ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/11 ojú ìwé 14-15
  • Ṣé Ó Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí “Àwọn Ẹni Mímọ́”?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ó Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí “Àwọn Ẹni Mímọ́”?
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ó Yẹ Ká Máa Ké Pe “Àwọn Ẹni Mímọ́”?
  • Àdúrà Jẹ́ Ìjọsìn
  • Alárinà Tó Ń Bani Kẹ́dùn
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí Àwọn Ẹni Mímọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Báwo Làwọn Ẹni Mímọ́ Tòótọ́ Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ṣó Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà sí Àwọn Ẹni Mímọ́
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Nìdí Tí Mo Fi Gbọ́dọ̀ Gbàdúrà Lórúkọ Jésù?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 1/11 ojú ìwé 14-15

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ó Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí “Àwọn Ẹni Mímọ́”?

Marie àti Theresa gbà pé tọkàntọkàn làwọn fi ń ṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì. Àwọn méjèèjì ló ní ìgbàgbọ́ nínú “àwọn ẹni mímọ́.” Marie gbà gbọ́ pé “àwọn ẹni mímọ́” lè ran òun lọ́wọ́ bí òun bá gbàdúrà sí wọn. Ní ti Theresa, ìgbà gbogbo ló máa ń gbàdúrà sí “ẹni mímọ́” tí wọ́n gbà pé ó ń tì wọ́n lẹ́yìn ní abúlé wọn. Ó tún máa ń gbàdúrà sí “ẹni mímọ́” kan tí wọ́n jọ ń jẹ́ orúkọ kan náà.

BÍI ti Marie àti Theresa, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ló ní àwọn ẹni mímọ́ tí wọ́n máa ń gbàdúrà sí láti tọrọ ìbùkún. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia, sọ pé: “Àwọn ẹni mímọ́ máa ń bá àwa èèyàn bẹ Ọlọ́run, àǹfààní sì wà nínú gbígbàdúrà sí wọn ká bàa lè . . . rí ìbùkún Ọlọ́run gbà.”

Àmọ́, ojú wo ni Ọlọ́run fi wo ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbàdúrà sí “àwọn ẹni mímọ́” kí wọ́n lè bá wa bẹ òun? Jẹ́ ká gbé ohun tí Bíbélì sọ yẹ̀ wò.

Ṣé Ó Yẹ Ká Máa Ké Pe “Àwọn Ẹni Mímọ́”?

Kò sí olóòótọ́ olùjọsìn Ọlọ́run kankan nínú Bíbélì tó gbàdúrà sí “ẹni mímọ́.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìwé New Catholic Encyclopedia sọ pé, “ọ̀rúndún kẹta ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbà gbọ́ [pé] àwọn lè gbàdúrà nípasẹ̀ àwọn ẹni mímọ́.” Èyí jẹ́ igba [200] ọdún lẹ́yìn ikú Kristi. Torí náà, ẹ̀kọ́ yìí kò pilẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Jésù àtàwọn tí Ọlọ́run mí sí láti ṣàkọsílẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù sínú Bíbélì. Kí nìdí?

Bíbélì sọ léraléra pé Ọlọ́run nìkan ni ká máa gbàdúrà sí, ká sì máa gbàdúrà lórúkọ Jésù Kristi. Jésù sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere yẹn bá ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni ní Mátíù 6:9-13 mu. Nígbà tó ń ṣàlàyé bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. . . . ” (Mátíù 6:9) Ó ṣe kedere nígbà náà pé, Baba wa ọ̀run nìkan ló yẹ ká máa gbàdúrà sí. Òótọ́ yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà pàtàkì kan nínú Bíbélì.

Àdúrà Jẹ́ Ìjọsìn

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia, sọ pé, “Àdúrà ni ọ̀rọ̀ àti èrò tá a fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún Ọlọ́run, àwọn ọlọ́run tàbí àwọn òrìṣà tàbí àwọn nǹkan míì táwọn èèyàn ń sìn. . . . Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìsìn tó wà láyé ló fojú pàtàkì wo àdúrà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà jọ́sìn.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ó bójú mu láti máa kúnlẹ̀ àdúrà sí ẹnikẹ́ni mìíràn yàtọ̀ sí Ẹlẹ́dàá àti Olùfúnni-ní-ìyè wa?’ (Sáàmù 36:9) Jésù sọ pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ ká fún òun ní “ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.”—Diutarónómì 4:24; 6:15.

Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Jòhánù yẹ̀ wò. Lẹ́yìn tí ó gba ìran ológo tó wà lákọọ́lẹ̀, ìyẹn ìwé Ìṣípayá nínú Bíbélì, ìbẹ̀rù tó bá àpọ́sítélì yìí mú kó “wólẹ̀ láti jọ́sìn níwájú ẹsẹ̀ áńgẹ́lì” tó fi ìran náà hàn án. Kí ni áńgẹ́lì náà ṣe? Ó sọ fún un pé, “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ àti ti àwọn arákùnrin rẹ . . . Jọ́sìn Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 22:8, 9) Bíbélì tún fi hàn lẹ́ẹ̀kan sí i pé Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn.

Abájọ nígbà náà tó fi jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ni Bíbélì pè ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Síwájú sí i, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ni Olódùmarè, òun nìkan ló ní ọlá àṣẹ, ìmọ̀ àti agbára láti fún wa ní ohunkóhun tá a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípasẹ̀ àdúrà tó bá wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. (Jóòbù 33:4) Jésù Kristi pàápàá, gbà pé ó ní ibi tí agbára òun mọ. (Mátíù 20:23; 24:36) Síbẹ̀, Ọlọ́run ti fún Jésù Kristi ní ọlá àṣẹ tó pọ̀, lára ojúṣe Jésù sì ni pé òun ni Alárinà fún gbogbo èèyàn.

Alárinà Tó Ń Bani Kẹ́dùn

Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Ó lè gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.” (Hébérù 7:25) Èyí fi hàn pé, Jésù lè jẹ́ Alárinà tó ń báni kẹ́dùn fún àwọn tó bá “ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀.” Èyí kò túmọ̀ sí pé ká máa gbàdúrà sí Jésù, kó lè máa sọ ohun tá à ń béèrè fún Ọlọ́run. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run lórúkọ Jésù, nípa bẹ́ẹ̀ à ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ rẹ̀. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù nìkan ló kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ Alárinà wa?

Ohun kan ni pé, Jésù ti gbé ayé rí gẹ́gẹ́ bí èèyàn, èyí sì jẹ́ kó lè mọ̀ dáadáa bí ìyà ṣe ń rí lára. (Jòhánù 11:32-35) Bákan náà, Jésù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn ní ti pé ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó jí òkú dìde, ó sì ran gbogbo àwọn tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run. (Mátíù 15:29, 30; Lúùkù 9:11-17) Ó tiẹ̀ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n. (Lúùkù 5:24) Èyí jẹ́ kó dá wa lójú pé, tá a bá dẹ́ṣẹ̀, “àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo.”—1 Jòhánù 2:1.

Ó yẹ ká máa gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ àti ìgbatẹnirò Jésù. Òótọ́ ni pé, a ò láṣẹ láti jẹ́ alárinà bíi ti Jésù. Àmọ́, a lè gbàdúrà fún àwọn ẹlòmíì. Ìfẹ́ tá a bá ní sí wọn ló máa mú ká ṣe bẹ́ẹ̀. Jákọ́bù kọ̀wé pé: ‘Kí ẹ máa gbàdúrà fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo, nígbà tí ó bá wà lẹ́nu iṣẹ́, ní ipá púpọ̀.’—Jákọ́bù 5:16.

Theresa àti Marie wá mọ àwọn òtítọ́ ṣíṣeyebíye yìí nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò Bíbélì fúnra wọn. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rọ ìwọ náà pé kó o ṣàyẹ̀wò Bíbélì. Bí Jésù ti sọ, “àwọn tí ń jọ́sìn [Ọlọ́run] gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—Jòhánù 4:24.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ta ni ẹnì kan ṣoṣo tí Jésù sọ pé ó yẹ ká máa gbàdúrà sí?—Mátíù 6:9.

● Kí ni ojúṣe Jésù?—Hébérù 7:25.

● Ṣé ó yẹ ká máa gbàdúrà fún àwọn ẹlòmíì?—Jákọ́bù 5:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́