Ohun Tí Àwọn Òbí Sọ
Tó o bá ní ọmọ tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ iléèwé, ó ṣeé ṣe kó o máa dojú kọ àwọn ìṣòro kan. Bí àpẹẹrẹ, báwo lo ṣe máa bójú tó ọmọ tó ń ṣe ìjọ̀ngbọ̀n? Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, kó o sì tọ́ ọ sọ́nà láì ki àṣejù bọ̀ ọ́? Wo bí àwọn òbí kan ṣe bójú tó àwọn ìṣòro náà.
ỌMỌ TÓ Ń ṢE ÌJỌ̀NGBỌ̀N
“Nígbà tí ọmọ bá wà ní ọmọ ọdún méjì, àkókò yìí máa ń ṣòro gan-an fún àwọn òbí, torí pé ọmọ máa ń fẹ́ ní gbogbo ohun tó bá ti wù ú. Ọmọ wa ọkùnrin ní irú ìṣòro yìí. Tá ò bá ṣe ohun tó fẹ́ fún un, ńṣe ló máa bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohunkóhun tó bá tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ nù. Òun ni àkọ́bí wa, torí náà a ò mọ̀ pé bí àwọn ọmọde ṣe máa ń ṣe ìjọ̀ngbọ̀n nìyẹn. Ara kì í tù wá, kódà bí àwọn òbí mìíràn bá sọ fún wa pé bí àwọn ọmọ tó wà ní ọjọ́ orí yẹn ṣe máa ń ṣe nìyẹn.”—Susan, Kẹ́ńyà.
“Nígbà tí ọmọ wa obìnrin wà ní ọmọ ọdún méjì, yóò sùn sílẹ̀, á máa pariwo, á máa sunkún, á máa fẹsẹ̀ ta nǹkan . . . Èyí máa ń bíni nínú gan-an! Tá a bá ní ká bá a sọ̀rọ̀ nírú àkókò yẹn, kò ní gbọ́. Èmi àti ọkọ mi á wá sọ fún un pé kó kọjá sínú yàrá rẹ̀, a ó sì fi ohùn jẹ́jẹ́ sọ fún un pé tára ẹ̀ bá ti balẹ̀, ó lè jáde wá bá wa, ká lè jọ jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú rẹ̀. Tí ara rẹ̀ bá ti balẹ̀, ọ̀kan lára wa á lọ bá a nínú yàrá rẹ̀, a ó sì jẹ́ kó mọ ìdí tí a kò fi fara mọ́ ìwà tó hù. Ohun tá à ń ṣe yìí máa ń yọrí sí rere. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tá a gbọ́ tó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó dárí ji òun. Nígbà tó yá, kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe ìjọ̀ngbọ̀n mọ́, ó sì jáwọ́ nínú ṣiṣẹ́ ìjọ̀ngbọ̀n pátápátá.”—Yolanda, Sípéènì.
“Àwọn ọmọdé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rìn máa ń dán àwọn nǹkan kan wò láti mọ bóyá ó máa rí bẹ́ẹ̀. Tó o bá gba ọmọ láyè láti ṣe ohun tí o ti kìlọ̀ fún un pé kò gbọ́dọ̀ ṣe, kò ní jẹ́ kí ọmọ náà mọ ohun tó o fẹ́ gan-an. A ti wá rí i pé tá a bá dúró lórí ohun tá a sọ, àwọn ọmọ wa á bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pé igbe kíké kọ ló máa jẹ́ kí àwọn rí ohun tí àwọn ń fẹ́ gbà.”—Neil, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
ÌBÁWÍ
“Bí ọmọ kò bá tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún, ó máa ń ṣòro láti mọ̀ bóyá ó ń fetí sílẹ̀. Sísọ àsọtúnsọ ni oògùn rẹ̀. O ní láti sọ ọ̀rọ̀ náà ní àsọtúnsọ lọ́pọ̀ ìgbà, kó o fara ṣàpèjúwe, kó o sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe ṣàkó.”—Serge, Faransé.
