ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 3/15 ojú ìwé 8-9
  • Bí O Ṣe Lè Ṣàkóso Ìbínú Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí O Ṣe Lè Ṣàkóso Ìbínú Rẹ
  • Jí!—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Máa Bínú Sódì?
    Jí!—2009
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàkóso Ìbínú Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbínú?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Sùúrù
    Jí!—2019
Àwọn Míì
Jí!—2015
g 3/15 ojú ìwé 8-9

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́

Bí O Ṣe Lè Ṣàkóso Ìbínú Rẹ

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

“Mo ké mọ́ ẹ̀gbọ́n mi, mo sì fìbínú jáàmù ilẹ̀kùn débi pé àgádágodo tó wà lẹ́yìn rẹ̀ dápàá sára ògiri. Kò sígbà tí mo rí àpá yìí tí mi ò kì í rántí ìwà tí mo hù lọ́jọ́ yẹn.”—Diane.a

“Mo pariwo mọ́ bàbá mi pé, ‘Bàbá burúkú ni yín!’ mo sì fìbínú ju ilẹ̀kùn gbàgà. Àmọ́ kí ilẹ̀kùn náà tó tì, mo rí i lójú bàbá mi pé ọ̀rọ̀ yẹn dùn wọ́n wọra, nígbà tí ojú mi wálẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé kí n kó ọ̀rọ̀ mi jẹ, àmọ́ ẹyin lohùn.”—Lauren.

Ǹjẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lauren àti Diane ti ṣe ẹ́ rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ìbínú máa bà ẹ́ jẹ́ láwùjọ. Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] kan tó ń jẹ́ Briana sọ pé: “Mo máa ń rò pé àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ gbà mí bí mo ṣe rí. Àmọ́ mo kíyè sí i pé ẹni tí kò bá lè ṣàkóso ìbínú rẹ̀ máa ń dà bí ọ̀dẹ̀ lójú àwọn èèyàn. A jẹ́ pé bí mo ṣe rí lójú àwọn èèyàn nìyẹn!”

Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń yára bínú yóò hu ìwà òmùgọ̀.”—Òwe 14:17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Báwọn èèyàn ṣe máa sá tí iná bá sọ níbì kan, bẹ́ẹ̀ náà làwọn èèyàn ṣe máa ń yẹra fún oníbìínú èèyàn

Ìbínú lè mú káwọn èèyàn máa yẹra fún ẹ. Ọ̀dọ́kùnrin ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Daniel sọ pé: “Wàá tẹ́ lójú àwọn èèyàn tó o bá ń bínú lódìlódì.” Elaine tóun náà jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ pé: “Àwọn èèyàn kì í fẹ́ sún mọ́ ẹni tó bá ń tètè bínú.”

Bíbélì sọ pé: “Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́; má sì bá ènìyàn tí ó máa ń ní ìrufùfù ìhónú wọlé.”—Òwe 22:24.

O lè ṣàkóso ara rẹ. Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kan tó ń jẹ́ Sara sọ pé: “O kò lè pinnu bó ṣe yẹ káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ sí ẹ, àmọ́ o lè pinnu bó o ṣe máa fèsì. Kò dìgbà tó o bá gbaná jẹ káwọn èèyàn tó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ kan dùn ẹ́.”

Bíbélì sọ pé: ‘Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá, ẹni tí ó sì ń ṣàkóso ìbínú rẹ̀ sàn ju ẹni tí ó kó ìlú ńlá.’—Òwe 16:32.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ṣètò bó o ṣe máa ṣàtúnṣe. Kàkà kó o kàn gbà pé bí ìwà tìẹ ṣe rí nìyẹn, á dáa kó o sapá láti ṣàtúnṣe láàárín àkókò kan bóyá bí oṣù mẹ́fà. Láàárín àkókò náà, máa ṣàkọsílẹ̀ bó o ṣe ń tẹ̀síwájú. Ìgbàkugbà tó o bá ti bínú, ṣàkọsílẹ̀ (1) ohun tó ṣẹlẹ̀, (2) bó o ṣe fèsì àti (3) èsì tó dáa tó yẹ kó o fún ẹni náà àti ìdí tó o fi rò pé irú èsì yẹn dáa. Wá pinnu láti lo àbá yẹn nígbà míì tí ẹnì kan bá múnú bí ẹ. Ìmọ̀ràn kan rèé: Ṣàkọsílẹ̀ àwọn àṣeyọrí tó o bá ṣe àti bí inú rẹ ṣe dùn tó nígbà tó o kó ara rẹ níjàánu.—Ìlànà Bíbélì: Kólósè 3:8.

