ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 6/15 ojú ìwé 3-5
  • Ṣé Pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé Fẹ́ Parẹ́ Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé Fẹ́ Parẹ́ Ni?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpèjúwe Mọ̀nàǹkọyẹ̀rì Nípa “Ọjọ́ Ìparun”
  • Ṣíṣe Àtúnṣe Bí Ènìyàn Ṣe Ń Ṣi Ilẹ̀ Ayé Lò
  • Ó Ṣeé Ṣe
  • Ṣé Àwọn Èèyàn Ò Ní Ba Ayé Yìí Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé
    Jí!—2023
  • Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Ẹlẹgẹ́—Báwo Ni Ọjọ́ Ọ̀la Yóò Ṣe Rí?
    Jí!—1996
  • Ìjábá Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Yóò Ha Pa Ayé Wa Run Bí?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 6/15 ojú ìwé 3-5

Ṣé Pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé Fẹ́ Parẹ́ Ni?

ÒPIN ọ̀rúndún ogún ti sún mọ́lé, ọ̀rúndún kọkànlélógún sì ti dé tán. Lójú ìwòye èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pé àjálù ti rọ̀ dẹ̀dẹ̀ ń ṣe kàyéfì báyìí pé àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ pé mìmì ńlá kan fẹ́ mi ayé láìpẹ́.

O lè ti ṣàkíyèsí àwọn àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn tí ń sọ̀rọ̀ nípa èyí—kódà odindi ìwé lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ní ti àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún, kí a ṣì máa wò ó ná. Àwọn kan tọ́ka sí i pé dídé òpin ọdún 2000 kàn jẹ́ títi orí ọdún kan bọ́ sí òmíràn ni (tàbí ìṣẹ́jú kan, láti ọdún 2000 sí 2001), wọ́n sì rò pé kì í ṣe nǹkan bàbàrà. Ohun tí ó kan ọ̀pọ̀ ènìyàn gbọ̀ngbọ̀n ni ọjọ́ ọ̀la pípẹ́títí ti pílánẹ́ẹ̀tì wa.

Àsọtẹ́lẹ̀ kan tí àwọn ènìyàn ń ránnu mọ́ lóde òní ni pé nígbà tí ó bá ṣe—bó pẹ́ ni bó yá ni—pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé tìkára rẹ̀ yóò pa run yán-án yán-án. Ṣe àgbéyẹ̀wò kìkì díẹ̀ lára irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ jàǹbá bẹ́ẹ̀.

Nínú ìwé rẹ̀, The End of the World—The Science and Ethics of Human Extinction, tí a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní ọdún 1996, John Leslie, tí í ṣe òǹkọ̀wé àti onímọ̀ ọgbọ́n orí, mú àbá mẹ́ta wá nípa bí ìwàláàyè ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé ṣe lè dópin. Ó kọ́kọ́ béèrè pé: “Ǹjẹ́ ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí a fi bọ́ǹbù átọ́míìkì jà ha lè fi òpin sí ìran ènìyàn?” Ó wá fi kún un pé: “Ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó ṣẹlẹ̀ . . . ni àkúrun nípasẹ̀ ìtànṣán olóró: àrùn jẹjẹrẹ, ìbàjẹ́ ètò tí ń dènà àrùn tí yóò fi jẹ́ pé àwọn àrùn tí ń ran ènìyàn yóò gbèèràn, tàbí bíbí ọ̀pọ̀ abirùn ọmọ. Bákan náà, àwọn kòkòrò tíntìntín tí ó ṣe pàtàkì fún ire àyíká lè ṣègbé.” Àbá kẹta tí Ọ̀gbẹ́ni Leslie gbé kalẹ̀ ni pé ìràwọ̀ onírù tàbí asteriod lè kọlu ilẹ̀ ayé: “Ó jọ pé iye àwọn ìràwọ̀ onírù àti asteroid tí ó tó ẹgbẹ̀rún méjì ni ipa ìrìnnà wọn fi hàn pé wọ́n lè ṣèèṣì kọlu Ilẹ̀ Ayé lọ́jọ́ kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì fẹ̀ tó kìlómítà kan sí mẹ́wàá ní ìbú. Àwọn ìràwọ̀ onírù àti asteroid díẹ̀ wà tí ó tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ (iye wọn ṣòro fojú bù), àwọn kéékèèké sì wà tí ó pọ̀ níye gan-an.”

