ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 3/14 ojú ìwé 14-15
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Ọmọ Rẹ Obìnrin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Ọmọ Rẹ Obìnrin
  • Jí!—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
  • Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Bó O Ṣe Lè Kojú Àìbalẹ̀ Ọkàn
    Jí!—2020
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Wàhálà Níléèwé?
    Jí!—2008
  • Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2014
g 3/14 ojú ìwé 14-15

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Ọmọ Rẹ Obìnrin

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ọmọ rẹ obìnrin sọ pé gbogbo nǹkan tojú sú òun. Ó yà ẹ́ lẹ́nu láti gbọ́ bẹ́ẹ̀, lo bá bi ara rẹ pé, ‘Kí lọmọ ọdún mẹ́tàlá mọ̀ tó ń jẹ́ pé nǹkan tojú súni?’ ‘Kò tíì dàgbà tó ẹni tí nǹkan ń tojú sú!’ Kó tó di pé o sọ irú ọ̀rọ̀ yìí sí ọmọ rẹ, jẹ́ ká wo àwọn nǹkan bíi mélòó kan tó lè fayé sú àwọn ọmọbìnrin.

ÌDÍ TÓ FI MÁA Ń ṢẸLẸ̀

Àwọn àyípadà inú ara. Àwọn nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ọmọbìnrin bá bàlágà máa ń mú ìnira díẹ̀ lọ́wọ́. Ohun tó sì máa ń dá kún ìnira tàbí àìfararọ yìí ni pé tí ọmọbìnrin kan bá kíyè sí i pé àwọn ìyipadà kan ò tíì wáyé lára rẹ̀ bíi táwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tàbí tó jẹ́ pé ó tètè bàlágà ṣáájú àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Annaa tó ti pé ọmọ ogún ọdún báyìí sọ pé: “Láàárín àwọn ẹgbẹ́ mi, mo wà lára àwọn tó kọ́kọ́ wọ bùrèsíà, èyí kì í jẹ́ kí ara mi balẹ̀ rárá. Tí mo bá wà pẹ̀lú àwọn ojúgbà mi, ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò bẹ́gbẹ́ mu rárá!”

Ìmọ̀lára tó ń yí pa dà. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Karen, tó ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún báyìí sọ pé: “Ó máa ń tojú sú mi bí ìmọ̀lára mi ṣe máa ń yí pa dà bìrí. Inú mi á dùn lójú ọjọ́ àmọ́ nígbà tó bá fi máa di alẹ́ ńṣe ni màá kàn máa wa ẹkún mu bí omi. Ọ̀rọ̀ ara mi ò yé mi rárá. Mi ò sì mọ ohun tí mo lè ṣe sí i.”

Tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan oṣù. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kathleen sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi ti ṣàlàyé bí nǹkan ṣe máa rí fún mi tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ mi ò múra sílẹ̀ rárá nígbà tí mo kọ́kọ́ rí nǹkan oṣù mi. Àìmọye ìgbà ni mo máa ń wẹ̀ lójúmọ́, torí ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dọ̀tí gan-an. Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ò tiẹ̀ káàánú mi rárá, ńṣe ni wọ́n máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Níbi ti ara ti ń ni mí nítorí nǹkan oṣù tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rí, eré làwọn ka gbogbo ẹ̀ sí.”

Ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Marie tó ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] báyìí náà sọ ohun tó jọ èyí, ó ní: “Nígbà tí mo wà láàárín ọmọ ọdún méjìlá sí mẹ́rìnlá, kò rọrùn rárá fún mi láti sọ pé mi ò bá àwọn ojúgbà mi ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe. Bí ẹnì kan bá sọ pé òun ò bá àwọn ọmọléèwé mi ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe, ńṣe ni wọ́n máa ń fayé ni onítọ̀hún lára.” Anita ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sọ pé: “Fún àwọn tó wà ní ọjọ́ orí mi yìí, nǹkan pàtàkì ni pé kí èèyàn bẹ́gbẹ́ pé. Ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń báni táwọn ọ̀rẹ́ bá pani tì kì í ṣe kékeré.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ran ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ kó lè sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro rẹ̀. Ọmọ rẹ lè má kọ́kọ́ fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro rẹ̀. Torí náà, o gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù kó o sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì tó sọ pé “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—Jákọ́bù 1:19.