Ṣe sùúrù kó o tó fèsì. Tẹ́nì kan bá múnú bí ẹ, má ṣe sọ ohun tó bá kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe sùúrù, kó o sì mí kanlẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kan tó ń jẹ́ Erik sọ pé: “Tí mo bá mí kanlẹ̀, ó máa ń jẹ́ kí n ronú dáadáa kí n tó sọ ohun tí màá pa dà wá kábàámọ̀.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 21:23.

Ronú jinlẹ̀ dáadáa. Àwọn ìgbà míì wà tó o máa bínú torí pé ibi tó kọjú sí ẹ nínú ọ̀rọ̀ kan lo rí. Àmọ́, sapá láti ronú lórí bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára ẹlòmíì. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jessica sọ pé: “Táwọn èèyàn bá tiẹ̀ hùwà tó bí mi nínú, mo mọ̀ pé nǹkan kan ló mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí máa jẹ́ kí n lè fòye bá wọn lò.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 19:11.

Kúrò níbi tí wàhálà ti bá fẹ́ ṣẹlẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 17:14) Ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ ni pé tó o bá ti rí i pé wàhálà fẹ́ ṣẹlẹ̀ níbì kan, á dáa kó o tètè kúrò níbẹ̀. Kàkà kó o máa ronú lórí ọ̀rọ̀ tó ń bí ẹ nínú, gbọ́kàn kúrò lórí ẹ̀ kó o sì wá nǹkan míì ṣe. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Danielle sọ pé: “Tí mo bá ń ṣeré ìmárale, ara máa ń tù mí, èyí sì máa ń jẹ́ kí n gbé ìbínú kúrò lọ́kàn.”

Fọwọ́ wọ́nú. Bíbélì sọ pé: “Kí inú yín ru, ṣùgbọ́n ẹ má ṣẹ̀. Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ ní ọkàn-àyà yín, . . . kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.” (Sáàmù 4:4) Kò sẹ́ni tí kì í bínú, àmọ́ téèyàn bá fàyè gbà á jù, kí ló lè ṣẹlẹ̀? Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Richard sọ pé: “Tó o bá ń jẹ́ kí ẹlòmíì múnú bí ẹ, ńṣe lò ń jẹ́ kẹ́ni náà máa darí ẹ. Torí náà, á dáa kó o fọwọ́ wọ́nú, kó o sì fi hàn pé o dàgbà dénú.” Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè ṣàkóso ìbínú rẹ kàkà tí ìbínú náà á fi mú kó o ṣìwà hù.

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

FI ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN

  • “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú.”—Kólósè 3:8.

  • “Ẹni tí ń pa ẹnu rẹ̀ àti ahọ́n rẹ̀ mọ́ ń pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú àwọn wàhálà.”—Òwe 21:23.

  • “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.”—Òwe 19:11.

DANIEL

“Máa jẹ oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀, kó o sì máa mumi dáadáa. Mo ti rí i pé tí mi ò bá jẹun dáadáa, ara máa ń kan mí.”

NATALIE

“Tó o bá kọ́ bó o ṣe lè ṣàkóso ìbínú rẹ, a jẹ́ pé o ti kúrò lọ́mọdé nìyẹn. Àwọn ọmọdé ló máa ń bára wọn fa ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan, àmọ́ àwọn àgbà máa ń fẹ̀sọ̀ yanjú ìṣòro ni.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́