Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ sí Ogun Jíjà Lóde Òní?
NÍGBÀ tí Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi jagunjagun, ó sọ pé: “[Ọlọ́run] ń kọ́ ọwọ́ mi fún ogun, apá mi sì ti tẹ ọrun bàbà.”—Sáàmù 18:34.
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni, ó sọ pé: “Nítorí bí àwa tilẹ̀ ń rìn nínú ẹran ara, a kò ja ogun gẹ́gẹ́ bí ohun tí a jẹ́ nínú ẹran ara. Nítorí àwọn ohun ìjà ogun wa kì í ṣe ti ara.”—2 Kọ́ríńtì 10:3, 4.
Ǹjẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjèèjì yìí ta ko ara wọn? Àbí àwọn ìdí pàtàkì wà tí Ọlọ́run fi gbà kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì máa jagun, àmọ́ tí kò fọwọ́ sí i pé kí àwọn Kristẹni máa jagun? Ǹjẹ́ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ogun jíjà ti yí pa dà? A máa rí ìdáhùn tó ṣe kedere sí àwọn ìbéèrè yìí tá a bá ṣàyẹ̀wò ìyàtọ̀ pàtàkì mẹ́ta tó wà láàárín Ísírẹ́lì àtijọ́ àti ìjọ Kristẹni tòótọ́.
Ìyàtọ̀ Pàtàkì Mẹ́ta
1. Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ní ààlà ilẹ̀ tó jẹ́ tiwọn, àwọn òǹrorò ẹ̀dá ló sì sábà máa ń yí wọn ká. Torí èyí, Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n dáàbò bo ilẹ̀ wọn, ó sì ń mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. (Onídàájọ́ 11:32, 33) Àmọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ kò ní ààlà ilẹ̀, káàkiri ayé ni èèyàn ti lè rí wọn. Torí náà, tí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó wà ní orílẹ̀-èdè kan bá gbé ogun ja orílẹ̀-èdè mìíràn, ńṣe ni wọ́n á máa bá onígbàgbọ́ bíi ti wọn jà, ìyẹn àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn tí wọ́n jọ ń jọ́sìn Ọlọ́run, àwọn tí Jésù sọ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ kí wọ́n sì kú fún pàápàá.—Mátíù 5:44; Jòhánù 15:12, 13.
2. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ní ọba kan tí ìtẹ́ rẹ̀ wà ní ìlú Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, Jésù Kristi ló ń ṣàkóso àwọn Kristẹni tòótọ́, ìyẹn ẹni tó ti di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára báyìí, tí ìtẹ́ rẹ̀ sì wà ní ọ̀rún. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” (Jòhánù 18:36) Èyí fi hàn pé, kò sí ìjọba tàbí ìṣàkóso kan lórí ilẹ̀ ayé tó lè sọ pé ti Kristi ni òun. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ yìí fi ṣe pàtàkì sí àwọn “ẹmẹ̀wà” Jésù tàbí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? Kókó kẹta máa ṣàlàyé.
3. Gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè tó kù náà ṣe máa ń ṣe, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ máa ń rán àwọn oníṣẹ́ jáde, ìyẹn àwọn tá a mọ̀ lónìí sí àwọn aṣojú ìjọba ní ilẹ̀ òkèèrè tàbí ikọ̀. (2 Ọba 18:13-15; Lúùkù 19:12-14) Kristi náà ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ ọ̀nà pàtàkì méjì ni tirẹ̀ gbà yàtọ̀. Àkọ́kọ́, gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ló ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú tàbí ikọ̀. Èyí ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Nítorí náà, àwa jẹ́ ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 5:20) Wọ́n kì í gbé ohun ìjà ogun, nítorí pé oníṣẹ́ àlàáfíà ni wọ́n. Ohun kejì ni pé, gbogbo àwọn tó bá fẹ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ wọn ni wọ́n máa ń wàásù fún. Jésù sọ pé “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Ó tún sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè “di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.
Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í sábà fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹmẹ̀wà Kristi. Èyí ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Kristẹni ajíhìnrere náà, Tímótì pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun àtàtà ti Kristi Jésù, kó ipa tìrẹ nínú jíjìyà ibi.” (2 Tímótì 2:3) Àwọn ohun ìjà Tímótì jẹ́ àwọn ohun ti ẹ̀mí, tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà nínú rẹ̀, èyí tó jẹ́ “idà ẹ̀mí.”—Éfésù 6:11-17.
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Pa Ísírẹ́lì Ìgbàanì Tì Tó Sì Wá Ń Lo Ìjọ Kristẹni?
Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [1,500] ọdún ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ fi gbádùn àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, nítorí májẹ̀mú tàbí àdéhùn tó wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 19:5) Mósè lo ṣe alárinà májẹ̀mú náà, èyí sì kan Òfin Mẹ́wàá àtàwọn òfin mìíràn, gbogbo ìwọ̀nyí ló sì gbé ìjọsìn tòótọ́ àti ìwà rere lárugẹ. (Ẹ́kísódù 19:3, 7, 9; 20:1-17) Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run, débi pé wọ́n pa àwọn wòlíì Ọlọ́run.—2 Kíróníkà 36:15, 16; Lúùkù 11:47, 48.
Níkẹyìn, Jèhófà rán Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, tí wọ́n bí gẹ́gẹ́ bíi Júù. Dípò kí àwọn Júù tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà náà, ńṣe ni wọ́n kọ̀ ọ́. Èyí ló mú kí Ọlọ́run fòpin sí májẹ̀mú tó ti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá fún ìgbà pípẹ́, ògiri ìṣàpẹẹrẹ tó pààlà sáàárín àwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù sì wó lulẹ̀.a (Éfésù 2:13-18; Kólósè 2:14) Àárín àkókò yìí ni Ọlọ́run dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ tó sì fi Jésù ṣe Orí ìjọ náà. Bákan náà, kí ọ̀rúndún kìíní tó parí, ìjọ yẹn ti di èyí tó kún fún àwọn èèyàn látinú onírúurú ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè. Àpọ́sítélì Pétérù tó jẹ́ Júù sọ pé: “Ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù [Ọlọ́run], tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:35.
Àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé. Ìdí nìyẹn táwọn èèyàn fi mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa fún iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n máa ń ṣe àti bí wọn kì í ṣe é lọ́wọ́ sí ìṣèlú àti ogun. (Mátíù 26:52; Iṣe 5:42) Wọ́n kì í jẹ́ kí ohunkóhun dí wọn lọ́wọ́ kíkéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba kan ṣoṣo tó máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò tó sì máa mú àlàáfíà tí kò lópin wá sí ayé. Ìrètí àgbàyanu yìí ló wà lọ́kàn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà tó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn adípò fún Kristi, àwa bẹ̀bẹ̀ pé: ‘Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́.’” (2 Kọ́ríńtì 5:20) Ọ̀rọ̀ yìí ti túbọ̀ wá jẹ́ kánjúkánjú gan-an báyìí, torí pé a ti ń sún mọ́ òpin “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé burúkú yìí.—2 Tímótì 3:1-5.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tá à ń lo ọ̀rọ̀ náà “Júù” fun tẹ́lẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wá láti ẹ̀yà Júdà. Àmọ́, nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í lo orúkọ náà fún gbogbo àwọn tó jẹ́ Hébérù.—Ẹ́sírà 4:12.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Ànímọ́ tó ṣe pàtàkì wo ló yẹ káwọn Kristẹni máa fi hàn sí ara wọn?—Jòhánù 13:34, 35.
● “Ohun ìjà” tó ṣe pàtàkì jù lọ wo làwọn Kristẹni ní?—Éfésù 6:17.
● Iṣẹ́ pàtàkì wo làwọn aṣojú Kristi ń jẹ́?—Mátíù 24:14; 2 Kọ́ríńtì 5:20.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Látinú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni àwọn tó para pọ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá, wọn kì í sì í lọ́wọ́ sí ogun táwọn orílẹ̀-èdè ń bára wọn jà