Pọ́ọ̀lù Fìgboyà Wàásù Níwájú Àwọn Lóókọ-Lóókọ
KÒ SÍ bí ìyàtọ̀ àárín àwọn ọkùnrin méjì náà ṣe lè hàn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀kan dé adé nígbà tí èkejì wà nínú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀. Ọ̀kan jẹ́ ọba; èkejì jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti lo ọdún méjì lẹ́wọ̀n, ó wá dúró níwájú alákòóso àwọn Júù, Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kejì. Ọba náà àti olorì rẹ̀, Bẹ̀níìsì, ti dé “pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àṣehàn aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀, wọ́n sì wọnú gbọ̀ngàn àwùjọ lọ, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọkùnrin jàǹkàn-jàǹkàn ní ìlú ńlá náà.” (Ìṣe 25:23) Ìwé ìtọ́kasí kan sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí àwọn tó wà níbẹ̀ ti tó ọgọ́rùn-ún mélòó kan.”
Fẹ́sítọ́ọ̀sì, gómìnà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò, ló ṣètò ìpàdé ọ̀hún. Ó tẹ́ gómìnà tó ṣáájú rẹ̀, Fẹ́líìsì, lọ́rùn láti jẹ́ kí a gbàgbé Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n. Àmọ́ Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣiyèméjì nípa bí àwọn ẹ̀sùn tí a fi kan Pọ́ọ̀lù ṣe lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó. Pọ́ọ̀lù ti tẹnu mọ́ ọn pé òun kò lẹ́bi rárá tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi sọ pé kí a gbé ẹjọ́ òun lọ síwájú Késárì! Ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù ru ìfẹ́ ìtọpinpin Àgírípà Ọba sókè. Ó wí pé: “Èmi alára yóò fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkùnrin náà.” Fẹ́sítọ́ọ̀sì yára ṣètò kíákíá, ó ṣeé ṣe kí ó máa ronú lórí ohun tí èrò ọba yóò jẹ́ nípa àràmàǹdà ẹlẹ́wọ̀n yìí.—Ìṣe 24:27–25:22.
Lọ́jọ́ kejì, Pọ́ọ̀lù bá ara rẹ̀ níwájú ògìdìgbó àwọn onípò-ọlá. Ó sọ fún Àgírípà pé: “Mo ka ara mi sí aláyọ̀ pé iwájú rẹ ni èmi yóò ti gbèjà ara mi lónìí yìí, ní pàtàkì, níwọ̀n bí ìwọ ti jẹ́ ògbógi nínú gbogbo àṣà àti àríyànjiyàn láàárín àwọn Júù. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́ láti fi sùúrù gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.”—Ìṣe 26:2, 3.
Àwíjàre Onígboyà Tí Pọ́ọ̀lù Wí
Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù sọ ìtàn ara rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni, fún Àgírípà. Ó wí pé: “Mo gbìyànjú láti fi ipá mú wọn láti kó ọ̀rọ̀ wọn jẹ. . . . Mo lọ jìnnà dé ṣíṣe inúnibíni sí wọn, kódà ní àwọn ìlú ńlá tí ń bẹ lẹ́yìn òde.” Pọ́ọ̀lù tẹ̀ síwájú ní sísọ bí ó ṣe rí ìran àgbàyanu kan, nínú èyí tí Jésù tí a ti jí dìde náà bi í pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Láti máa bá a nìṣó ní títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́ mú kí ó nira fún ọ.”a—Ìṣe 26:4-14.
Jésù wá gbéṣẹ́ fún Sọ́ọ̀lù láti wàásù “àwọn ohun tí ìwọ ti rí àti àwọn ohun tí èmi yóò mú kí o rí nípa mi” fún àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé òun tiraka taápọntaápọn láti ṣe iṣẹ́ àyànfúnni òun ní kíkún. Síbẹ̀, ó sọ fún Àgírípà pé, “tìtorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù fi gbá mi mú nínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì gbìdánwò láti pa mí.” Pọ́ọ̀lù fọ̀ràn lọ ìfẹ́ tí Àgírípà ní sí ìsìn àwọn Júù, nípa títẹnu mọ́ ọn pé ìwàásù òun ní gidi “kò sọ nǹkan kan àyàfi àwọn ohun tí àwọn Wòlíì àti Mósè sọ pé yóò ṣẹlẹ̀” nípa ikú Mèsáyà náà àti àjíǹde rẹ̀.—Ìṣe 26:15-23.
Fẹ́sítọ́ọ̀sì já lù ú. Ó wí ní ohùn rara pé: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ti ń dà ọ́ lórí rú!” Pọ́ọ̀lù dáhùn pé: “Kì í ṣe pé orí mi ti ń dà rú, Fẹ́sítọ́ọ̀sì Ẹni Títayọ Lọ́lá, ṣùgbọ́n àwọn àsọjáde tí ó jẹ́ òtítọ́ àti ti ìyèkooro èrò inú ni mo ń sọ jáde.” Pọ́ọ̀lù wá sọ nípa Àgírípà pé: “Ọba tí mo ń bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ mọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí dáadáa; nítorí mo gbà pé kò sí ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí tí ó bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí rẹ̀, nítorí a kò ṣe ohun yìí ní kọ́lọ́fín.”—Ìṣe 26:24-26.
