ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/08 ojú ìwé 22-24
  • Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Ò Fi Fọkàn Tán Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Ò Fi Fọkàn Tán Mi?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Máa Ń Dunni Gan-an!
  • Fi Hàn Pé O Ṣeé Fọkàn Tán
  • Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Wọ́n Padà Fọkàn Tán Ẹ
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Màá Fi Ní Òmìnira Sí I?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jẹ́ Káwọn Òbí Mi Fọkàn Tán Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù!
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Fífọkàntánni Ló Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Èèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 4/08 ojú ìwé 22-24

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Ò Fi Fọkàn Tán Mi?

“Mo fẹ́ káwọn òbí mi tiẹ̀ jẹ́ kí n máa dá ròde. Kì í ṣe pé mo fẹ́ máa rìnrìnkurìn o! Ṣe ni mo kàn fẹ́ kí mọ́mì jẹ́ kí n máa lọ kí ẹ̀gbọ́n dádì mi, mi ò fẹ́ kí wọ́n máa rò pé mo fẹ́ máa kẹ́gbẹ́ kiri.”—Sarah, ọmọ ọdún méjìdínlógún.a

“Gbogbo ìgbà ni mo máa ń bi àwọn òbí mi pé kí ló dé tí wọn ò ṣe kí ń fọkàn tán mi tí n bá fẹ́ tẹ̀ lé àwọn ọ̀rẹ́ mi jáde. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń sọ fún mi pé: ‘A fọkàn tán ẹ, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ la ò fọkàn tán.’ Ó máa ń dùn mí gan-an tí wọ́n bá sọ bẹ́ẹ̀!”—Christine, ọmọ ọdún méjìdínlógún.

BÍ OWÓ ni fífọkàn tánni rí. Kéèyàn tó rí i, ikun imú ọ̀tún á fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí tòsì, kì í dúró pẹ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé owó kì í tó olówó. Bọ́ràn ti rí pẹ̀lú fífọkàn tánni náà nìyẹn. Iliana tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí mo bá ti fẹ́ jáde làwọn òbí mi máa ń da ìbéèrè bò mí nípa ibi tí mò ń lọ, àwọn tá a jọ ń lọ, ohun tí mo fẹ́ ṣe lọ́hùn-ún àti ìgbà tí mo máa padà. Mo mọ̀ pé òbí mi ni wọ́n, àmọ́ inú máa ń bí mi tí wọ́n bá ń da irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ bò mí!”

Ṣé o máa ń rò ó nígbà míì pé àwọn òbí ẹ lè fọkàn tán ẹ jù báyìí lọ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe nípa rẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́ náà, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí tí ọ̀rọ̀ fífọkàn tánni fi jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹlẹgẹ́ láàárín ọ̀pọ̀ òbí àtàwọn ọ̀dọ́.

Ó Máa Ń Dunni Gan-an!

Bíbélì sọ pé “ọkùnrin yóò . . . fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ìyẹn ò sì yọ àwọn obìnrin náà sílẹ̀. Yálà ọkùnrin ni ẹ́ tàbí obìnrin, bó o bá ti ń bàlágà, àgbà ń kàn ẹ́ bọ̀ nìyẹn, ìyẹn ni pé o máa tó dẹni tó lè dá gbé, tá á sì ní ìdílé tiẹ̀ bó bá yá.

Àmọ́ ṣá o, èèyàn ò lè kúrò lọ́dọ̀ọ́ kó sì ṣàdédé bára rẹ̀ nípò àgbà bí ẹni gba ẹnu ọ̀nà kan kọjá sí ẹnu ọ̀nà míì. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bí ẹni ń gun òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé, lèèyàn máa ń dépò àgbà. A gbà pé, ìwọ àtàwọn òbí ẹ lè máa ní èrò tó takora lórí ibi tó o ti dàgbà dé. Maria gbà pé àwọn òbí òun ò fọkàn tán òun tó bá dọ̀rọ̀ irú àwọn ọ̀rẹ́ tóun ń bá rìn, ó sọ pé: “Ọmọ ogún ọdún ni mí, ọ̀rọ̀ yìí ò sì yé dájà sílẹ̀. Àwọn òbí mi máa ń rò pé mi ò gbọ́n débi tí màá fi kúrò níbi tí kò yẹ ọmọlúwàbí. Mo ti gbìyànjú láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé mi ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kúrò níbi tí kò yẹ ọmọlúwàbí, àmọ́ ìyẹn ò tẹ́ wọn lọ́rùn!”

Bó ti hàn nínú ọ̀rọ̀ Maria, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ fífọkàn tánni dá awuyewuye sílẹ̀ láàárín àwọn òbí àtàwọn ọ̀dọ́. Ṣé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nílé tiyín náà nìyẹn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe lè jẹ́ káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ dáadáa? Bó bá sì jẹ́ pé wọn ò fọkàn tán ẹ mọ́ torí àwọn ìwà tí kò bójú mu kan tó o ti hù, kí lo lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà?

