rí níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé ò pẹ́ ju nǹkan bí ìṣẹ́jú méje ààbọ̀ lọ. Èkejì sì ni pé ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn tí wọ́n ń fi òṣùpá kà ni Jésù kú. Ìgbà tí oṣù òṣùpá bá lé lójú sánmà ló sábà máa ń jẹ́ ọjọ́ kìíní nínú oṣù Nísàn, òṣùpá máa ń wà láàárín ayé àti oòrùn, ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀sán dòru nírú àkókò bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bó bá fi máa di Nísàn ọjọ́ kẹrìnlá, òṣùpá á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ yí ayé po. Nípa bẹ́ẹ̀, àárín oòrùn àti òṣùpá ni ayé máa wà, torí náà, dípò kí òṣùpá ṣíji bo ìmọ́lẹ̀ oòrùn, ńṣe ni ìtànṣán oòrùn á tàn yòò sára òṣùpá. A óò wá rí òṣùpá rokoṣo, èyí tó jẹ́ àkókò yíyẹ láti ṣèrántí Ikú Jésù.
[Àwòrán]
Oṣù Nísàn 14 máa ń bọ́ sí ọwọ́ ìgbà tí òṣùpá bá lé lójú sánmà
[Àwòrán/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Bó ṣe ń fara hàn níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
●
⇧
●
⇧
●
⇧ ÁFÍRÍKÀ
BENIN ●
⇧
TÓGÒ ●
⇧
GÁNÀ ●
⇧
●
⇧
●
⇧
●
⇧
●
⇧
●
[Credit Line]
Àwòrán Ilẹ̀: A gbé e karí fọ́tò NASA/Visible Earth
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Bí ọ̀sán ṣe dòru rèé ní March 29, 2006
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn òǹwòran gbé awò àkànṣe sójú kí wọ́n bàa lè wo bí ọ̀sán ṣe dòru