ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 5/14 ojú ìwé 6
  • Má Ṣe Jẹ́ Káyé Sú Ẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe Jẹ́ Káyé Sú Ẹ
  • Jí!—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Jí!—2001
  • Pípa Ara Ẹni—Ìṣòro Wíwọ́pọ̀ Láàárín Àwọn Ọ̀dọ́
    Jí!—1998
  • Ohun Tó Ń mú Káyé Sú Àwọn Èèyàn Kan
    Jí!—2001
  • Gbígbẹ̀mí Ara Ẹni—Ìṣòro Ńlá Tó Ń Yọ́ Kẹ́lẹ́ Ṣọṣẹ́
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—2014
g 5/14 ojú ìwé 6

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Má Ṣe Jẹ́ Káyé Sú Ẹ

TÓ O bá mọ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Diana,a wàá rí i pé ó jáfáfá, ó lọ́yàyà, ó sì kóni mọ́ra. Àmọ́ bí ọ̀dọ́bìnrin yìí ṣe dára tó yìí, ìbànújẹ́ tó ń bá a fínra kọjá àfẹnusọ. Tí nǹkan ọ̀hún bá dé sí i báyìí, ńṣe ló máa ń rí ara rẹ̀ bí ẹni tí kò wúlò fún nǹkan kan, ó sì lè máa ṣe é bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù. Ó sọ pé: “Ọjọ́ kan ò ní lọ kí n má ronú pé ó sàn kí n kú. Ó dá mi lójú pé bí mo tiẹ̀ wà láàyè, mi ò ṣe ẹnì kankan láǹfààní.”

“Àwọn ìwádìí kan fi hàn pé gbogbo ìgbà tá a bá rí èèyàn kan tó gbẹ̀mí ara ẹ̀, ọgọ́rùn-ún méjì míì ló ti gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn, nígbà tó jẹ́ pé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [mìíràn] ń ronú láti gbẹ̀mí ara wọn.”​—THE GAZETTE, MONTREAL, CANADA.

Diana sọ pé òun ò ní pa ara òun láé. Àmọ́, nígbà míì kò rí ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ kó ṣì wà láyé. Ó sọ pé: “Ohun tó máa ń wù mí jù lọ ni pé kí n kú sínú jàǹbá kan. Mo ti wá rí ikú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ mi, kì í ṣe ọ̀tá mi.”

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ wọn náà jọ ti Diana. Àwọn kan tiẹ̀ ti ronú láti gbẹ̀mí ara wọn, nígbà tó jẹ́ pé àwọn míì ti gbìyànjú ẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun táwọn ọ̀mọ̀ràn sọ ni pé, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ti gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn ló jẹ́ pé kì í kúkú ṣe pé ó wu àwọn náà láti kú, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ wọ́n. Ní kúkúrú, ayé ti sú wọn; àmọ́ wọ́n fẹ́ mọ ìdí tó fi yẹ káwọn ṣì wà láàyè.

Má ṣe jẹ́ káyé sú ẹ. Jẹ́ ká wo ìdí mẹ́ta tó fi yẹ kó o ṣì wà láàyè.

IRỌ́: Téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ nípa gbígbẹ̀mí ara ẹni tàbí téèyàn ń lo ọ̀rọ̀ náà, èyí á mú káwọn èèyàn fẹ́ láti gbìyànjú ẹ̀ wò.

ÒÓTỌ́: Téèyàn bá sọ̀rọ̀ nípa gbígbẹ̀mí ara ẹni, ó sábà máa ń mú kí ẹni tó ti ń ronú láti gbẹ̀mí ara rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pèrò dà.

a A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́