Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Ṣé Mo Ti Sọ Àwọn Ohun Tó Ń Gbé Ìsọfúnni Jáde Di Bárakú?
Kí ló jọra nínú ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta yìí?
“Mo fẹ́ràn kí n máa fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù gan–an! Mo ronú pé òun ló ń mú mi lórí yá jù lọ. Ká kúkú sọ pé ó ti gbà mí lọ́kàn pátápátá.”—Alan.a
“Mọ́mì mi ra tẹlifíṣọ̀n sínú yàrá mi, inú mi sì dùn gan-an! Dípò tí màá fi lọ sùn lálẹ́, òun ni mo máa ń jókòó tì fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Ó tẹ́ mi lọ́rùn kí n máa wo tẹlifíṣọ̀n ju kí n lo àkókò pẹ̀lú àwọn ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ mi.”—Teresa.
“Láwọn àkókò kan, mi ò kì í lè lọ síbikíbi tàbí kí n ṣe ohunkóhun láì máa ronú pé bóyá ẹnì kan ti fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí ìkànnì mi lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Tí mo bá jí láàárín òru, àfi kí n lọ sórí ìkànnì mi. Tí mo bá fi lè ní àkókò díẹ̀ báyìí, máa ṣá rí i pé mo fi ìsọfúnni tuntun sórí ìkànnì mi.”—Anna.
Èwo nínú àwọn ọ̀dọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni wàá sọ pé ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde ti di bárakú fún lọ́nà kan ṣá?
□ Alan □ Teresa □ Anna
NÍGBÀ tí àwọn òbí rẹ wà ní ọ̀dọ́, tẹlifíṣọ̀n àti rédíò ni ohun pàtàkì tó ń gbé ìsọfúnni jáde tí wọ́n mọ̀. Nígbà yẹn, kò sí ohun méjì tí wọ́n ń fi fóònù ṣe ju kí wọ́n fi pe èèyàn lọ, ara ògiri ni wọ́n sì máa ń dè é mọ́. Ó jọ pé ìgbà ojú dúdú nìyẹn, àbí? Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Anna náà gbà pé ìgbà ojú dúdú nìyẹn. Ó sọ pé: “Kò sí àwọn nǹkan tó ń gbé ìsọfúnni jáde lóríṣiríṣi nígbà táwọn òbí mi wà lọ́dọ̀ọ́. Ńṣe ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bí wọ́n ṣe máa lo fóònù alágbèéká báyìí.”
Lóde òní, o lè gba ìpè, gbọ́ orin, wo fíìmù, gbá géèmù, fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ rẹ, ya fọ́tò, wo Íńtánẹ́ẹ̀tì, gbogbo èyí lo sì lè ṣe lórí ohun èlò kan tó o lè jù sí àpò aṣọ rẹ. Torí pé láti kékeré lo ti ń lo kọ̀ǹpútà, fóònù alágbèéká, tẹlifíṣọ̀n àti Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè máà rí ohun tó burú nínú pé kó o máa lò ó ní gbogbo ìgbà. Àwọn òbí rẹ sì lè máa wò ó pé ó ti di bárakú fún ẹ. Tí wọ́n bá sọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn fún ẹ, má ṣe ronú pé àsìkò ti wọn ti kọjá lọ. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—Òwe 18:13.
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí àwọn òbí rẹ fi lè kọminú sí ọ̀nà tí ò ń gbà lo ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde? Ṣe ìdánrawò tó wà níbí yìí kó o lè mọ̀ bóyá lílo àwọn ohun kan tó ń gbé ìsọfúnni jáde ti di bárakú fún ẹ.
‘Ṣé Ó Ti Di Bárakú fún Mi?’
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan túmọ̀ bárakú sí “àṣà kan tí èèyàn ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, tí èèyàn kò sì fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀ láìka ti ìpalára tó lè tìdí ẹ̀ yọ sí.” Tá a bá fi ojú ìtúmọ̀ yìí wò ó, àwọn ọ̀dọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a sọ̀rọ̀ wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ni àwọn ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde ti di bárakú fún lọ́nà kan. Ìwọ ńkọ́? Wo ìfọ́síwẹ́wẹ́ ìtumọ̀ yẹn níbí yìí. Ka ohun tí àwọn ọ̀dọ́ yìí sọ, kó o sì wò ó bóyá ìwọ náà ti sọ ohun kan tàbí ṣe ohun kan tó jọ ọ́. Kó o wá kọ ìdáhùn rẹ.