Fi Hàn Pé O Ṣeé Fọkàn Tán

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ pé: “Ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe torí àwọn ọ̀dọ́ ló ṣe kọ̀wé yìí, síbẹ̀ ìlànà inú rẹ̀ kàn wọ́n. Bó o bá ń fi hàn pó o yẹ lẹ́ni tó ṣeé fọkàn tán, àwọn èèyàn á máa fọkàn tán ẹ. Kì í ṣe pé o ò ní máa ṣàṣìṣe o. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tí kì í ṣàṣìṣe. (Oníwàásù 7:20) Ó dáa, ṣé ìwà tìẹ gan-an fi hàn pé o yẹ lẹ́ni táwọn òbí ẹ lè fọkàn tán?

Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A [ń] dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ṣé mo máa ń sòótọ́ fáwọn òbí mi nípa ibi tí mo lọ àtàwọn ohun tí mo ṣe?’ Gbọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà lórí kókó yìí.

Lori: “Mo máa ń kọ lẹ́tà sí ọmọkùnrin kan tí mo fẹ́ràn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láìjẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Àṣírí tú sáwọn òbí mi lọ́wọ́, wọ́n sì ní kí n jáwọ́ ńbẹ̀. Mo ṣèlérí fún wọn pé mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, àmọ́ mi ò jáwọ́. Odindi ọdún kan ni mo fi ń bá a lọ láti máa kọ lẹ́tà yìí táwọn òbí mi sì máa ń ká mi mọ́, màá tún ṣèlérí fún wọn pé mo máa jáwọ́ ńbẹ̀ sùgbọ́n mi ò jáwọ́. Nígbà tó yá, àwọn òbí mi ò tiẹ̀ wá fọkàn tán mi mọ́!”

Kí lo rò pó fà á táwọn òbí Lori ò fi fọkàn tán an mọ́, kí ni ì bá sì ti ṣe nígbà táwọn òbí rẹ̀ kọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro rẹ̀? Kọ ìdáhùn ẹ sínú àlàfo yìí.

․․․․․

Beverly: “Àwọn òbí mi ò gbẹ̀rí mi jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ọkùnrin, àmọ́ mo ti wá mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Mo máa ń báwọn ọmọkùnrin méjì kan tí wọ́n fi ọdún méjì jù mí lọ tage. Ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo fi máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, tá a bá sì jọ wà níbi àríyá, àwọn méjì yìí nìkan ni mo sábà máa ń bá sọ̀rọ̀. Odindi oṣù kan làwọn òbí mi ò fi jẹ́ kí n lo fóònù mi, tí wọn ò sì jẹ́ kí n lọ síbi témi àtàwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí ti lè pàdé.”

Kí lo rò pó fà á táwọn òbí Beverly kò fi fọkàn tán an lákòókò kan, kí ni ì bá ti ṣe kí wọ́n lè fọkàn tán an?

․․․․․

Annette: “Nígbà tí mo wà níléèwé girama, èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan mú bíà alágolo kọ̀ọ̀kan lọ sílé láti ibi àríyá kan ká lè fi gbádùn ara wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀ pé àwọn òbí wa ò ní fara mọ́ ọn. Màmá ọ̀rẹ́ mi rí bíà tó mú lọ sílé. Bó ṣe tú àṣírí tèmi náà nìyẹn. Èyí tó burú jù nínú gbogbo ẹ̀ ni pé inú mọ́mì mi ò dùn, ó sì hàn lójú wọn!”

Bó bá jẹ́ pé àbúrò rẹ ni Annette, ìmọ̀ràn wo lo máa fún un kí màmá yín lè tún padà fọkàn tán an?

․․․․․

Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Wọ́n Padà Fọkàn Tán Ẹ

Bó bá jẹ́ pé ìwà ẹ ló fà á táwọn òbí ẹ ò fi fọkàn tán ẹ bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ wọn tán wọ̀nyí ńkọ́? Ìyẹn náà ò tíì kọjá àtúnṣe. Àmọ́, ọ̀nà wo lo máa gbé e gbà?

Ó ṣeé ṣe káwọn òbí ẹ túbọ̀ fọkàn tán ẹ bó o ti ń fi hàn pé o níwà ọmọlúwàbí. A lè ṣàkàwé ẹ̀ lọ́nà yìí: Fojú inú yàwòrán ọkùnrin kan tó jẹ báńkì lówó. Bó bá ń san gbèsè rẹ̀ déédéé, àwọn òṣìṣẹ́ báńkì yẹn máa fọkàn tán an, ìyẹn sì lè mú kí wọ́n yá a lówó nígbà míì. Bọ́ràn ṣe rí nínú ilé náà nìyẹn. Bó o bá fi hàn pé o yẹ lẹ́ni tí wọ́n lè fọkàn tán, kódà nínú àwọn ohun tí kò tó nǹkan pàápàá, ó ṣeé ṣe káwọn òbí rẹ túbọ̀ fọkàn tán ẹ nígbà míì.

