Ṣé Ilẹ̀ Ayé Lè Pèsè Ohun Tí Ìran Tó Ń Bọ̀ Lọ́jọ́ Iwájú Máa Nílò?
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KÁNÁDÀ
◼ Lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan àtàwọn òléwájú nínú ṣíṣe àyẹ̀wò àyíká ti wà lẹ́nu àyẹ̀wò ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí apá kan ìwádìí tí wọ́n pè ní Millennium Ecosystem Assessment tàbí [MA], wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé àbájáde àkọ́kọ́ jáde lára ìwádìí wọ́n ni. Díẹ̀ rèé lára ibi tí wọ́n fẹnu ọ̀rọ̀ ìwádìí náà jóná sí: Láti bí àádọ́ta ọdún sígbà tá a wà yìí làwọn èèyàn ti ń nílò oúnjẹ, omi tó mọ́, igi gẹdú, òwú àti epo rọ̀bì púpọ̀ sí i. Ìyẹn sì ti mú kí ọ̀pọ̀ ìyípadà tá ò tíì rírú ẹ̀ rí máa ṣẹlẹ̀ láyìíká wa, débi tí kò fi ní rọrùn fún ilẹ̀ ayé láti pèsè ohun táwọn ìran tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú máa nílò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé lọ́nà tó fi lè máa mú èso tàbí irúgbìn jáde, káwọn igbó ẹgàn máa sẹ́ ìdọ̀tí tó wà nínú atẹ́gùn, kí wọ́n sì máa sọ ilẹ̀ di eléso nípa fífa omi látinú agbami òkun, aráyé ti fi àṣìlò sọ èyí di ohun tó ṣòro. Kódà, wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa gbogbo ẹran ìgbẹ́ tó wà nínú igbó tán.
Ìwé ìròyìn kan lórílẹ̀-èdè Kánádà, ìyẹn Globe and Mail sọ pé: “Àwọn èèyàn ń ba ayé jẹ́ gan-an lọ́nà tá ò rírú ẹ̀ rí débi pé bí wọn ò bá ṣọ́ra àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ò ní lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ mọ́, ìyẹn sì lè fa àrùn, pípa igbó run tàbí pípa àwọn ohun alààyè tó wà nínú omi run.” Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé: “Àwọn ilẹ̀ àbàtà, ẹgàn, pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí koríko hù sí, ẹnu odò, odò ẹja láwọn etíkun àtàwọn ibùgbé ohun alààyè míì tó máa ń sọ afẹ́fẹ́, omi àtàwọn nǹkan tó ń so ìwàláàyè ró dọ̀tun ni wọ́n ti bà jẹ́ kọjá ààlà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àjọ MA tó ń ṣàyẹ̀wò àyíká gbà pé ọwọ́ àwùjọ ẹ̀dá ló kù sí láti pẹ̀rọ̀ sí ìṣòro táráyé ń kó bá àyíká, wọ́n sọ pé kí èyí tó lè ṣeé ṣe àfi “káwọn èèyàn yáa tètè dẹ́kun bíba àyíká jẹ́.”
Ṣé Ilẹ̀ Ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ lè bọ́ lọ́wọ́ gbogbo wàhálà yìí? Dájúdájú! Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìkáwọ́ wa ni Ọlọ́run fi gbogbo ohun tó dá sí, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa ká má bàa ṣe àyíká wa báṣubàṣu. (Sáàmù 115:16) Àmọ́ ṣá o, ìgbà tí Ọlọ́run bá dá sí ọ̀ràn àyíká àtàwọn ohun alààyè tó ń gbénú ẹ̀ làwọn nǹkan tó lè padà sípò. ‘Olùṣẹ̀dá Atóbilọ́lá’ ṣèlérí pé òun á yí àfiyèsí òun sórí ilẹ̀ ayé, òun á sì “fún un ní ọ̀pọ̀ yanturu.” (Jóòbù 35:10; Sáàmù 65:9-13) Agbami òkun àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀ wà lára ibi tí Ọlọ́run máa yí àfiyèsí rẹ̀ sí torí pé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Olùṣẹ̀dá lágbára lórí agbami òkun. (Sáàmù 95:5; 104:24-31) Ó sì dájú pé ohun tó ṣèlérí máa ṣẹ torí pé Ọlọ́run “kò lè purọ́.”—Títù 1:2.
Ó fini lọ́kàn balẹ̀ láti mọ̀ pé ilẹ̀ ayé á pèsè ohun tí ìran tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú máa nílò. Èyí ń mú kí gbogbo àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa yìn ín nítorí ọgbọ́n, agbára, àti oore rẹ̀ tó pọ̀ yanturu, ó sì tún ń mú kí wọ́n máa gbé e lárugẹ nítorí gbogbo ọ̀nà tó ń gbà fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ gbogbo ohun tó dá.—Sáàmù 150:1-6.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]
Àwòrán òbìrí ayé: Fọ́tò NASA