ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 9/1 ojú ìwé 6-7
  • Ìjọsìn Tó Máa Ṣe ọ́ Láǹfààní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjọsìn Tó Máa Ṣe ọ́ Láǹfààní
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Ń Mú Káyé Ẹni Nítumọ̀
  • Ìjọsìn Tòótọ́ Á Jẹ́ Kí Ìwà Rẹ Túbọ̀ Dára Sí I
  • Ìsìn Tó Dára Ń Jẹ́ Ká Ní Ìrètí Pé Ọ̀la Á Dára
  • Ǹjẹ́ Ó Pọn Dandan Kó O Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kankan?
    Jí!—2012
  • Awọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun—Awọn Ènìyàn Aláyọ̀ Tí Wọn Wà Létòlétò
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Jọ́sìn Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 9/1 ojú ìwé 6-7

Ìjọsìn Tó Máa Ṣe ọ́ Láǹfààní

ONÍSÁÀMÙ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ásáfù sọ pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.” Ásáfù ti kọ́kọ́ ń wò ó pé kóun fara wé àwọn tí wọn ò ka Ọlọ́run sí, kóun lè máa gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ. Ṣùgbọ́n ó tún wá ronú nípa àǹfààní tó wà nínú sísúnmọ́ Ọlọ́run, ó sì wá gbà pé ìyẹn gan-an lohun tó dára fóun láti ṣe. (Sáàmù 73:2, 3, 12, 28) Ǹjẹ́ ìjọsìn tòótọ́ lè ṣe ìwọ náà láǹfààní lóde òní? Ọ̀nà wo ló sì lè gbà ṣe ọ́ láǹfààní?

Jíjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún gbígbé ìgbésí ayé ìfẹ́ tara ẹni nìkan. Àwọn tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀ kì í láyọ̀ nítorí pé ìmọtara-ẹni-nìkan ta ko ọ̀nà tí “Ọlọ́run ìfẹ́” gbà dá wa. (2 Kọ́ríńtì 13:11) Jésù kọ́ wa ni ohun pàtàkì kan nípa èèyàn, ó sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ìdí nìyẹn tínú wa fi máa ń dùn láti ṣe nǹkan fáwọn ọ̀rẹ́ wa àti ìdílé wa. Ṣùgbọ́n ṣíṣe nǹkan fún Ọlọ́run ló máa ń mú kí ayọ̀ wa túbọ̀ pọ̀ gan-an. Jèhófà ló yẹ ká fẹ́ràn ju ẹnikẹ́ni lọ. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, tí ìgbésí ayé wọn yàtọ̀ síra ti rí i pé jíjọ́sìn Ọlọ́run nípa ṣíṣe ohun tó ní ká ṣe máa ń fúnni láyọ̀ gan-an.—1 Jòhánù 5:3.

Ohun Tó Ń Mú Káyé Ẹni Nítumọ̀

Àǹfààní mìíràn tó tún wà nínú ìjọsìn tòótọ́ ni pé á mú káyé rẹ nítumọ̀. Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé èèyàn sábà máa ń láyọ̀ tó bá rí i pé òun ń gbé ohun pàtàkì ṣe? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní ohun tí wọ́n ń lé nígbèésí ayé wọn, ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ìdílé wọn, àwọn ọ̀rẹ́, iṣẹ́ ajé, tàbí gbígbafẹ́. Àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sábà fún wọn láyọ̀ nítorí ayé téèyàn ò ti mọ bí ọ̀la ṣe máa rí là ń gbé. (Oníwàásù 9:11) Àmọ́, ìjọsìn tòótọ́ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tó túbọ̀ ń mú káyé ẹni nítumọ̀, ìyẹn ohun tí yóò máa fúnni láyọ̀ àní nígbà tí gbogbo ohun yòókù nígbèésí ayé ẹni bá jáni kulẹ̀.