Ohun tí Annette wá mọ̀ nígbà tó yá nìyẹn. Ó sọ pé, “Tó o bá ṣì kéré, o ò lè fi bẹ́ẹ̀ mọyì kí wọ́n fọkàn tán ẹ. Ní báyìí, tágbà ti wá ń dé, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n máa hùwà lọ́nà tá á jẹ́ káwọn òbí mi máa bá a nìṣó láti fọkàn tán mi.” Ẹ̀kọ́ wo lo lè rí kọ́ nínú èyí? Dípò kó o máa ṣàròyé pé àwọn òbí ẹ ò fọkàn tán ẹ, o ò kúkú ṣe máa sa gbogbo ipá ẹ láti hùwà tá á jẹ́ kó o ṣeé fọkàn tán.

Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn òbí ẹ lè fọkàn tán ẹ tó bá dọ̀rọ̀ àwọn nǹkan tá a tò sísàlẹ̀ yìí? Fi àmì sí àpótí tó bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìwà tó bá ỵẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí.

□ Dídé sílé lákòókò táwọn òbí mi bá fọwọ́ sí

□ Ṣíṣe nǹkan lákòókò tó yẹ

□ Píparí àwọn iṣẹ́ ilé

□ Mímú kí iyàrá mi wà ní mímọ́ tónítóní

□ Lílo tẹlifóònù

□ Mímú àwọn ìlérí mi ṣẹ

□ Ṣíṣọ́wó ná

□ Jíjí lákòókò

□ Sísọ òótọ́

□ Gbígba àṣìṣe mi kí n sì tọrọ àforíjì

□ Àwọn nǹkan míì

O ò ṣe pinnu pé wàá fi hàn pé o yẹ lẹ́ni tó ṣeé fọkàn tán nínú àwọn nǹkan tó o fàmì sí lókè wọ̀nyí? Fetí sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà [rẹ] àtijọ́ ṣe déédéé.” (Éfésù 4:22) Jẹ́ “kí Bẹ́ẹ̀ ni [rẹ] túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni.” (Jákọ́bù 5:12) “Kí olúkúlùkù . . . máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.” (Éfésù 4:25) “Jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí [rẹ] nínú ohun gbogbo.” (Kólósè 3:20) Bó bá yá, ìlọsíwájú rẹ máa fara hàn kedere sáwọn ẹlòmíì, títí kan àwọn òbí rẹ.—1 Tímótì 4:15.

Àmọ́ bó o bá ṣì ń nímọ̀lára pé àwọn òbí ẹ ò fọkàn tán ẹ láìka gbogbo ìsapá rẹ sí ńkọ́? O ò ṣe kúkú bá wọn sọ ọ́? Dípò kó o máa ṣàròyé pé ó yẹ kí wọ́n túbọ̀ fọkàn tán ẹ, ńṣe ni kó o fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ohun tí wọ́n rò pé ó yẹ kó o ṣe tí wọ́n á fi gbẹ̀rí ẹ jẹ́. Ṣàlàyé tó ṣe kedere lórí ibi tó ò ń lọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.

Má ṣe retí pé kí nǹkan yí padà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kò sí àníàní pé wọ́n á fẹ́ rí i dájú pé o mú àwọn ìlérí ẹ ṣẹ. Lo àǹfààní yẹn láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o yẹ lẹ́ni tí wọ́n lè fọkàn tán. Bó bá wá yá, ó ṣeé ṣe káwọn òbí ẹ túbọ̀ fọkàn tán ẹ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Beverly tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan nìyẹn. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ kékeré kọ́ lèèyàn máa ṣe kí wọ́n tó lè fọkàn tán an, ó sì rọrùn láti pàdánù rẹ̀,” ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “wọ́n ti ń fọkàn tán mi báyìí, ìyẹn sì ń múnú mi dùn gan-an!”

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Kí ló lè mú káwọn òbí ẹ máa lọ́ra láti fọkàn tán ẹ, kódà lẹ́yìn tó o ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti mú kí wọ́n gbẹ̀rí ẹ jẹ́?

◼ Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o sọ tinú ẹ fáwọn òbí ẹ, bó o bá fẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fọkàn tán ẹ?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]

Sa gbogbo ipá ẹ láti máa hùwà tá á jẹ́ kó o ṣeé fọkàn tán

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kíkúrò lọ́dọ̀ọ́ dà bí ìgbà téèyàn ń gun òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé títí tá á fi dépò àgbà, táwọn ẹlòmíì á sì lè fọkàn tán an

[Àwòrán]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌGBÀ TÓ O BÁ DÀGBÀ

ÌGBÀ ÌBÀLÁGÀ

ÌGBÀ ỌMỌDÉ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́