ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 5/15 ojú ìwé 7
  • Ohun tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nílẹ̀ Áfíríkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nílẹ̀ Áfíríkà
  • Jí!—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Ń Pa Ẹranko Ráínò (RHINO) Láìgbàṣẹ
  • Àwọn Èèyàn Kì í Fẹjọ́ Sùn Tí Wọ́n Bá Gba Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ Lọ́wọ́ Wọn
  • Àwọn Tó Ń Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì Nílẹ̀ Áfíríkà
  • Àwọn Ọmọ Rhino Tí Kò Lóbìí ní Kẹ́ńyà
    Jí!—1998
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Fífi Idà Ẹ̀mí Gbógun Ti Ìwà Ìbàjẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Èé Ṣe Tí Ìwà Ìbàjẹ́ Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Jí!—2015
g 5/15 ojú ìwé 7

OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ | ÁFÍRÍKÀ

Ohun tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nílẹ̀ Áfíríkà

Onírúurú àjọ àti àwọn èèyàn ń sapá láti mú kí ayé dẹrùn fún àwọn olùgbé ilẹ̀ Áfíríkà. Síbẹ̀, àgbègbè yìí ṣì ní àwọn ìṣòrò tó le gan-an.

Wọ́n Ń Pa Ẹranko Ráínò (RHINO) Láìgbàṣẹ

Lọ́dún 2013, wọ́n pa ẹranko kan tí wọ́n ń pè ní ráínò tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan àti mẹ́rin [1,004] ní orílẹ̀-èdè South Africa láìgbàṣẹ. Bẹ́ẹ̀, mẹ́tàlá péré ni wọ́n pa lára àwọn ẹranko yìí lọdún 2007. Pẹ̀lú bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń ta ìwo ẹranko yìí tó, àwọn èèyàn ò yéé béèrè fún un, ó le débi pé iye tí wọ́n ń ta kìlógíráàmù kan lára ìwo rẹ̀ ju iye tí wọ́n ń ta kìlógíráàmù góòlù kan lọ. Wọ́n lè rí ìdajì mílíọ̀nù dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, (ìyẹn nǹkan bíi 83,750,000 náírà) látara ẹyọ ìwo kan péré.

RONÚ LÓRÍ ÈYÍ: Ǹjẹ́ ìjọba lè fòpin sí ìwà ìrúfin?—Jeremáyà 10:23.

Àwọn Èèyàn Kì í Fẹjọ́ Sùn Tí Wọ́n Bá Gba Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ Lọ́wọ́ Wọn

Àjọ kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ kíkó owó jẹ lágbàáyé, ìyẹn àjọ Transparency International, sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà ni wọ́n ti ń gbà àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jù lọ láyé. Síbẹ̀, nǹkan bí ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn tí wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ wọn ni kì í fẹjọ́ sùn. Agbẹnusọ fún àjọ yìí lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà sọ pé: “Ó jọ pé àwọn aráàlú kò fọkàn tán ìjọba pé wọ́n máa ṣe nǹkan kan sí i tí àwọn bá fẹjọ́ sùn pé àwọn kan ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ojú àwọn tí ó ríran kedere.”—Ẹ́kísódù 23:8.

Àwọn Tó Ń Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì Nílẹ̀ Áfíríkà

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìkàn-síra-ẹni lágbàáyé, ìyẹn àjọ International Telecommunication Union, fojú bù ú pé tó bá fi máa di ìparí ọdún 2014, nǹkan bí ìdá ogún lára àwọn èèyàn tó ń gbé nílẹ̀ Áfíríkà á ti máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Iye àwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lórí ẹ̀rọ alágbèéká nílẹ̀ Áfíríkà ń yára pọ̀ sí í ní ìlọ́po méjì ju iye àwọn tó ń lò ó kárí ayé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́