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi kan náà la ti tọ́ àwọn ọmọ wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, àmọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ní ìwà tiẹ̀. Ọ̀kan á máa ké tó bá ti mọ̀ pé òun ti ṣe ohun tó dùn wá; òmíràn á gbìyànjú láti rí i bóyá òun lè mú ká ṣe ohun tó fẹ́. Nígbà míì ojú lásán tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu la máa fi bá wọn wí, ìgbà míì sì wà tá a máa ní láti fìyà jẹ wọ́n.”—Nathan, Kánádà.
“Ó ṣe pàtàkì kéèyàn má máa yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà. Lẹ́sẹ̀ kan náà, kò yẹ kí òbí jẹ́ kìígbọ́-kìígbà tàbí ẹni tó le koko jù. Nígbà míì tá a bá rí i pé ọmọ wa ti kábàámọ̀ ohun tó ṣe, a máa ń wò ó pé ohun tó dára jù ni pé ká fi òye hùwà sí i, ká sì dín ìyà tá a fẹ́ fi jẹ́ ẹ kù.”—Matthieu, Faransé.
“Mó máa ń gbìyànjú láti má ṣe òfin tó pọ̀ jù, àmọ́ mi ò kì í yí ìwọ̀nba tí mo bá ṣe pa dà. Ọmọ mi ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta mọ ohun tí màá ṣe fún òun tó bá ṣe àìgbọràn, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó mọ irú ìwà tó máa hù. Lóòótọ́, nígbà tó bá rẹ̀ mí ó máa rọrùn láti fojú pa ìwà àìtọ́ tó bá hù rẹ́. Àmọ́ kí n bàa lè dúró lórí ohun tí mo sọ, mo máa ń mú ara mi ní ọ̀ranyàn. Ó dáa ká máa dúró lórí ohun tá a bá sọ!”—Natalie, Kánádà.
DÚRÓ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ RẸ
“Ọpọlọ àwọn ọmọdé pé gan-an, bí ọ̀rọ̀ àwọn òbí kò bá dọ́gba, wọ́n á mọ̀.”—Milton, Bòlífíà.
“Nígbà míì ọmọ mi ọkùnrin á béèrè ohun kan náà ní onírúurú ọ̀nà, kó lè mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ mi á yàtọ̀ síra. Bí mo bá sì sọ pé kó ṣe ohun kan àmọ́ tí ohun tí mọ́mì rẹ̀ sọ yàtọ̀ sí tèmi, ó máa kà á sí pé ọ̀rọ̀ wa kò dọ́gba, á sì fẹ́ ṣe tinú rẹ̀.”—Ángel, Sípéènì.
“Nígbà míì tí inú mi bá dùn mo máa ń gbójú fo ìwà tí kò dáa tí ọmọ mi bá hù, àmọ́ tínú bá ń bí mi, mo máa ń bá a wí gan-an. Mo wá rí i pé ńṣe lèyí á kàn jẹ́ kó túbọ̀ máa hu ìwà tí kò dáa.”—Gyeong-ok, Kòríà.
“Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọdé mọ̀ pé bí a bá sọ pé ìwà kan kò dáa lónìí, kò dáa náà lá máa jẹ́ títí.”—Antonio, Brazil.
“Bí ọ̀rọ̀ àwọn òbí kò bá ṣọ̀kan, ọmọ á ronú pé èèyàn kò lè mọ ohun tí dádì àti mọ́mì máa ṣe jàre, bí ara wọn bá ṣe rí ló máa ń pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Àmọ́ bí àwọn òbí bá dúró lórí ohun tí wọ́n sọ, àwọn ọmọ á mọ̀ pé ohun tí kò dáa, kò dáa náà ni. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí àwọn òbí lè gbà dáàbò bo àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn.”—Gilmar, Brazil.
