ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/08 ojú ìwé 3
  • Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Kí Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Kí Ni?
  • Jí!—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Ṣèlérí Èrè Àgbàyanu fún Dáníẹ́lì
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Ìwé Dáníẹ́lì àti Ìwọ
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Ońṣẹ́ kan Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún un Lókun
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Dáníẹ́lì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 4/08 ojú ìwé 3

Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Kí Ni?

ÌSỌFÚNNI tí wọ́n kọ sára pátákó tí wọ́n gbé sójú fèrèsé ṣọ́ọ̀bù kan kà pé, “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn.” Ìsọfúnni náà ò ṣòroó lóye. Ó lè túmọ̀ sí pé àsìkò tí wọ́n ń tajà ní ẹ̀dínwó ò ní pẹ́ kásẹ̀ ńlẹ̀ tàbí pé wọn ò ní pẹ́ kógbá sílé. Àmọ́ tẹ́nì kan bá wá sọ pé, “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí” ńkọ́? Kí nìyẹn túmọ̀ sí?

Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń lo gbólóhùn náà, “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àti “àkókò òpin.” (2 Tímótì 3:1; Dáníẹ́lì 12:4) Ó ti lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún tí wòlíì Dáníẹ́lì ti rí ìran àwọn agbára ayé àti rògbòdìyàn tó máa wáyé láàárín wọn títí di “àkókò òpin.” Áńgẹ́lì Jèhófà sì sọ fún un pé àkókò òpin yìí gan-an làwọn nǹkan wọ̀nyí tó máa nímùúṣẹ. (Dáníẹ́lì 8:17, 19; 11:35, 40; 12:9) Dáníẹ́lì tún kọ̀wé pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.

Jésù Kristi lo ọ̀rọ̀ náà, “òpin” nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í nípa “àmì wíwàníhìn-ín [rẹ̀] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3-42) Kò sí àníàní pé ọ̀rọ̀ nípa ohun kan tó fẹ́ dópin ni Dáníẹ́lì àti Jésù ní lọ́kàn, ìyẹn ìyípadà kan tó kàmàmà, tó máa kan gbogbo olùgbé ayé àtàwọn tó ti gbé láyé rí. Dáníẹ́lì kọ̀wé nípa òpin tó máa dé bá gbogbo ìjọba ayé. Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan.”

Ṣó yẹ kíyẹn kàn ẹ́ ṣá? Bẹ́ẹ̀ ni. Gbogbo wa ló yẹ kọ́rọ̀ náà kàn, torí gbogbo wa lọ̀rọ̀ náà ta bá. Síbẹ̀, ọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ làwọn kan fi ń mú ọ̀rọ̀ yìí. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.’” (2 Pétérù 3:3, 4) Bọ́ràn ṣe rí gan-an lónìí nìyẹn, àwọn kan gbà gbọ́ pé kò sóhun tuntun lábẹ́ ọ̀run, àti pé bí nǹkan ṣe ń rí látẹ̀yìn wá náà lá á ṣe máa rí lọ.

Ṣé ẹ̀rí tiẹ̀ wà pé àkókò tí Bíbélì pè láwọn ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé lóòótọ́? Ẹ jẹ́ ká gbé ìyẹn yẹ̀ wò báyìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́