Àpèjúwe Mọ̀nàǹkọyẹ̀rì Nípa “Ọjọ́ Ìparun”

O lè ronú nípa Paul Davies, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mìíràn, tí í ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n ní Yunifásítì ti Adelaide, Australia. Ìwé ìròyìn náà, Washington Times, pè é ní “òǹkọ̀wé tí ó gbajúmọ̀ jù lọ lágbàáyé nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.” Ní ọdún 1994, ó kọ ìwé náà The Last Three Minutes, tí a wá mọ̀ báyìí sí “ìyá tí ó bí gbogbo ìwé yòókù nípa ọjọ́ ìparun.” A pe orí kìíní ìwé náà ní “Ọjọ́ Ìparun,” ó sì ṣàlàyé ohun àfinúrò tí ó lè ṣẹlẹ̀ bí ìràwọ̀ onírù kan bá kọlu pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé. Kà lára àpèjúwe rẹ̀ tí ń mú ara sẹ́gìíìrì:

“Pílánẹ́ẹ̀tì yìí bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì bí ẹni pé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìsẹ̀lẹ̀ ni ó ń mì í tì-tì-tì. Ìgbì ọ̀gbálẹ̀gbáràwé gbá gbogbo ojú ilẹ̀ ayé lọ fáú, ó wó gbogbo ilé kanlẹ̀ bẹẹrẹbẹ, ó rún ohun gbogbo wómúwómú. Ó ká ilẹ̀ bí ìgbà tí a bá ká ẹní tí ó fi wú gọnbu di àwọn òkè ayọná-yèéfín tí ó ga ní ọ̀pọ̀ kìlómítà, ó tú ohun tí ó wà nínú Ilẹ̀ Ayé síta ní wíwa ihò tí ó fẹ̀ tó àádọ́jọ kìlómítà. . . . Pàǹtírí tìrìgàngàn kù gbùù sínú afẹ́fẹ́, ó sì bo oòrùn lójú jákèjádò pílánẹ́ẹ̀tì. Wàyí o, bílíọ̀nù ìpẹ́pẹ́ ìràwọ̀ aṣekúpani tí ń jó lọ́úlọ́ú ni ó rọ́pò ìmọ́lẹ̀ oòrùn, ó mú kí ilẹ̀ gbóná yoyo, bí àwọn ohun tí ó tú síta ti ń dà wìì láti òfuurufú padà sílẹ̀.”

Ọ̀jọ̀gbọ́n Davies ń bá a lọ láti rí ìṣẹ̀lẹ̀ àfinúrò yìí gẹ́gẹ́ bí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà pé ìràwọ̀ onírù tí a mọ̀ sí Swift-Tuttle yóò kọlu ilẹ̀ ayé. Ó tún ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé bí irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní àìpẹ́ ọjọ́, nínú èrò rẹ̀, “bó pẹ́ bó yá Swift-Tuttle, tàbí nǹkan kan tí ó dà bí rẹ̀, yóò kọlu Ilẹ̀ Ayé.” Ó gbé ìparí èrò rẹ̀ ka àbá náà pé àwọn ohun tí ó tó 10,000, tí wọ́n fẹ̀ ní ìdajì kìlómítà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni wọ́n ń lọ káàkiri ní ipa ìrìnnà sísokọ́ra ti Ilẹ̀ Ayé.

Ìwọ ha gbà gbọ́ pé irú ohun bíbanilẹ́rù bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ ní ti gidi? Ó yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó gbà gbọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n ń fi ara wọn lọ́kàn balẹ̀ pé kì yóò ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ayé wọn. Àmọ́ ṣá o, èé ṣe tí pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé yóò tilẹ̀ fi pa run—yálà láìpẹ́ tàbí ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sí ìgbà tí a wà yìí? Dájúdájú, ilẹ̀ ayé tìkára rẹ̀ kọ́ ni ó ń dá wàhálà sílẹ̀ fún àwọn tí ń gbé inú rẹ̀, ì báà jẹ́ ènìyàn tàbí ẹranko. Kàkà bẹ́ẹ̀, kì í ha ṣe ènìyàn tìkára rẹ̀ ni okùnfà ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìṣòro ọ̀rúndún ogún yìí, títí kan ṣíṣeéṣe kí wọ́n “run ilẹ̀ ayé” pátápátá?—Ìṣípayá 11:18.