“Bí àwọn òbí kò bá ń mọ ohun tí wọ́n máa ṣe, tó jẹ́ pé wọ́n máa ń ṣe ohun tí àwọn ọmọ bá béèrè torí pé àwọn èèyàn wà níbẹ̀, àwọn ọmọ lè máa lo irú àǹfààní yẹn. Tí mi ò bá ní gba ọmọkùnrin mi láyè láti ṣe ohun kan, màá ti sọ fún un láti ìbẹ̀rẹ̀, màá sì jẹ́ kó mọ̀ pé kò sí bó ṣe lè bẹ̀bẹ̀ tó mi ò ní yí ohun tí mo sọ pa dà.”—Chang-seok, Kòríà.
“Ohùn bàbá àti ìyá gbọ́dọ̀ ṣọ̀kan. Bí èmi àti ìyàwó mi ò bá fohùn ṣọ̀kan, a jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tó bá ku àwa méjèèjì. Àwọn ọmọ lè mọ̀ bí ohùn àwọn òbí wọn kò bá ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ kan, wọ́n sì lè gbìyànjú láti lo àǹfààní yìí.”—Jesús, Sípéènì.
“Bí ọmọ kan bá mọ̀ pé ohùn àwọn òbí òun ṣọ̀kan àti pé òun kò lè tàn wọ́n jẹ, ọkàn rẹ̀ á balẹ̀. Wọ́n mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bí àwọn bá gbọ́ràn tàbí tí àwọn bá ṣe àìgbọ́ràn.”—Damaris, Jámánì.
“Èmi àti ìyàwó mi mọ̀ pé, láti fi hàn pé a dúró lórí ọ̀rọ̀ wa, á ní láti mú ìlérí wa ṣẹ nígbà tá a bá sọ fún ọmọ wa obìnrin pé á máa fún un ní nǹkan kan tó dáa. Èyí jẹ́ kó mọ̀ pé òun lè fọkàn tán ìlérí tá a bá ṣe fún òun.”—Hendrick, Jámánì.
“Bí ẹni tó gbà mí síṣẹ́ bá ń yí ojúṣe mi pa dà ní gbogbo ìgbà, ó máa bí mi nínú. Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ náà kò yàtọ̀ sí èyí. Ọkàn wọn máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá mọ ìlànà tá a fi lélẹ̀ fún wọn, tí wọ́n sì mọ̀ pé kò ní yí pa dà. Wọ́n tún ní láti mọ ohun tá a máa ṣe fún wọn bí wọ́n bá ṣe àìgbọràn, kí wọ́n sì mọ̀ pé ìyẹn náà kò ní yí pa dà.”—Glenn, Kánádà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
“Kí Bẹ́ẹ̀ ni yín túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, àti Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.”—Jákọ́bù 5:12
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
ÌSỌFÚNNI NÍPA ÌDÍLÉ
A Lóyún Láìròtẹ́lẹ̀ ÀYÍPADÀ TÁ A ṢE
Gẹ́gẹ́ bí Tom àti Yoonhee Han ṣe sọ ọ́
Tom: Kò tíì ju oṣù mẹ́fà lọ lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó tí Yoonhee, ìyàwó mi rí i pé òun ti lóyún. Lójú, mo ṣe bí i pé kò síṣòro, torí mo fẹ́ kí ìyàwó mi mọ̀ pé òun lè gbára lé mi fún ìtùnú àti okun. Àmọ́, nínú lọ́hùn ún, ẹ̀rù ń bà mí gan-an!
Yoonhee: Gbogbo nǹkan tojú sú mi, ẹ̀rù sì ń bà mí! Mo sunkún títí; ó ń ṣe mí bíi pé mi ò tíì ṣe tán láti bímọ, mi ò sì kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ ìyá ọmọ.
