Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ó Pọn Dandan Kó O Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kankan?
TÓ BÁ jẹ́ pé àwọn nǹkan tó o ti rí nínú ẹ̀sìn ti mú kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn sú ẹ, tó o wá ń ronú pé ẹ̀sìn ò já mọ́ nǹkan kan, ìwọ nìkan kọ́ lo máa ń nírú èrò yìí. Kódà, ṣe ni iye àwọn èèyàn tí kò dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kankan túbọ̀ ń pọ̀ sí i.
Àwọn kan ti pa ẹ̀sìn tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ tẹ́lẹ̀ tì torí wọ́n gbà pé àgàbàgebè inú ìsìn wọ̀nyẹn pọ̀, wọn kì í sì í rára gba nǹkan sí. Ó máa ń ni àwọn ẹlòmíì lára láti máa tẹ̀ lé ọ̀nà ìjọsìn kan pàtó. Síbẹ̀, àwọn kan gbà pé kò pọn dandan fún àwọn láti dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kankan kí àwọn tó lè jọ́sìn Ọlọ́rùn. Kí ni Bíbélì tiẹ̀ sọ nípa dídara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn?
Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Nígbà Àtijọ́
Bíbélì ṣàlàyé tó ṣe kedere nípa bí àwọn baba ńlá ayé ìgbàanì, irú bí Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù ṣe jọ́sìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ nígbà kan pé: “Mo ti di ojúlùmọ̀ [Ábúráhámù] kí ó lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ àti agbo ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n bàa lè pa ọ̀nà Jèhófà mọ́ láti ṣe òdodo àti ìdájọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:19) Ábúráhámù jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ní àjọṣe tààràtà pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá bí ọ̀rẹ́ sí ọ̀rẹ́. Síbẹ̀, òun àti agbo ilé rẹ̀ tún jọ sin Ọlọ́run pa pọ̀. Bákan náà, àwọn baba ńlá míì ní ayé ìgbàanì táwọn náà jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, máa ń kóra jọ pẹ̀lú àwọn ẹ̀lòmíì, irú bí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àtàwọn ẹrú wọn kí wọ́n lè jọ́sìn Ọlọ́run pa pọ̀.
Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì àti lẹ́yìn náà, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, pé kí wọ́n máa kóra jọ fún ìjọsìn. (Léfítíkù 23:2, 4; Hébérù 10:24, 25) Láwọn ìgbà tí wọ́n bá pé jọ fún irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń kọrin, wọ́n máa ń ka Ìwé Mímọ́, wọ́n sì máa ń gbàdúrà pa pọ̀. (Nehemáyà 8:1-8; Kólósè 3:16) Ìwé Mímọ́ tún sọ pé kí àwùjọ àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n máa mú ipò iwájú nínú ìjọ nígbà ìjọsìn.—1 Tímótì 3:1-10.
Àǹfààní Tó Wà Nínú Ká Jọ Máa Sin Ọlọ́rùn Nínú Ìjọ
Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tá a gbé yẹ̀ wò nínú Bíbélì yìí, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé, Ọlọ́run máa retí pé kí àwa ọ̀rẹ́ rẹ̀ lóde òní náà máa pé jọ láti jọ́sìn rẹ̀. Àǹfààní púpọ̀ ló sì wà nínú jíjọ sin Ọlọ́run nínú ìjọ.
Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ fi àwọn tó ń fi tọkàntọkàn jọ́sìn Ọlọ́run wé ẹni tó ń rìn ní ojú ọ̀nà híhá, nínú àpẹẹrẹ míì, ó fi wọ́n wé ẹni tó ń sá eré ìdíje. (Mátíù 7:14; 1 Kọ́ríńtì 9:24-27) Ó lè tètè rẹ sárésáré kan tó ń sáré ìje ẹlẹ́mìí ẹṣin gba ọ̀nà págunpàgun, kó sì wá tipa bẹ́ẹ̀ pa eré ìje náà tì. Àmọ́ tí sárésáré náà bá rí ìṣírí gbà lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì, ó lè ṣe kọjá ohun tó rò pé agbára rẹ̀ gbé. Bákan náà, ẹni tó bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run dáadáa lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, láìka àdánwò tó lè dé báa sí, tó bá ń rí ìṣírí gbà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe ìjọsìn.