Ṣíṣe Àtúnṣe Bí Ènìyàn Ṣe Ń Ṣi Ilẹ̀ Ayé Lò

Nípa pé ó ṣeé ṣe kí ènìyàn tìkára rẹ̀ ba ilẹ̀ ayé jẹ́ pátápátá nípasẹ̀ ṣíṣì í lò àti ìwọra rẹ̀ ńkọ́? Ó hàn gbangba pé a ti ba àwọn ibì kan jẹ́ gan-an lórí ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ pípa igbó run, bíba àyíká jẹ́ lọ́nà tí kò mọ níwọ̀n, àti bíba omi jẹ́. Àwọn òǹkọ̀wé náà, Barbara Ward àti René Dubos ṣàkópọ̀ èyí lọ́nà tí ó gún régé ní nǹkan bí ọdún 25 sẹ́yìn nínú ìwé wọn tí a ń pè ní Only One Earth: “Lájorí àgbègbè mẹ́ta tí a ti ń ba àyíká jẹ́ tí a gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò—afẹ́fẹ́, omi, àti ilẹ̀—ni ó para pọ̀ jẹ́ àwọn ohun ìpìlẹ̀ pàtàkì mẹ́ta tí ó ṣe kókó fún ìwàláàyè lórí pílánẹ́ẹ̀tì wa.” Ipò nǹkan kò sì tíì sunwọ̀n sí i ní ti gidi láti ìgbà yẹn wá, àbí ó ti sunwọ̀n sí i?

Nígbà tí a bá ń ronú nípa ṣíṣeéṣe kí ènìyàn fi ìwà ẹ̀gọ̀ rẹ̀ run ilẹ̀ ayé, a lè mọ́kàn le nípa ríronú nípa agbára àràmàǹdà ti ìmúsọjí àti ti àmúdọ̀tun tí pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé ní. Nígbà tí René Dubos ń ṣàlàyé agbára àgbàyanu ti ìpadàbọ̀sípò yìí, ó ṣe àkíyèsí tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí nínú ìwé rẹ̀ mìíràn, The Resilience of Ecosystems:

“Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bẹ̀rù pé ó ti pẹ́ jù kí a tó wá jí gìrì sí ìbàjẹ́ tí a ti ṣe sí àyíká, nítorí pé ìbàjẹ́ tí a ti ṣe sí àyíká kò ní àtúnṣe. Nínú èrò tèmi, kò sídìí fún ojú ìwòye àìsí àtúnṣe yìí, nítorí pé àyíká ní agbára pípabanbarì láti padà bọ̀ sípò láti inú ipò ìbàjẹ́ tí ó burú jáì.

“Àyíká ní oríṣiríṣi ohun èlò amúṣẹ́yá fún mímú ara rẹ̀ padà bọ̀ sípò. . . . Ìwọ̀nyí ń jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún àyíká láti borí ìṣòro nípa wíwulẹ̀ máa dá a padà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ sí ipò ìwàdéédéé ti ìpilẹ̀ṣẹ̀.”

Ó Ṣeé Ṣe

Àpẹẹrẹ títayọ kan lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí ni ti ìfọ̀mọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ sí odò Thames olókìkí ní London. Ìwé náà, The Thames Transformed, láti ọwọ́ Jeffery Harrison àti Peter Grant, ṣàkọsílẹ̀ àṣeyọrí arabaríbí yìí tí ó fi ohun tí ó lè jẹyọ hàn bí àwọn ènìyàn bá pawọ́ pọ̀ ṣiṣẹ́ fún àǹfààní gbogbo gbòò. Mọ́gàjí Edinburgh ti ilẹ̀ Britain kọ̀wé nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú ìwé rẹ̀ pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìtàn àṣeyọrí ńláǹlà rèé tí ó yẹ kí a tẹ̀ jáde, àní láìka òtítọ́ náà sí pé èyí lè fún àwọn kan ní ìṣírí láti ronú pé ìṣòro dídáàbòbo àyíká kò le tó bí wọ́n ti rò tẹ́lẹ̀. . . . Gbogbo wọn lè fọkàn balẹ̀ nítorí ohun tí a gbéṣe ní Thames. Ìhìn rere náà ni pé ó ṣeé ṣe, ohun tí wọ́n bá dáwọ́ lé sì lè kẹ́sẹjárí.”