Tom: Èmi náà kò tíì ṣe tán láti di bàbá báyìí! Àmọ́ nígbà tá a bá àwọn òbí míì sọ̀rọ̀, a wá rí i pé oyún àìròtẹ́lẹ̀ wọ́pọ̀ ju bá a ṣe rò lọ. Bákan náà, ó tún fún wa láǹfààní láti gbọ́ ohun tí àwọn òbí mìíràn fẹ́ sọ nípa ayọ̀ tó wà nínú jíjẹ́ bàbá àti ìyá. Díẹ̀díẹ̀, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í fojú sọ́nà, èyí sì rọ́pò ẹ̀rù tó ń bà mí àti bí mi ò ṣe dá ara mi lójú.
Yoonhee: Lẹ́yìn tá a bí Amanda, a tún wá dojú kọ àwọn ìpèníjà tuntun. Ńṣe ló máa ń sunkún ṣáá, mi ò sì lè sùn dáadáa fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀. Oúnjẹ kò lọ lẹ́nu mi, mi ò sì lókun nínú mọ́. Níbẹ̀rẹ̀ mi ò kì í fẹ́ wà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Àmọ́, mo wá rí i pé, dídé ara mi mọ́lé kò lè ṣe ìrànlọ́wọ́ kankan. Torí náà, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ. Èyí fún mi láǹfààní láti jíròrò ìṣòro mi pẹ̀lú àwọn míì, ó sì jẹ́ kí ń rí i pé kì í ṣe èmi nìkan ni mo ní ìṣòro.
Tom: Mo sapá ká lè máa ṣe àwọn nǹkan tá à ń ṣe déédéé nínú ìdílé wa nìṣó. Bí àpẹẹrẹ, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, èmi àti Yoonhee ìyàwó mi sì pinnu pé a ó máa lọ sí òde ìwàásù déédéé, a ò sì ní máa pa ìpàdé Kristẹni jẹ. Láfikún sí i, ní báyìí tá a ti ní ọmọ, owó tá à ń ná túbọ̀ pọ̀ sí i, àwọn ìnáwó kan sì wà tí a kì í rò tẹ́lẹ̀. A rí i dájú pé a kì í ná kọjá iye tó ń wọlé fún wa, ká má bàa kọrùn bọ gbèsè, èyí tó máa mú kí wàhálà pọ̀ sí i lọ́rùn wa.
Yoonhee: Mo kọ́kọ́ ronú pé kó mọ́gbọ́n dání pé kí n máa lọ wàásù, torí pé àwọn ọmọdé máa ń díni lọ́wọ́. Àmọ́ ká sòótọ́, àwọn èèyàn fẹ́ràn kí wọ́n máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọdé. Èyí ló jẹ́ kí n máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé, ó sì jẹ́ kí n túbọ̀ ní èrò tó tọ́ nípa ọmọ mi.
Tom: Bíbélì sọ pé “àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà” wọ́n sì tún jẹ́ “èrè.” (Sáàmù 127:3) Fún èmi o, ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ẹ̀bùn pàtàkì ni ọmọ jẹ́. Bíi ti ogún èyíkéyìí téèyàn bá jẹ, ọwọ́ rẹ ló kù sí: O lè lò ó lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání, o sì lè lò ó nílòkulò. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ìpele kọ̀ọ̀kan tí ọmọ ń dé bó ṣe ń dàgbà ló ṣàrà ọ̀tọ̀, mo sì fẹ́ kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé ọmọ mi bó ṣe ń bọ́ sí ipele kọ̀ọ̀kan, torí pé bí àǹfààní yẹn bá ti kọjá lọ, o ò tún lè pa dà rí i mọ́.
Yoonhee: Nígbà míì, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa máa ń yani lẹ́nu, àmọ́ níní ọmọ tá ò múra sílẹ̀ fún kì í ṣe nǹkan ìyàlẹ́nu tó burú. Amanda ọmọ wa ti di ọmọ ọdún mẹ́fà báyìí, mo sì máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣáá ni.
[Àwòrán]
Tom àti Yoonhee pẹ̀lú Amanda, ọmọbìnrin wọn