Pọ́ọ̀lù wá dojú ọ̀rọ̀ kọ Àgírípà ní tààrà. “Àgírípà Ọba, ìwọ ha gba àwọn Wòlíì gbọ́ bí?” Láìsí iyèméjì, ìbéèrè náà ni Àgírípà lára. Ó ṣe tán, ó ní ipò kan tó gbọ́dọ̀ dáàbò bò, fífara mọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ yóò sì túmọ̀ sí fífara mọ́ ohun tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì pè ní ‘ìdàlórírú.’ Bóyá nítorí pé Pọ́ọ̀lù tètè rí òye pé Àgírípà ń lọ́ra, ó dáhùn ìbéèrè rẹ̀ fúnra rẹ̀. Ó wí pé: “Mo mọ̀ pé o gbà gbọ́.” Ágírípà wá sọ̀rọ̀ wàyí, ṣùgbọ́n kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀ síbì kan. Ó sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.”—Ìṣe 26:27, 28.
Lọ́nà tó jáfáfá, Pọ́ọ̀lù lo gbólóhùn ìyọra-ẹni tí Àgírípà sọ láti fi gbé kókó pàtàkì kan jáde. Ó wí pé: “Ẹ̀bẹ̀ mi sọ́dọ̀ Ọlọ́run ni pé yálà ní àkókò kúkúrú tàbí ní àkókò gígùn, kì í ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú yóò di irú ènìyàn tí èmi náà jẹ́, láìsí ìdè wọ̀nyí.”—Ìṣe 26:29.
Àgírípà àti Fẹ́sítọ́ọ̀sì kò rí ohun kan tó tọ́ sí ikú tàbí ìfisẹ́wọ̀n lára Pọ́ọ̀lù. Síbẹ̀, wọn kò lè yí gbàjarè tó ké láti gbé ẹjọ́ rẹ̀ dé iwájú Késárì padà. Nítorí náà ni Àgírípà fi wí fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: “À bá ti tú ọkùnrin yìí sílẹ̀ ká ní kò ké gbàjarè sí Késárì.”—Ìṣe 26:30-32.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa
Ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà wàásù níwájú àwọn onípò-ọlá jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ fún wa. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá Àgírípà Ọba sọ̀rọ̀, ó lo ọgbọ́n inú. Kò ṣàìmọ̀ nípa ìwàkiwà tí ń lọ láàárín Àgírípà àti Bẹ̀níìsì. Ìgbéyàwó wọn jẹ́ ti ìbátan sísúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí, nítorí pé òbí kan náà ló bí Àgírípà àti Bẹ̀níìsì. Àmọ́ ní àkókò yìí, Pọ́ọ̀lù kò wá sọ̀rọ̀ lórí ìwà rere. Dípò bẹ́ẹ̀, ó tẹnu mọ́ àwọn kókó tí òun àti Àgírípà jọ gbà. Síwájú sí i, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé Farisí onímọ̀, Gàmálíẹ́lì, ló kọ́ Pọ́ọ̀lù lẹ́kọ̀ọ́, ó sọ pé Àgírípà jẹ́ ògbógi nínú gbogbo àṣà àwọn Júù. (Ìṣe 22:3) Láìka àwọn ọ̀nà ìhùwà Àgírípà sí, Pọ́ọ̀lù bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nítorí pé, Àgírípà wà ní ipò àṣẹ kan.—Róòmù 13:7.
Nígbà tí a bá ń fìgboyà wàásù nípa àwọn ìgbàgbọ́ wa, kì í ṣe ète wa láti máa tú àṣírí ìwà àìmọ́ tí àwọn tí a ń bá sọ̀rọ̀ ń hù tàbí láti máa dá wọn lẹ́bi. Dípò bẹ́ẹ̀, kí ó lè rọrùn fún wọn láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ó yẹ kí a máa tẹnu mọ́ àwọn apá gbígbámúṣé inú ìhìnrere náà, kí a máa tẹnu mọ́ àwọn ìrètí tí a jọ ní. Nígbà tí a bá ń bá àwọn tó dàgbà jù wá lọ tàbí àwọn tó wà nípò àṣẹ sọ̀rọ̀, a gbọ́dọ̀ mọ ipò wọn fún wọn. (Léfítíkù 19:32) Lọ́nà yìí, a lè fara wé Pọ́ọ̀lù, tó wí pé: “Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí n lè rí i dájú pé mo gba àwọn kan là.”—1 Kọ́ríńtì 9:22.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ náà, “títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́” ń ṣàpèjúwe akọ màlúù kan tó ṣe ara rẹ̀ léṣe níbi tó ti ń tàpá sí ọ̀pá ẹlẹ́nu ṣóṣóró tí a ṣe láti máa fi darí ẹranko, kí a sì máa fi tọ́ ọ. Lọ́nà kan náà, nípa ṣíṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni, Sọ́ọ̀lù yóò wulẹ̀ ṣe ara rẹ̀ léṣe, nítorí pé àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run ń tì lẹ́yìn ló ń bá jà.