Àṣà kan tó ti di bárakú. “Mo máa ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà. Kì í jẹ́ kí n ráyè sùn, ọ̀rọ̀ géèmù náà ló sì máa ń pọ̀ jù nínú nǹkan tí mò ń bá àwọn èèyàn sọ. Mi ò kì í sún mọ́ àwọn ìdílé mi mọ́, géèmù náà ni mo sì máa ń ronú nípa rẹ̀ ṣáá ní gbogbo ìgbà.”—Andrew.
Lójú tìẹ, báwo ló ṣe yẹ kéèyàn pẹ́ tó nídìí lílo àwọn ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde? ․․․․․
Báwo ni àwọn òbí rẹ ṣe fẹ́ kó o pẹ́ tó nídìí ẹ̀? ․․․․․
Wákàtí mélòó lò ń lò lójúmọ́ láti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, láti wo tẹlifíṣọ̀n, láti wa àwòrán jáde lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí kó o kọ ọ̀rọ̀ síbẹ̀, láti fi gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ? ․․․․․
Lẹ́yìn tó o wo àwọn ìdáhùn tó o kọ sókè yìí, ǹjẹ́ o lè sọ pé àkókò tí ò ń lò nídìí àwọn ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde ti pọ̀ jù?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ
Àṣà kan téèyàn kò lè jáwọ́ nínú rẹ̀ tàbí tí èèyàn kò fẹ́ jáwọ́. “Àwọn òbí mi kíyè sí i pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, wọ́n sì sọ fún mi pé ó ti pọ̀ jù. Bí mo bá sì wo ti àwọn ọmọ míì tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́, èmi kò tíì ṣe nǹkan kan rárá. Àmọ́, tá a bá fi wé tí àwọn òbí mi, mo máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù jù wọ́n lọ. Àmọ́ ńṣe nìyẹn dà bí ìgbà téèyàn ń fi èso ápù wé ọsàn, ọmọ ogójì [40] ọdún làwọn òbí mi, èmi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15].”—Alan.
Ṣé àwọn òbí rẹ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sọ fún ẹ pé o máa ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ̀
Ǹjẹ́ kò wù ẹ́ láti jáwọ́ tàbí kó ṣòro fún ẹ láti jáwọ́ nínú lílo ohun èlò yìí?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ́
Ìpalára tó lè tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. “Àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù ní gbogbo ìgbà, kódà nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀. Ẹ ò rí i pé ewu wà nínú ìyẹn!”—Julie.
“Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ra fóònù, gbogbo ìgbà ni mo máa ń rẹ́ni pè tàbí fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí. Ohun tí mo máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà nìyẹn. Ó ba àjọṣe mi pẹ̀lú ìdílé mi jẹ́, ó sì tún ba àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi jẹ́. Ní báyìí mo wá kíyè sí i pé, nígbà tí mo bá jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi tàbí tá a jọ ń sọ̀rọ̀, wọ́n sábà máa ń dá ọ̀rọ̀ wa dúró, tí wọ́n á sọ pé: ‘Jọ̀ọ́ dúró ná. Mo fẹ́ fèsì ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sórí fóònù mi.’ Ohun tó fà á tí èmi àti àwọn yẹn ò fi rẹ́ gan-an nìyẹn.”—Shirley.
