ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/08 ojú ìwé 14-15
  • Ṣó Yẹ Ká Máa Forúkọ Oyè Pe Àwọn Èèyàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó Yẹ Ká Máa Forúkọ Oyè Pe Àwọn Èèyàn?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ Ò Túmọ̀ sí Pé A Gba Tiwọn
  • Bí Pọ́ọ̀lù Ṣe Lo Orúkọ Oyè
  • Ọlá Tó Mọ Níwọ̀n
  • “Mo Ké Gbàjarè sí Késárì!”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Pọ́ọ̀lù Fìgboyà Wàásù Níwájú Àwọn Lóókọ-Lóókọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Tẹ́wọ́ Gba Ìhìn Ìjọba Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Bọla fun Oriṣi Eniyan Gbogbo
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 10/08 ojú ìwé 14-15

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Yẹ Ká Máa Forúkọ Oyè Pe Àwọn Èèyàn?

BÁWỌN Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, wọ́n máa ń bá àwọn aláṣẹ ìjọba tó wà nípò gíga àtàwọn tó kéré nípò pàdé. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò fìgbà kankan forúkọ oyè pe ara wọn. Àmọ́, nígbà yẹn àwọn èèyàn sábà máa ń forúkọ oyè pe àwọn tó bá lágbára tàbí ọlá àṣẹ lórí àwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ “Ẹni Ọlọ́lá” làwọn èèyàn máa ń pe Olú Ọba ilẹ̀ Róòmù.—Ìṣe 25:21.

Torí náà ojú wo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fi wo fíforúkọ oyè pe àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá wà níwájú àwọn aláṣẹ ìjọba? Ojú wo ló sì yẹ káwa náà máa fi wò ó?

Bíbọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ Ò Túmọ̀ sí Pé A Gba Tiwọn

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, . . . ẹni tí ó béèrè fún ọlá, ẹ fún un ní irúfẹ́ ọlá bẹ́ẹ̀.” (Róòmù 13:7) Ìmọ̀ràn yìí sì kan fífi orúkọ oyè tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba pè wọ́n. Lóde òní, àwọn èèyàn sábà máa ń lo àwọn orúkọ oyè bí Ọlọ́lá tàbí Ẹni Ọ̀wọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó wà nípò ńlá. Àmọ́, àwọn kan lè máa béèrè pé, ‘Kí nìdí tí màá fi máa fi irú àwọn orúkọ oyè yìí pè wọ́n nígbà tí mo mọ̀ pé wọn ò yẹ lẹ́ni téèyàn ń bọlá fún, wọn ò sì ń ṣẹni ọ̀wọ̀?’

Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn aláṣẹ ló ń ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, àmọ́ gbogbo wọn náà kọ́ ló ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Síbẹ̀ náà, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká fara wa sábẹ́ àwọn ọba àtàwọn gómìnà “nítorí Olúwa.” (1 Pétérù 2:13, 14) Torí náà, tá a bá gbà pé Ọlọ́run ló gba àwọn aláṣẹ láyè láti wà nípò tí wọ́n wà, ìyẹn á jẹ́ ká lè bọ̀wọ̀ fún wọn ká sì fún wọn ní ọlá tó bá yẹ wọ́n.—Róòmù 13:1.

Ìwà tí aláṣẹ kan ń hù ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ọlá tí ẹsẹ Bíbélì yìí ní ká fún un, torí ìyẹn kọ́ là ṣe ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Pé à ń forúkọ oyè pe aláṣẹ ò sọ pé a gba ti ìwà tó ń hù. Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi èyí hàn kedere.

Bí Pọ́ọ̀lù Ṣe Lo Orúkọ Oyè

Àwọn èèyàn fẹ̀sùn èké kan Pọ́ọ̀lù ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n fàṣẹ ọba mú un lọ síwájú Fẹ́líìsì, gómìnà Jùdíà. Oníwàkiwà ni Fẹ́líìsì láàárín àwọn aláṣẹ àdúgbò. Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Róòmù kan tó ń jẹ́ Tacitus tiẹ̀ kọ̀wé pé Fẹ́líìsì “rò pé òun lè hùwà ìkà kóun sì mú un jẹ.” Ó fẹ́ràn láti máa gba ẹ̀gúnjẹ ju kó dájọ́ bó ṣe yẹ lọ. Síbẹ̀, nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà látìmọ́lé fún ọdún méjì, ó máa ń bọ̀wọ̀ fún Fẹ́líìsì, àwọn méjèèjì sì máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa. Fẹ́líìsì ń retí pé kí Pọ́ọ̀lù fún òun ní ẹ̀gúnjẹ, àmọ́ ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń lo gbogbo àǹfààní tó bá ní láti wàásù fún un.—Ìṣe 24:26.