Nínú àkòrí náà “Ìfọ̀mọ́ Ńláǹlà Náà,” Harrison àti Grant kọ̀wé lọ́nà ìwúrí nípa ohun tí a gbéṣe ní 50 ọdún tí ó ti kọjá pé: “Ní ìgbà àkọ́kọ́ lágbàáyé, odò kan tí a ń lò fún iṣẹ́ òwò, tí a bà jẹ́ gidigidi, ni a ti mú padà bọ̀ sípò tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àwọn ẹyẹ awọ́dò àti ẹja ti padà kún inú rẹ̀ ṣọ́ṣọ́. Pé irúfẹ́ àmúdọ̀tun bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ wéréwéré, lábẹ́ ipò tí ó kọ́kọ́ jọ pé kò ti lè ṣẹlẹ̀ láé, jẹ́ ìṣírí àní fún olùdáàbòbo ẹranko tí ó gbà pé kò sí àtúnṣe mọ́ rárá.”

Harrison àti Grant wá ṣàlàyé àmúdọ̀tun náà: “Odò náà kàn ń bà jẹ́ ṣáá ni bí ọdún ti ń gorí ọdún, kí ó tó wá di pé àjálù ìkẹyìn já lù ú nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nígbà tí onírúurú ẹ̀gbin bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn sínú rẹ̀. Àwọn ọdún 1940 sí 1950 ni ó burú jù lọ fún odò Thames. Odò náà kò yàtọ̀ sí ihò ṣáláńgá; omi náà di dúdú, kò ní afẹ́fẹ́ oxygen kankan, nígbà tí ó sì di àwọn oṣù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, òórùn burúkú tí ń bù tìì láti inú odò Thames bo gbogbo àgbègbè náà. . . . Àwọn ẹja tí ó kún inú rẹ̀ tìrìgàngàn tẹ́lẹ̀ ti lọ, yàtọ̀ sí ìwọ̀nba àwọn ẹja àdàgbá díẹ̀ tí ó yè é nítorí agbára tí wọ́n ní láti fa afẹ́fẹ́ símú ní tààràtà láti ojú omi. Àwọn ẹyẹ tí ó wà ní àwọn àgbègbè inú ìlú tí a kọ́lé sí láàárín ìlú London àti Woolwich ṣẹ́ ku ìwọ̀n kéréje pẹ́pẹ́yẹ omi àti ògbùgbú, wọ́n sì wà láàyè nítorí pé àwọn ọkà tí ń dàálẹ̀ ní ibùdókọ̀ ojú omi ni wọ́n ń jẹ dípò oúnjẹ wọn àtilẹ̀wá. . . . Ta ni ì bá gbà nígbà yẹn pé ìyípadà bìrí yẹn máa tó ṣẹlẹ̀? Láàárín ọdún mẹ́wàá, àgbègbè odò kan náà yẹn máa tó yí padà láti inú ipò ṣíṣàìní ẹ̀dá abìyẹ́ kankan di ilé ààbò fún ọ̀pọ̀ onírúurú ẹyẹ omi, títí kan iye tí ó pọ̀ tó 10,000 ẹ̀dá abìyẹ́ inú igbó àti 12,000 àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò tí wọ́n wá ń lo ìgbà òtútù níbẹ̀.”

Àmọ́ ṣá o, èyí ṣàpèjúwe kìkì àmúdọ̀tun kan ṣoṣo ní ibi kékeré kan ní àgbáyé. Síbẹ̀síbẹ̀, a lè rí ohun púpọ̀ kọ́ láti inú àpẹẹrẹ yìí. Ó fi hàn pé kò yẹ kí a rò pé pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé yóò parẹ́ nítorí àṣìlò, ìwọra, àti ìwà àìnírònú ènìyàn. Ẹ̀kọ́ bíbójúmu àti ìsapá àjùmọ̀ṣe fún ire gbogbo aráyé lè ran ilẹ̀ ayé lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe ìbàjẹ́ ńláǹlà tí a ṣe sí àwọn ohun alààyè, àyíká, àti ojú ilẹ̀ pàápàá. Ṣùgbọ́n ewu ìparun láti ọwọ́ àwọn ohun tí ó lè fò wá láti ojúde òfuurufú ńkọ́, bí ìràwọ̀ onírù tàbí asteroid tí ń fò káàkiri?

Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yìí pèsè ìdáhùn tí ó tẹ́ni lọ́rùn sí irú ìbéèrè tí ń dani láàmú bẹ́ẹ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Ẹ̀kọ́ àti ìsapá àjùmọ̀ṣe lè ran ilẹ̀ ayé lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe ìbàjẹ́ ńláǹlà tí a ṣe sí i pàápàá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́