Ìdílé Kan Ni Gbogbo Wa
OJÚ wo lo fi ń wo àwọn èèyàn tí àwọ̀ ara wọn yàtọ̀ sí tìrẹ tàbí tí wọ́n wá látinú ẹ̀yà míì? Ṣé o máa ń wò ó pé èèyàn bíi tiẹ̀ ni wọ́n? Ó dunni pé ọ̀pọ̀ máa ń rò pé àwọn sàn ju àwọn ẹ̀yà kan lọ. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ni kéèyàn lérò pé, ẹ̀yà tí ẹnì kan ti wá ló máa pinnu irú ìwà táá máa hù, ohun táá lè ṣe àti pé àwọn èèyàn tó wá látinú ẹ̀yà kan sàn ju àwọn èèyàn tó wá látinú ẹ̀yà míì lọ.”
Èrò yìí ti dá ọ̀pọ̀ wàhálà sílẹ̀. Bí àwọn kan ṣe gbà pé ẹ̀yà tiwọn sàn ju ti àwọn míì lọ “ti mú kí wọ́n máa fipá darí orílẹ̀-èdè míì, tí wọ́n á sì máa mú àwọn míì lẹ́rú,” gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Wen-Shing Tseng tó kọ ìwé ìléwọ́ kan tó ń jẹ́ Handbook of Cultural Psychiatry, ṣe sọ. Ó fi kún un pé wọ́n ti lo ẹ̀yà láti dá “ara wọn láre fún àìdọ́gba tó wà láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, nínú ètò ọrọ̀ ajé àti lórí ọ̀ràn ìṣèlú.” Kódà lóde òní, ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ṣì wà lọ́kàn àwọn èèyàn jákèjádò ayé. Àmọ́, ṣé orí òtítọ́ ni èrò òdì táwọn èèyàn ní yìí dá lé? Kí ni sáyẹ́ǹsì àti Bíbélì sọ nípa rẹ̀?
Kí Ni Sáyẹ́ǹsì Sọ?
Àwárí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe nípa apilẹ̀ àbùdá ẹ̀dá èèyàn ti jẹ́ ká rí i pé irọ́ gbuu ló wà nìdí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Àwọn tó ń ṣèwádìí nípa àwọn èèyàn tó ń gbé ní ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé ti rí i pé bí wọ́n bá mú èèyàn méjì ní ilẹ̀ tó yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì ṣàyẹ̀wò DNA wọn, ìyẹn èròjà tó ń pinnu àwọ̀, ìrísí àti ìṣesí ẹ̀dá, ìyàtọ̀ tó máa ń wà láàárín àwọn méjèèjì kì í tó nǹkan.a Bẹ́ẹ̀ sì rèé, lára ọgọ́rùn-ún èèyàn tó wá látinú ẹ̀yà kan ṣoṣo èyíkéyìí, àwọn tí DNA wọn yàtọ̀ síra tó mẹ́rìn-dín-láàádọ́rùn-ún [86] sí àádọ́rùn-ún [90]. Èyí tó fi hàn pé nínú èèyàn ọgọ́rùn-ún tó wá láti àwọn ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ẹni mẹ́rìnlá péré tàbí àwọn tí kò tiẹ̀ tóyẹn ni DNA wọn yàtọ̀ síra.
Ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Nature, sọ pé: “Torí pé apilẹ̀ àbùdá kan náà làwọn èèyàn ní, apilẹ̀ àbùdá yìí ló yẹ kó jẹ́ ohun pàtàkì tá a ó máa lò láti fi tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀ràn kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ká sì tún máa fi paná awuyewuye tó máa ń mú wá.”
Èrò yìí kì í ṣe tuntun. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1950, Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀, gbé àwọn èrò kan jáde láti fi paná ọ̀ràn kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Èrò tí wọ́n gbé jáde náà wá látọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá èèyàn, àwọn onímọ̀ nípa apilẹ̀ àbùdá àtàwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá. Síbẹ̀ náà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kò tíì kásẹ̀ nílẹ̀. Ó ṣe kedere pé mímọ̀ pé àwa èèyàn ò yàtọ̀ síra nìkan kò tó. A tún gbọ́dọ̀ fa èrò kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu kúrò nínú ọkàn. Jésù Kristi sọ pé: “Láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú ti ń wá.”—Mátíù 15:19, 20.
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì máa ń wọni lọkàn gan-an. Bí àpẹẹrẹ, yàtọ̀ sí pé Bíbélì sọ ohun tó bá sáyẹ́ǹsì mu pé ‘láti ara ọkùnrin kan ni Ọlọ́run ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá,’ Bíbélì tún sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35; 17:26) Ǹjẹ́ èyí ò mú kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?—Diutarónómì 32:4.
Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ká fi hàn pé a fẹ́ràn òun nípa fífara wé òun. Éfésù 5:1, 2 sọ pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.” “Rírìn nínú ìfẹ́” gba pé ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn, láìka àwọ̀ tàbí ẹ̀yà wọn sí.—Máàkù 12:31.
Ọlọ́run kò ní gba àwọn tí ìwà burúkú, ìkórìíra àti ẹ̀tanú sí ẹ̀yà míì kún ọwọ́ wọn, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ̀. (1 Jòhánù 3:15) Kódà, àkókò tí Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn èèyàn búburú run kúrò lórí ilẹ̀ ayé ń yára sún mọ́lé. Kìkì àwọn tó bá ní àwọn ànímọ́ bíi ti Ọlọ́run ló máa ṣẹ́ kù. Nígbà yẹn gbogbo ìran èèyàn á wá jẹ́ ìdílé kan, nípa tara àti nípa tẹ̀mí.—Sáàmù 37:29, 34, 38.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àmọ́ ṣáá o, àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀ tó máa ń wáyé nínú DNA àwọn èèyàn lè pọ̀ gan-an tó bá dọ̀ràn àìlera ara, torí pé àwọn àìsàn kan wà tí wọ́n ní í ṣe pẹ̀lú apilẹ̀ àbùdá.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
“Apilẹ̀ àbùdá kan náà làwọn èèyàn ní”