“Ẹ Ṣeun Púpọ̀ fún Ìfẹ́ Àtọkànwá Tẹ́ Ẹ Ní Sáwọn Èèyàn”
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ RỌ́ṢÍÀ
◼ Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lápá ìlà oòrùn ìlú Chita ní Siberia máa ń ṣèpàdé nínú kíláàsì ilé ìwé kan kí wọ́n tó kó lọ sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Àwọn ọ̀gá iléèwé yẹn kọ lẹ́tà ìdúpẹ́ sí ìjọ yẹn torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn hùwà ọmọlúwàbí, wọ́n fi kíláàsì náà sílẹ̀ ní mímọ́ tónítóní, wọ́n sì tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ níbẹ̀ ṣe.
Lára ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà náà kà pé: “Ẹ ṣeun púpọ̀ fún ìfẹ́ àtọkànwá tẹ́ ẹ ní sáwọn èèyàn, gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ̀ ń bá pàdé ló mọ̀ bẹ́ẹ̀, a sì mọrírì iṣẹ́ míṣọ́nnárì àti iṣẹ́ afẹ́nifẹ́re tẹ́ ẹ̀ ń ṣe fún gbogbo èèyàn. A ò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ lára yín fún ọ̀pọ̀ ọdún tẹ́ ẹ fi lo iléèwé wa, ẹ ti jẹ́ ká rí i pé àwọn èèyàn tó bá gba Ọlọ́run gbọ́ máa ń níwà ọmọlúwàbí, wọ́n mọṣẹ́ wọn níṣẹ́, wọ́n jẹ́ onínúure, wọ́n ní àfojúsùn, wọ́n ní ìgbàgbọ́, wọ́n sì mọ ohun tí wọ́n fẹ́ fayé wọn ṣe.” Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn sí ohun tí wọ́n sọ nípa wa yẹn.
◼ Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [5,500] kìlómítà sí apá ìwọ̀ oòrùn ìlú Chita tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà lọ síbi ayẹyẹ àkànṣe kan táwọn aláṣẹ àgbègbè St. Petersburg pè wá sí. Kí nìdí tí wọ́n fi pè wá? Ìdí ni pé lẹ́yìn tí yìnyín tó máa ń bo ilẹ̀ lọ́dọọdún bá ti yọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè náà máa ń palẹ̀ pàǹtírí mọ́ lójú ọ̀nà kan tó gùn tó ọgọ́ta kìlómítà tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ jìn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílùú náà. Aṣojú ìjọba fún ẹni tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa rán lọ níwèé ẹ̀rí kan tó fi hàn pé ìjọba mọrírì iṣẹ́ rere tó ń ṣàwọn ará àdúgbò láǹfààní táwọn ará wa máa ń ṣe ládùúgbò yẹn. Inú àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ dùn, wọ́n sì pàtẹ́wọ́. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ọ̀hún ṣi Jèhófà pè, ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà níbẹ̀ yára sọ bó ṣe yẹ kó pè é gan-an, ìyẹn fi hàn pé wọ́n mọ orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì mọ àwọn tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọn.
Olórí ohun tó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀ ni pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wàásù fún gbogbo èèyàn, a sì ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ [150,000] lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà báyìí. A fẹ́ láti máa bá a nìṣó láti fi “ìfẹ́ àtọkànwá hàn sáwọn èèyàn” nípa wíwàásù ìhìn rere tó ń tuni nínú látinú Bíbélì fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ gbọ́.—Mátíù 22:39.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Wọ́n fún ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà nílùú Rọ́ṣíà ní ìwé ẹ̀rí fún iṣẹ́ rere táwọn ará wá ṣe