Èyí lè jẹ́ ká túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ nínú ìwé Hébérù 10:24, 25 pé: “Ẹ jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.” Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Ọlọ́run pa pọ̀ bí ọmọ ìyá kan náà, wọ́n á wà ní ìṣọ̀kan bíi pé wọ́n jẹ́ ara kan náà.
Bíbélì sọ pé ìfẹ́ àti àlàáfíà ló máa so ara tàbí ìjọ yẹn pọ̀, tí wọ́n á sì wà ní ìṣọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, Éfésù 4:2, 3 gba àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ níyànjú láti máa ṣe ohun gbogbo “pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́, kí ẹ máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” Báwo lo ṣe lè fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò tó bá jẹ́ pé ṣe lò ń dá sin Ọlọ́run, tí o sì kọ̀ láti pé jọ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì tí wọ́n jẹ́ olùjọ́sìn?
Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ jọ gba ohun kan náà gbọ́, kí wọ́n sì máa jọ́sìn òun pa pọ̀, dípò kí oníkálùkù tó gbà pé òun sún mọ́ Ọlọ́run máa dá jọ́sìn. Bíbélì gba àwọn olùjọ́sìn níyànjú láti máa fohùn ṣọ̀kan, kí wọ́n má ṣe fàyè gba ìpínyà, ‘kí a lè so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.’ (1 Kọ́ríńtì 1:10) Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn máa dá nìkan sin òun ni, a jẹ́ pé ohun tá a kà nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn kò nítumọ̀ kankan.
Ní kedere, ẹ̀rí tá a rí látinú Bíbélì fi hàn pé inú Ọlọ́run máa ń dùn sí ìjọsìn tá a bá para pọ̀ ṣe. Ìjọsìn tá a para pọ̀ ṣe, irú èyí tí Ìwé Mímọ́ sọ, tá a sì ṣe lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́, lè fún ẹ ní ìtìlẹ́yìn tó o nílò kó o lè máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó máa mú inú rẹ dùn.—Mátíù 5:3.
Òótọ́ ni pé àgàbàgebè àtàwọn ìwà burúkú míì tí kò lóǹkà ló kún ọwọ́ àwọn onísìn lóde òní. Síbẹ̀, kò yẹ kó o wá máa wò ó pé gbogbo ìsìn táwọn èèyàn ń pé jọ láti ṣe ni kò já mọ́ nǹkan kan. Ẹ̀sìn kan táwọn èèyàn ń para pọ̀ ṣe ní láti wà láyé yìí tí àwọn tó ń ṣe é ń fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn, tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa irú ìwà tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa hù. Irú ẹ̀sìn tá à ń para pọ̀ ṣe yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ojúlówó ìgbàgbọ́. Bíbélì sọ àwọn àmì tó o lè fi dá ẹ̀sìn táwọn èèyàn ń para pọ̀ ṣe, tí inú Ọlọ́run sì dùn sí mọ̀.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Ǹjẹ́ àpẹẹrẹ kankan tiẹ̀ wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé ká máa kóra jọ láti jọ́sìn?—Léfítíkù 23:2, 4.
● Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ láti jọ́sìn Ọlọ́run?—Hébérù 10:24, 25.
● Kí ló ń jẹ́ kí àwọn èèyàn lè máa jọ́sìn Ọlọ́run pa pọ̀?—Éfésù 4:2, 3.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]
Ǹjẹ́ ó yẹ kó o máa rò pé gbogbo ìsìn táwọn èèyàn ń pé jọ ṣe ni kò já mọ́ nǹkan kan?