Nígbà tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì gbapò Fẹ́líìsì gẹ́gẹ́ bíi gómìnà tuntun, ó gbà láti gbẹ́jọ́ Pọ́ọ̀lù ní Kesaréà. Fẹ́sítọ́ọ̀sì dábàá pé kí Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù kó lè rí ojúure àwọn lọ́gàálọ́gàá tó jẹ́ Júù. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé wọn ò lè gbọ́ ẹjọ́ òun dáadáa ní Jerúsálẹ́mù ló bá lo àǹfààní tó ní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilẹ̀ Róòmù, ó ní: “Mo ké gbàjarè sí Késárì!”—Ìṣe 25:11.

Fẹ́sítọ́ọ̀sì ò mọ bó ṣe máa ṣàlàyé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù tó bá déwájú Késárì, àmọ́ ìrànlọ́wọ́ dé nígbà tí Ọba Ágírípà Kejì wá ṣèbẹ̀wò àyẹ́sí sọ́dọ̀ Fẹ́sítọ́ọ̀sì tó sì ní òun á fẹ́ láti gbọ́ ẹjọ́ náà. Nígbà tó máa di ọjọ́ kejì, pẹ̀lú afẹfẹyẹ̀yẹ̀, ọmọ ogún tó lọ súà àtàwọn lọ́balọ́ba, ọba wọnú kóòtù ó sì jókòó sáàárín àwùjọ tó fẹ́ gbẹ́jọ́ ọ̀hún.—Ìṣe 25:13-23.

Nígbà tí wọ́n pe Pọ́ọ̀lù pé kó wá sọ tẹnu ẹ̀, ó lo orúkọ oyè náà “Ọba” nígbà tó máa bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó sì pọ́n Ágírípà lé pé ó ní òye tó yanranntí nípa àṣà ìbílẹ̀ àti pé ó mọ bó ṣe lè paná rògbòdìyàn tó bá wáyé láàárín àwọn Júù. (Ìṣe 26:2, 3) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìròyìn ti tàn kálẹ̀ pé Ágírípà ti hùwà má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́, ní ti pé ó bá àbúrò ẹ̀ sùn. Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé oníwàkiwà ni Ágírípà àti pé kò ní orúkọ rere. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù fún un ní ọ̀wọ̀ tó yẹ ọba.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń gbèjà ara ẹ̀, Fẹ́sítọ́ọ̀sì pariwo mọ́ ọn, ó ní: “Orí rẹ ti ń dà rú, Pọ́ọ̀lù!” Kàkà kí Pọ́ọ̀lù fara ya, ńṣe ló fi pẹ̀lẹ́tù dá gómìnà lóhùn, ó tiẹ̀ pè é ní “Ẹni Títayọ Lọ́lá.” (Ìṣe 26:24, 25) Pọ́ọ̀lù fún un ní ọ̀wọ̀ tó yẹ ipò tó wà. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo àwọn àpẹẹrẹ tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, a lè wá béèrè pé, Ṣó wá túmọ̀ sí pé kò síbi tí bíbọlá fáwọn èèyàn mọ ni?

Ọlá Tó Mọ Níwọ̀n

Bó ṣe wà nínú Róòmù 13:1, ó níbi tí ọlá àṣẹ àwọn aláṣẹ ìjọba mọ, ẹsẹ yẹn sọ pé: “Àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Torí náà ọlá tó mọ níwọ̀n ló tọ́ sáwọn aláṣẹ ìjọba torí ipò tó láàlà ni wọ́n wà. Jésù pààlà sí ọlá àṣẹ tó yẹ ká máa fáwọn ẹlòmíì nígbà tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni kí a má pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.”—Mátíù 23:8-10.

Èyí wá fi hàn pé tó bá dọ̀rọ̀ fífún àwọn èèyàn ní ọlá tó mọ níwọ̀n, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìyàtọ̀ wà láàárín orúkọ oyè ẹ̀sìn àti orúkọ oyè tí wọ́n ń lò fáwọn aláṣẹ ìjọba. Nígbà táwọn aláṣẹ ìjọba bá fún ara wọn ní orúkọ oyè ẹ̀sìn, ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé ká bọlá fún wọn ò ní ṣiṣẹ́ fún irú àwọn orúkọ oyè bẹ́ẹ̀. Ẹni tó bá ń fàwọn ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ ṣèwà hù á máa fún irú àwọn aláṣẹ bẹ́ẹ̀ ní ọlá tó yẹ wọ́n. Àmọ́, ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ ò ní gbà á láyè láti forúkọ oyè ẹ̀sìn pe àwọn èèyàn torí ó gbọ́dọ̀ “san . . . àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Mátíù 22:21.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Ojú wo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fi ń wo àwọn aláṣẹ?—Róòmù 13:7.

◼ Ṣé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù forúkọ oyè pe àwọn aláṣẹ ìjọba?—Ìṣe 25:11; 26:2, 25.

◼ Irú àwọn orúkọ oyè wo ni Jésù ò fọwọ́ sí?—Mátíù 23:8-10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]

Orúkọ oyè wo ni Pọ́ọ̀lù fi pe Ágírípà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́