Ǹjẹ́ o ti ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí ẹ́ lórí fóònù tàbí kó o kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ nígbà tó ò ń wa ọkọ̀ tàbí tó o wà nínú kíláàsì?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ́
Tó o bá ń bá àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, ṣé o máa ń dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu kó o lè fèsì ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí ẹ lórí kọ̀ǹpútà, dáhùn ìpè tàbí kó o ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí ẹ lórí fóònù?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ́
Ṣé lílò tó ò ń lo ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde kì í jẹ́ kó o ráyè sùn, tàbí kó má jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ sórí ẹ̀kọ́ rẹ?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ́
Bó O Ṣe Lè Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì
Tó o bá ń lo ohun èlò èyíkéyìí tó ń gbé ìsọfúnni jáde, yálà kọ̀ǹpútà, fóònù alágbèéká tàbí ohun èlò míì, bi ara rẹ láwọn ìbéèrè mẹ́rin tó wà nísàlẹ̀ yìí. Tó o bá fi àwọn ìmọ̀ràn tá a gbé karí Bíbélì tó wà níbẹ̀ sílò, tó o sì tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tó wà níbẹ̀, ó máa jẹ́ kó o wà ní aláàfíà, wàá sì lè máa ṣàkóso bó o ṣe ń lo àwọn ohun èlò náà.
1. Kí ló dá lé lórí? “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8.
Máa bá àwọn tó wà nínú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, kó o sì máa sọ ohun tó ń gbéni ró.—Òwe 25:25; Éfésù 4:29.
Má ṣe tan òfófó tó lè pani lára kálẹ̀, má ṣe fi ọ̀rọ̀ oníṣekúṣe tàbí àwòrán tó ń múni nífẹ̀ẹ́ sí ìbálòpọ̀ ránṣẹ́, má sì ṣe wo fídíò tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n tí kò bójú mu.—Kólósè 3:5; 1 Pétérù 4:15.
2. Ìgbà wo ni mo máa ń lò ó? “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.”—Oníwàásù 3:1.
Máa fi ìwọ̀n sí iye àkókò tó o máa lò lórí pípe àwọn èèyàn tàbí gbígba ìpè àti fífi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́, wíwo ètò orí tẹlifíṣọ̀n tàbí gbígbá géèmù orí kọ̀ǹpútà. Láti fi ọ̀wọ̀ hàn, pa ohun èlò rẹ nígbà tó o bá wà ní ibi tí wọ́n ti ń ṣe nǹkan pàtàkì, irú bíi níbi ìpàdé fún ìjọsìn. O lè ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá fi ránṣẹ́ sí ẹ kó o sì fèsì nígbà míì.
Má ṣe jẹ́ kí lílò tí ò ń lo ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde gba àkókò tó o ti yà sọ́tọ̀ láti lò pẹ̀lú ìdílé rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àkókò tó yẹ kó o fi kẹ́kọ̀ọ́ tàbí èyí tó yẹ kó o fi lọ́wọ́ nínú nǹkan míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run.—Éfésù 5:15-17; Fílípì 2:4.
3. Àwọn wo ni mò ń bá kẹ́gbẹ́? “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 15:33.
Máa lo ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde láti mú kí àjọṣe tó wà láàárín ìwọ àtàwọn tí wọ́n ń fún ẹ ní ìṣírí láti ṣe ohun tó tọ́ lágbára.—Òwe 22:17.
Má ṣe tan ara rẹ jẹ, wàá kọ́ àṣà, èdè àti ìrònú àwọn tó o yàn láti bá kẹ́gbẹ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ orí kọ̀ǹpútà, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń fi ránṣẹ́ lórí fóònù, tẹlifíṣọ̀n tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Òwe 13:20.
4. Báwo ni mo ṣe ń pẹ́ tó nídìí rẹ̀? “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.
Máa wo iye àkókò tó ò ń lò nídìí ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde.
Má ṣe kọ etí dídi bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá sọ fún ẹ pé o ti ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde, kó o sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí àwọn òbí rẹ bá fún ẹ.—Òwe 26:12.
Nígbà tí Andrew tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè lo ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó dáa, ó ní: “Àwọn ohun èlò wọ̀nyí máa ń múni lórí yá, àmọ́ fún ìgbà díẹ̀ ni. Mo ti kọ́ láti má ṣe jẹ́ kí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ di ohun ìdènà tó máa pín mi níyà kúrò lọ́dọ̀ ìdílé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi.”
