Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ayé Yìí Ń Bọ̀ Wá Di Párádísè?
ÀWỌN ìtàn àtẹnudẹ́nu tó ti dàṣà láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè bí Íjíbítì, Mẹ́síkò, Peru àti Tibet fi hàn pé ayé kan tó rójú ti wà nígbà kan rí, ìyẹn nígbà táwọn èèyàn kì í dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run, tí wọn kì í ṣàìsàn tí wọn kì í sì í kú. Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu yìí tún sọ bí ìran èèyàn ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ń tọwọ́ bọ àwọn ìtàn ọ̀hún lójú, tí wọ́n sì ń ṣe àbùmọ́ rẹ̀, síbẹ̀ àwọn ìtàn náà jọra débi pé ó ṣòro láti sọ pé ó kàn ṣèèṣì rí bẹ́ẹ̀ ni. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ti parí èrò sí pé àwọn ìtàn yẹn ti ní láti ṣẹlẹ̀ rí lóòótọ́. Ká sòótọ́, ohun táwọn ìtàn yẹn ń gbé wá séèyàn lọ́kàn jọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, ohun tá a rí kà nínú àwọn orí wọ̀nyẹn ò díjú bí àwọn ọ̀rọ̀ inú ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó pé pérépéré.—2 Tímótì 3:16.
Ìbẹ̀rẹ̀ Pípé
Ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, inú ọgbà Édẹ́nì tó tutù yọ̀yọ̀ ló fi wọ́n sí. Ara wọn jí pépé, wọ́n sì láǹfààní láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Àmọ́, ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá ló fa ikú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8-17; Róòmù 5:12) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún Ádámù àti Éfà ni pé kí wọ́n ‘máa so èso, kí wọ́n sì di púpọ̀, kí wọ́n sì kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.’ (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Bí gbogbo ayé ì bá ṣe di Párádísè nìyẹn, táwọn ẹ̀dá èèyàn pípé á sì máa láyọ̀ torí pé Ọlọ́run lá á máa darí wọn tá á sì máa ṣàkóso wọn.
Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti mú ìpinnu Ẹlẹ́dàá wọn ṣẹ kí wọ́n sì máa gbé lórí ilẹ̀ ayé fún àkókò tó lọ kánrin. Síbẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run máa mú ohun tó ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé yìí ṣẹ. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde [kì] yóò . . . padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe . . . àṣeyọrí sí rere.” (Aísáyà 55:11) Kódà, ọ̀kan lára àwọn olórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì ní í ṣe pẹ̀lú ìpinnu Jèhófà láti sọ ayé yìí di Párádísè níbi táwọn tó ń fàwọn ànímọ́ rẹ̀ ṣèwà hù á máa gbé títí láé.—Róòmù 8:19-21.
“Ìwọ Yóò Wà Pẹ̀lú Mi ní Párádísè”
Gbàrà tí Ádámù àti Éfà ti dẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa mú “irú ọmọ” kan jáde tó máa pa Sátánì Èṣù “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà” run tó sì máa fọ́ àwọn iṣẹ́ ibi ọwọ́ rẹ̀ túútúú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Ìṣípayá 12:9; 1 Jòhánù 3:8) Jésù Kristi ló wá di àkọ́kọ́ lára “irú ọmọ” yẹn. (Gálátíà 3:16) Pabanbarì ẹ̀ ni pé, Ọlọ́run ti yàn án ṣe Ọba Ìjọba kan ní ọ̀run, èyí tó máa ṣàkóso lé gbogbo ayé lórí.—Dáníẹ́lì 7:13, 14; Ìṣípayá 11:15.
Gbogbo ohun tí Ádámù kọ̀ láti ṣe ni Kristi máa ṣe láṣeyọrí. Kódà, Bíbélì pe Jésù ní “Ádámù ìkẹyìn.” (1 Kọ́ríńtì 15:45) Yàtọ̀ síyẹn, nínú àdúrà olúwa, Jésù fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ń bọ̀ wá dá sí ọ̀ràn ayé yìí, ó ní: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àkóso ayé máa tó bọ́ sọ́wọ́ Jésù, kò fì í lẹ́nu nígbà tó wà láyé láti sọ fún aṣebi tó ronú pìwà dà tí wọ́n kàn mọgí lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Párádísè orí ilẹ̀ ayé ni Jésù ní lọ́kàn torí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ayé yìí rí nìyẹn látìbẹ̀rẹ̀. Bíbélì sì kín òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn. Gbé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí yẹ̀ wò.
“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sáàmù 72:16) “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀.” (Òwe 2:21) “Wọn [àwọn aláìlẹ́bi] kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.
Níbàámu pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tò sókè yìí, Jésù sọ nínú ìwàásù rẹ̀ tó lókìkí, tó ṣe lórí òkè pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Kò sí àníàní pé “Párádísè” orí ilẹ̀ ayé ni ibí yìí ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, kì í ṣe ti ọ̀run.
Ohun Táwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Jinlẹ̀ Sọ
Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ gbà pé ayé máa di Párádísè nígbà Ìjọba Kristi. Joseph A. Seiss, tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, sọ pé: “Nígbà tí Mèsáyà bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso, gbogbo ayé ló máa padà rí . . . bó ṣe yẹ kó rí . . . ká ní Ádámù ò dẹ́ṣẹ̀ ni.” Nínú àlàyé tí wọ́n ṣe nínú ìwé The New Testament for English Readers, Henry Alford kọ̀wé pé: “Ìjọba Ọlọ́run . . . ò ní fìgbà kankan dáwọ́ iṣẹ́ dúró títí tó fi máa di ìjọba tó ń ṣàkóso ayé, táwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ á jogún ayé . . . , nígbẹ̀yìngbẹ́yín a máa sọ ọ́ dọ̀tun, ìbùkún rẹ̀ á sì wà fún àkókò tó lọ kánrin kése.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ ti Henry Alford.
Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó ni Isaac Newton, ó sì máa ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì. Òun náà kọ̀wé pé: “Àwọn èèyàn á máa bá a lọ láti gbé lórí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ọjọ́ ìdájọ́, kì í ṣe fún kìkì ẹgbẹ̀rún ọdún, bí kò ṣe títí láé.”
Torí pé Jésù Kristi lá máa ṣàkóso ayé ní tààràtà, a ò ní gbúròó ìwà ibi mọ́ láé àti láéláé. (Aísáyà 11:1-5, 9) Bó ṣe máa rí nìyẹn, ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé á di Párádísè, ìyẹn á sì jẹ́ fún ògo Olùṣẹ̀dá rẹ̀ títí láé.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé àtàwọn èèyàn?—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
◼ Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa gbé ṣe?—Mátíù 6:10.
◼ Kí nìdí tá ò fi ní gbúròó ìwà ibi mọ́ láé?—Aísáyà 11:1-5, 9.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
“Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 5:5