Má fojú kéré ohun tí ọmọ rẹ bá sọ fún ẹ. Rántí pé ọmọ rẹ ò nírìírí tó ẹ, kò ní irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ rí, kò sì mọ ohun tó lè ṣe sí i.—Ìlànà Bíbélì: Róòmù 15:1.

Má fi iṣẹ́ pá ọmọ rẹ lórí. Ìwé kan tó ń jẹ́ Teach Your Children Well, sọ pé àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fi iṣẹ́ pá lórí “sábà máa ń sọ pé nǹkan tojú sú àwọn, àárẹ̀ tó sì máa ń ṣe wọ́n jù ni ẹ̀fọ́rí àti inú rírun.”—Ìlànà Bíbélì: Fílípì 1:9, 10.

Rí i pé ọmọbìnrin rẹ ń sinmi dáadáa. Bí nǹkan bá ti tojú sú àwọn ọmọbìnrin, ó sábà máa ń gba oorun lójú wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, bí wọn ò bá sùn dáadáa, wọn ò ní lè ronú bó ṣe yẹ, nǹkan ò sì ní yéé tojú sú wọn.—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 4:6.

Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè máa ṣohun tó máa mú kí ara tù ú tí nǹkan bá fẹ́ tojú sú u. Táwọn ọmọbìnrin kan bá ṣe eré ìdárayá, ó máa ń dín ìdààmú ọkàn wọn kù. Bíbélì sọ pé, “Ènìyàn a máa rí àǹfààní . . . tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá.” (1 Tímótì 4:8, Ìròhìn Ayọ̀) Ohun tó máa ń ran àwọn ọmọbìnrin míì lọ́wọ́ láti kápá ìdààmú ọkàn wọn ni pé, wọ́n máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ní. Brittany, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì kéré, mo máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣòro tí mi ò tíì lè yanjú. Èyí máa ń jẹ́ kí n mọ bí ìṣòro kan ṣe rí lára mi, á sì wá rọrùn fún mi láti wá ojúùtú sí ìṣòro náà tàbí kí n gbé e kúrò lọ́kàn.”

Fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀. Báwo lo ṣe máa ń ṣe tí nǹkan bá tojú sú ẹ? Ṣé o kì í wa nǹkan tó pọ̀ jù máyà débi pé ọkàn rẹ ò ní balẹ̀ tó o bá ń ṣe é? Ṣé o kì í fara ṣiṣẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ, débi pé o kì í ráyè fún àwọn nǹkan tó ṣè pàtàkì jù nígbèésí ayé rẹ? Fílípì 4:5 sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” Má gbàgbé pé ọmọ rẹ ń wò ẹ́, àpẹẹrẹ rẹ ló sì máa tẹ̀ lé, ìbáà jẹ́ rere tàbí búburú.

a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

FI ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN

  • “Ó yẹ kí àwa tí a ní okun máa ru àìlera àwọn tí kò lókun.”—Róòmù 15:1.

  • “Ẹ . . . máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:9, 10.

  • “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 4:6.

ÒBÍ KAN TÓ FI ÀPẸẸRẸ ÀTÀTÀ LÉLẸ̀

Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Laura sọ pé: “Ọwọ́ dádì mi máa ń dí gan-an, àmọ́ wọn kì í jẹ́ kí ìṣòro mú wọn rẹ̀wẹ̀sì. Tí ìṣòro kan bá dé, wọ́n á kọ́kọ́ béèrè pé ‘Kí la máa ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí?’ tàbí ‘Ọ̀nà wo ló dára jù láti yanjú ọ̀rọ̀ yìí?’ Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ tí dádì mi gbádùn jù lọ láti máa sọ ni pé, ‘Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tá a bá ṣe nígbà tí ìṣòro bá dé ló máa pinnu bóyá ìṣòro ọ̀hún á mọ níwọ̀n tàbí á dohun tápá ò fẹ́ ká mọ́.’ Kì í ṣe pé dádì mi dára tán láìkù síbì kan o, nǹkan máa ń tojú sú wọn nígbà míì. Àmọ́ wọn kì í jẹ́ kí ìṣòro borí wọn. Àpẹẹrẹ wọn ni mo máa ń tẹ̀ lé tó bá ti fẹ́ dà bíi pé nǹkan tojú sú mi.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́