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ
“Àwọn òbí mi sábà máa ń sọ fún mi pé ‘Bóyá la ò ṣì ní lẹ fóònù yìí mọ́ ẹ lọ́wọ́, pẹ̀lú bó o ṣe ń lò ó yìí! Lákọ̀ọ́kọ́, eré ni mo kọ́kọ́ pè é, àmọ́ nígbà tó yá mo rí i pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré. Àmọ́ ní báyìí, mo ti dín bí mo ṣe máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù kù, mo sì wá láyọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ!”
“Ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n máa wò ó bóyá wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ní gbogbo ìgbà tí àyè bá ṣí sílẹ̀. Mi ò kì í ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi, mi ò sì fojú sí ẹ̀kọ́ mi mọ́. Àmọ́ mo ti jáwọ́ nínú ìyẹn báyìí, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n gbé ẹrù tó wúwo kan kúrò léjìká mi. Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì lòògùn ẹ̀.”
[Àwọn àwòrán]
Jovarny
Mariah
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
“ÌKÀNNÌ TÁWỌN ÈÈYÀN TI Ń FỌ̀RỌ̀ JOMI TORO Ọ̀RỌ̀ LÓRÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ DI BÁRAKÚ FÚN MI”
“Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, ìdílé wa kó kúrò ní àdúgbò tá à ń gbé. Mo sì fẹ́ máa gbúròó àwọn ọ̀rẹ́ mi, torí náà wọ́n ní kí n wá wọ ìkànnì kan tá a ti lè máa rí fọ́tò ara wa. Ìyẹn jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè máa gbà gbúròó ara wa. Àwọn ọ̀rẹ́ tí mo mọ̀ nìkan ni màá máa bá sọ̀rọ̀ kì í ṣe àwọn àjèjì, ǹjẹ́ ewu kankan wà nínú ìyẹn?
“Ní ìbẹ̀rẹ̀ gbogbo ẹ̀ ń lọ dáadáa. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ ni mo máa ń lọ sórí ìkànnì náà láti wo fọ́tò àwọn ọ̀rẹ́ mi, tí màá kọ ọ̀rọ̀ síbẹ̀, màá sì ka ohun tí wọ́n sọ nípa àwọn fọ́tò mi. Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wọ̀ mí lára. Kí n tó mọ̀, ó ti di pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń wà lórí ìkànnì náà. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo fi ń wà níbẹ̀, àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí, wọ́n á sì pè mí láti wá di ọ̀rẹ́ àwọn. Bó ṣe máa ń rí ni pé, ọ̀rẹ́ kan á sọ pé, ẹni yìí mọ bí wọ́n ṣe ń dáni lára yá, torí náà wàá gbà pé kó di ọ̀rẹ́ rẹ. Kó o tó ṣẹ́jú pẹ́, o ti ní ọ̀rẹ́ tó tó àádọ́ta lórí ìkànnì náà.
“Kò pẹ́ tí mo fi wá rí i pé, ńṣe ló kàn máa ń wù mí ṣáá láti wà lórí ìkànnì náà. Kódà, nígbà tí mo bá wà níbẹ̀, màá tún ti máa ronú ìgbà tí màá tún pa dà wá àti pé mo ní láti fi fọ́tò mi tuntun síbẹ̀. Màá ka ohun tí àwọn èèyàn sọ, màá fi fídíò síbẹ̀, kí n sì tó ṣẹ́jú pẹ́, ọ̀pọ̀ wákàtí ti kọjá lọ.
“Ó tó ọdún kan ààbọ̀ tí mo fi ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ nígbẹ̀yìn mo wá rí i pé ó ti di bárakú fún mi. Ní báyìí, mo ti ń ṣọ́ bí mo ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, mo sì gbájú mọ́ yíyan àwọn ọ̀rẹ́ lójúkojú, ìyẹn àwọn èèyàn tí mo mọ̀ pé ìlànà ìwà rere kan náà la jọ ń tẹ̀ lé. Àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi kò mọ ìdí tí mo fi ṣe ohun tí mo ṣe, àmọ́ mo ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe mi.”—Ellen, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18].
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?
