OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Mèsáyà
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà máa wá sáyé láti wá dá àwọn èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àìsàn, ìyà àti ikú. Ṣé Jésù Kristi ni Mèsáyà náà?
Báwo ni àwọn èèyàn ṣe máa dá Mèsáyà náà mọ̀?
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Mèsáyà náà máa gbà wá. Àkókò tó máa kọ́kọ́ fara hàn sì máa jìnnà sí ìkejì.a Èèyàn ni Mèsáyà náà máa jẹ́ nígbà tó bá kọ́kọ́ wá. Kí àwọn èèyàn lè dá a mọ̀ tó bá dé, àwọn tó kọ Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìgbésí ayé rẹ̀ àti nípa iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀. Kódà, “Jíjẹ́rìí Jésù” ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì dá lé.—Ìṣípayá 19:10.
Àwọn nǹkan tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé jẹ́ ìtọ́wò lásán lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó máa ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì sọ nípa Mèsáyà náà pé . . .
Ó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba.—Aísáyà 9:7; Lúùkù 3:23-31.b
Ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí i sí.—Míkà 5:2; Lúùkù 2:4-7.
Ó máa polongo “ìhìn rere.”—Aísáyà 61:1; Lúùkù 4:43.
Ó máa di ẹni ìtẹ́ńbẹ́lú àti aláìjámọ́ nǹkan kan lójú àwọn èèyàn.—Aísáyà 53:3; Mátíù 26:67, 68.
Wọ́n máa dalẹ̀ rẹ̀ nítorí ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà.—Sekaráyà 11:12, 13; Mátíù 26:14, 15.
Kò ní fọhùn rárá bí àwọn alátakò rẹ̀ ṣe fẹ̀sùn èké kàn án, tí wọ́n sì dájọ́ ikú fún un.—Aísáyà 53:6, 7; Mátíù 27:12-14.
Ó máa fi ara rẹ̀ rúbọ bí “ọ̀dọ́ àgùntàn,” kó lè pa ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́, kí a lè láǹfààní láti sún mọ́ Ọlọ́run.—Aísáyà 53:7; Jòhánù 1:29, 34, 36.
Wọn kò ṣẹ́ egungun rẹ̀ kankan nígbà tí wọ́n pa á.—Sáàmù 34:20; Jòhánù 19:33, 36.
Wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn olówó.—Aísáyà 53:9; Mátíù 27:57-60.
Ó jíǹde ní ọjọ́ kẹta.—Mátíù 16:21; 28:5-7.
Gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí àtàwọn míì tó wà nínú Bíbélì ló ṣẹ sí Jésù lára. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù tún jí òkú dìde, ó sì wo àwọn aláìsàn sàn. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé lóòótọ́ Jésù ni Mèsáyà náà. Bákan náà, àwọn nǹkan wọ̀nyí tún jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ohun tí Jésù máa ṣe lọ́jọ́ iwájú máa ṣẹ. (Lúùkù 7:21-23; Ìṣípayá 21:3, 4) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó jókòó sí “ọwọ́ ọ̀tún” Ọlọ́run, ó ń dúró de ìgbà tó máa parí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà.—Sáàmù 110:1-6.
“Nígbà tí Kristi bá dé, kì yóò ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ju èyí tí ọkùnrin yìí ti ṣe, àbí yóò ṣe bẹ́ẹ̀?”—Jòhánù 7:31.
Báwo ni Mèsáyà ṣe máa parí iṣẹ́ rẹ̀?
Àwọn Júù nígbà ayé Jésù rò pé ńṣe ni Mèsáyà náà máa gba àwọn lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù, á sì dá ìjọba pa dà fún Ísírẹ́lì. (Ìṣe 1:6) Ó ṣe díẹ̀ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pàápàá tó lóye pé ọ̀run ni Jésù ti máa parí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i Mèsáyà nígbà tó bá pa da di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára tó ń ṣàkóso látọ̀run.—Mátíù 28:18.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Nígbà tí Mèsáyà bá fara hàn lẹ́ẹ̀kejì . . .
Ó máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba nínú Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba kan tó máa kárí ayé.—Dáníẹ́lì 7:13, 14; Ìṣípayá 11:15.
Ó máa mú ìbùkún wá fún gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18; Sáàmù 72:7, 8.
Ó máa mú àwọn alákòóso àti “ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ta gìrì” nígbà tó bá pa wọ́n run torí pé wọ́n ta kò ó.—Aísáyà 52:15; Ìṣípayá 19:19, 20.
Ó máa ṣamọ̀nà “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn olódodo kárí ayé sí inú ayé tuntun tí àlàáfíà ti máa jọba.—Ìṣípayá 7:9, 10, 13-17.
Òun àti Jèhófà Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Lúùkù 23:43; Jòhánù 5:21, 28, 29.
Ó máa kọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀nà àlàáfíà.—Aísáyà 11:1, 2, 9, 10.
Ó máa mú ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa àìsàn àti ikú kúrò.—Jòhánù 1:29; Róòmù 5:12.
Ó máa fọ́ gbogbo iṣẹ́ Èṣù túútúú, á sì mú kí gbogbo èèyàn wà ní ìṣọ̀kan lábẹ́ ìṣàkóso Jèhófà Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 15:25-28; 1 Jòhánù 3:8.
Jésù parí iṣẹ́ tó kọ́kọ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí i Mèsáyà, ó sì máa parí ìkejì náà. Torí náà, àwọn tó bá gbọ́n gbọ́dọ̀ máa fiyè sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ torí òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.”—Jòhánù 14:6.
“Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́. Òun yóò sì ní àwọn ọmọ abẹ́ . . . dé òpin ilẹ̀ ayé.” —Sáàmù 72:7, 8.
a Ọ̀rọ̀ náà “Mèsáyà” wá látinú èdè Hébérù. Ìtumọ̀ kan náà ló ní pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà “Kristi” tó wá látinú èdè Gíríìkì.—Jòhánù 1:41.
b Àsọtẹ́lẹ̀ náà wà nínú ẹsẹ Bíbélì àkọ́kọ́, ìmúṣẹ rẹ̀ sì wà nínú ẹsẹ Bíbélì kejì.