Ìjọsìn tòótọ́ túmọ̀ sí mímọ Jèhófà kéèyàn sì máa sìn ín tọkàntọkàn. Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń sún mọ́ Ọlọ́run gan-an. (Oníwàásù 12:13; Jòhánù 4:23; Jákọ́bù 4:8) Ó lè ṣòro fún ọ láti gbà pé o lè mọ Ọlọ́run gan-an débi pé yóò di ọ̀rẹ́ rẹ. Tó o bá ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe ń bá àwọn èèyàn lò, tó o sì tún ronú nípa àwọn ohun tó dá, o lè tipa bẹ́ẹ̀ mọ oríṣiríṣi àwọn ànímọ́ tó ní. (Róòmù 1:20) Ìyẹn nìkan kọ́ o, tó o bá tún ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá lè mọ ìdí tá a fi wà láyé yìí, ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹni àti bó ṣe máa fòpin sí ìyà náà. Èyí tá a lè sọ pé ó jọni lójú jù lọ ni pé, á ṣeé ṣe fún ọ láti lè kó ipa pàtàkì nínú sísọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé. (Aísáyà 43:10; 1 Kọ́ríńtì 3:9) Tó o bá lóye àwọn nǹkan wọ̀nyí, ayé ò ní sú ọ rárá!

Ìjọsìn Tòótọ́ Á Jẹ́ Kí Ìwà Rẹ Túbọ̀ Dára Sí I

Ìjọsìn tòótọ́ á ṣe ọ́ láǹfààní nítorí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìwà rẹ túbọ̀ dára sí i. Bó o ṣe ń ṣe ìsìn tòótọ́, wàá dẹni tó láwọn ànímọ́ táá jẹ́ kí àjọṣe àárín ìwọ àtàwọn ẹlòmíì dùn bí oyin. Wàá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ nípa bó o ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ èèyàn, bó o ṣe lè máa sọ̀rọ̀ tìfẹ́tìfẹ́ àti bó o ṣe lè jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé. (Éfésù 4:20–5:5) Nígbà tó o bá mọ Ọlọ́run dáadáa débi tó o fi wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò wù ọ́ láti fara wé e. Bíbélì sọ pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.”—Éfésù 5:1, 2.

Ṣé inú rẹ kò ní dùn tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn tó ní irú ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní ló yí ọ ká? Ó dùn mọ́ni pé jíjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kì í ṣe ohun téèyàn ń dá nìkan ṣe. Ó ń jẹ́ kéèyàn wà pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ohun tó tọ́ àtohun tó dára. Àmọ́ ṣá o, ó lè má rọrùn fún ọ láti dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bá a ti rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìṣòro ọ̀pọ̀ ìsìn kì í ṣe pé wọn ò wà létòlétò, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe ni kò bá ìlànà Bíbélì mú. Ọ̀pọ̀ ìsìn ló ń ṣe àwọn ohun tí kò bá ìlànà Kristẹni mu. Ní ti àwọn èèyàn Ọlọ́run, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ṣètò wọn, fún ìdí rere ló sì fi ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.” (1 Kọ́ríńtì 14:33) Bíi ti ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, wàá rí i pe dídarapọ̀ mọ́ àwùjọ Kristẹni kan tó wà létòlétò yóò jẹ́ kó o túbọ̀ láyọ̀.

Ìsìn Tó Dára Ń Jẹ́ Ká Ní Ìrètí Pé Ọ̀la Á Dára

Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Ọlọ́run ń kó àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ jọ kí wọ́n lè la òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já, kí wọ́n sì jogún ayé tuntun tí ‘òdodo yóò máa gbé.’ (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 7:9-17) Ìjọsìn tó dára ń tipa báyìí fúnni ní ìrètí, èyí tó máa jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Ohun táwọn èèyàn kan gbé ìrètí wọn kà ni àwọn ìjọba tó fìdí múlẹ̀, rírí iṣẹ́ ajé ṣe, tàbí kí ara gbogbo èèyàn le àti kéèyàn fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣàṣà nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ló lè fini lọ́kàn balẹ̀ pé ọjọ́ ọ̀lá ẹni á jẹ́ aláyọ̀. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó yàtọ̀ sí èyí, ó ní: “A ti gbé ìrètí wa lé Ọlọ́run alààyè.”—1 Tímótì 4:10.

Tó o bá ṣèwádìí dáadáa, wàá rí àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́. Ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ló mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ pátápátá nínú ayé tó kún fún ìyapa yìí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè ni wọ́n wà, ipò tí olúkúlùkù wọn wà sì yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ìfẹ́ wọn fún Jèhófà àti fún ara wọn mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan. (Jòhánù 13:35) Wọ́n ń pè ọ́ láti wá fojú ara rẹ rí ohun tí wọ́n ń gbádùn. Ásáfù sọ pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.”—Sáàmù 73:28.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

O lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́