Nígbà míì ẹnu lè yà ẹ́ nígbà tó o bá dá ìjíròrò nípa eré ìnàjú sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Cheryl sọ pé: “Ìgbà kan wà tí dádì mi fura pé ọ̀kan lára àwọn orin tí mò ń gbọ́ kò dáa. Mo béèrè lọ́wọ́ wọn bóyá a lè jọ gbọ́ orin náà látòkè délẹ̀. Wọ́n sì gba ohun tí mo sọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún mi pé àwọn ò rí ohun tó burú níbẹ̀.”
Kọ àwọn ìbéèrè tí wàá fẹ́ béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ nípa ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde sí ìsàlẹ̀ yìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ
Ṣé ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà máa ń lo àkókò tó pọ̀ jù lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tó máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù tó sì máa ń gba ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i lórí fóònù, àbí ẹ̀rọ MP3 tí wọ́n fi ń gbọ́ orin ló máa ń gbájú mọ́ dípò kó máa bá ẹ̀yin òbí rẹ̀ sọ̀rọ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ kí lẹ lè ṣe?
Ẹ lè rò pé ohun tó máa yanjú ìṣòro yìí ni pé kẹ́ ẹ gba ohun èlò náà kúrò lọ́wọ́ ọmọ yín. Àmọ́, ẹ má ṣe bẹnu àtẹ́ lu gbogbo ohun èlò tó ń gbé ìsọfúnni jáde o. Ó ṣe tán, ẹ̀yin náà ń lo àwọn ohun èlò tó ń gbé ìsọfúnni jáde tí àwọn òbí yín kò lò. Dípò kẹ́ ẹ gba àwọn ohun èlò tí àwọn ọmọ yín ń lò lọ́wọ́ wọn, kí ló dé tí ẹ kò fi lo àkókò yẹn láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa fọgbọ́n lo àwọn ohun èlò wọ̀nyí, kí wọ́n sì máa lò ó ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì? Àyàfi tí ìdí míì bá wà tẹ́ ẹ fi fẹ́ gbà á lọ́wọ́ wọn. Báwo lẹ ṣe lè ṣe é?
Ẹ pe àwọn ọmọ yín jókòó, kẹ́ ẹ sì jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú wọn. Àkọ́kọ́, ẹ sọ ohun tó ń kọ yín lóminú. Èkejì, ẹ gbọ́ ohun tí àwọn náà fẹ́ sọ. (Òwe 18:13) Ẹ̀kẹta, ẹ sọ àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe fún wọn. Ẹ má ṣe bẹ̀rù láti fún wọn ní ìtọ́ni pàtó, àmọ́ ẹ fi òye bá wọn lò. (Fílípì 4:5) Ellen tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, sọ pé: “Lákòókò kan tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ṣáá ni mo máa ń kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, àwọn òbí mi kò gba fóònù mi lọ́wọ́ mi, ńṣe ni wọ́n kàn fún mi ní ìlànà tí màá máa tẹ̀ lé. Bí wọ́n ṣe bójú tó ọ̀ràn náà ti ràn mí lọ́wọ́ láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kódà bí àwọn òbí mi ò bá tiẹ̀ sí níbẹ̀ láti wo ohun tí mò ń ṣe.”
Bí àwọn ọmọ yín kò bá wá fẹ́ tẹ̀ lé ohun tẹ́ ẹ sọ ńkọ́? Ẹ má ṣe parí èrò sí pé ìmọ̀ràn yín kò wọ̀ wọ́n létí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ ṣe sùúrù, kẹ́ ẹ sì fún wọn láyè láti ronú nípa ọ̀rọ̀ náà. Ó ṣì ṣeé ṣe kí wọ́n gbọ́ ohun tẹ́ ẹ sọ, kí wọ́n sì ṣe àyípadà tó bá yẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni ọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Hailey, tó sọ pé: “Inú kọ́kọ́ bí mi nígbà tí àwọn òbí mi sọ pé mo ti jẹ́ kí kọ̀ǹpútà di bárakú fún mi. Àmọ́ nígbà tó yá, bí mo ṣe ń ronú nípa rẹ̀, mo wá rí i pé àwọn gan-an ló tọ̀nà.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ṣé ìwọ lò ń darí ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde tó o ní, àbí òun ló ń darí rẹ?