Àwọn Ọmọ Rhino Tí Kò Lóbìí ní Kẹ́ńyà
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KẸ́ŃYÀ
KÍ LÓ máa ń ṣẹlẹ̀ nínú igbó nígbà tí ọmọ ẹranko kan bá kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀? Ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹranko apẹranjẹ pa á. Kí ìyẹn má bàa ṣẹlẹ̀, àwọn aṣọ́gbó máa ń dáàbò bo irú àwọn ọmọ ẹranko bẹ́ẹ̀ ní Kẹ́ńyà, wọn óò sì mú wọn lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ ẹranko aláìlóbìí. Daphne Sheldrick ló ni ọ̀kan lára irú àwọn ilé ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ tí a mọ̀ dáradára ní Ọgbà Ẹranko ti Orílẹ̀-Èdè ní Nairobi. Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, Sheldrick ti tọ́jú ọ̀pọ̀ ẹranko títí kan ẹfọ̀n, ẹtu, ológbò civet, ìmàdò, mongoose, erin, àti ẹranko rhino, ó sì dá wọn padà sínú igbó.
Ní ọdún tó kọjá, àwọn ọmọ rhino dúdú méjì, Magnette àti Magnum, wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó ń tọ́jú. Ọmọ Edith, tí ó ṣì wà láàyè ní Ọgbà Ẹranko ní Nairobi, ni Magnette. Wọ́n gbé ọmọ náà wá sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ ẹranko aláìlóbìí láàárín oṣù February ní ọdún 1997, lẹ́yìn tí ó ti kúrò lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀. Ọjọ́ márùn-ún ti pé kí àwọn aṣọ́gbó tó wá rí ìyá Magnette. Nígbà yẹn, kò dájú pé ìyá náà lè gba ọmọ náà padà nítorí pé ó ti pẹ́ tí ó ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ àti nítorí òórùn ènìyàn tí yóò máa gbọ́ lára rẹ̀.
January 30, 1997, ni wọ́n bí Magnum, ó sì jẹ́ ọmọ ẹranko rhino tí ń jẹ́ Scud, tí ẹsẹ̀ iwájú rẹ̀ ti dá, bóyá ó já lu ihò nígbà tí ó wà lórí eré. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti sapá gan-an láti wo ẹsẹ̀ Scud sàn, àrùn wọnú egungun rẹ̀, wọ́n sì fi ojú àánú pa á ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn tí ó bí Magnum.
Títọ́jú Ẹranko Rhino
Àwọn ọmọ rhino kì í ṣe wàhálà, wọ́n sì rọrùn láti tọ́jú, àmọ́ a kò lè tọ́ wọn nínú ilé. Lójúmọmọ, wákàtí mẹ́rin-mẹ́rin ni wọ́n máa ń fi ìgò oúnjẹ ọmọdé ńlá mu mílíìkì, wọ́n sì máa ń parí odindi agolo ògidì mílíìkì kan lẹ́ẹ̀kan. Wọ́n tún máa ń jẹ igi àti ewé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ rhino kì í ga ju nǹkan bí 40 sẹ̀ǹtímítà péré lọ, wọ́n kì í sì í tóbi ju 30 kìlógíráàmù sí 40 kìlógíráàmù lọ bí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí wọn, wọ́n máa ń yára tóbi—wọ́n máa ń tóbi ní ìwọ̀n kìlógíráàmù kan lójúmọ́! Bí ẹranko rhino bá dàgbà tán, ó máa ń tóbi ju tọ́ọ̀nù kan lọ.
Àwọn tí ń tọ́jú wọn máa ń wà pẹ̀lú Magnette àti Magnum bí wọ́n bá ń rin ọ̀nà jíjìn nínú ọgbà ẹranko náà lójoojúmọ́. Kì í ṣe nítorí àtiṣeré ìmárale lásán ni wọ́n ṣe ń rin ìrìn náà; nítorí ète pàtàkì kan ni—láti mú kí àwọn ẹranko rhino náà lè gbé inú igbó. Ẹ jẹ́ kí a gbé bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí yẹ̀ wò.
Ojú àwọn ẹranko rhino kì í ríran dáradára, àmọ́ wọ́n ní agbára ìgbóòórùn tí ó mú hánhán àti agbára ìrántí tí ó pegedé. Nítorí náà, òórùn ara ni àwọn ẹranko rhino kọ́kọ́ fi ń mọ ara wọn. Àwọn ẹranko rhino máa ń ya ìgbẹ́ jọ, wọ́n sì máa ń fọ́n ìtọ̀ sí ara ewéko láti pààlà sí ibùgbé wọn.
Bí nǹkan bá rọgbọ, ìyá máa ń dáàbò bo ọmọ rẹ̀, ipa olóòórùn aláìlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ń pa pọ̀ mọ́ ti ìyá rẹ̀ títí yóò fi bí ọmọ mìíràn. Nígbà yẹn, ara ọmọ náà yóò ti bá àwùjọ àwọn ẹranko rhino náà mu, wọn óò sì tẹ́wọ́ gbà á. Ọ̀ràn náà yàtọ̀ nínú ọ̀ràn ti àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé bí Magnette àti Magnum. Wọ́n gbọ́dọ̀ ya ìgbẹ́ tiwọn mọ́ ti ẹranko rhino tí ń gbé àgbègbè náà kí wọ́n tó fojú kàn wọ́n. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá ń rin ọ̀nà jíjìn náà lójoojúmọ́, àwọn ọmọ rhino aláìlóbìí náà máa ń ya ìgbẹ́ ti wọn kún èyí tí ó ti wà nínú igbó náà tẹ́lẹ̀. Lọ́nà yìí, àwọn ẹranko rhino tí wọ́n wà ní àgbègbè náà yóò gbọ́ òórùn wọn, wọn óò ṣàyẹ̀wò nípa rẹ̀, wọn óò wá tẹ́wọ́ gbà wọ́n níkẹyìn. Gbígbé àwọn ẹranko rhino tí ènìyàn tọ́jú padà sínú igbó ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó ṣòro, tí ó sì lè gba ọ̀pọ̀ ọdún.
Kí Ló Wà Lọ́jọ́ Iwájú fún Àwọn Ẹranko Aláìlóbìí Náà?
Bí Àjọ Akówójọ fún Ìdáàbòbò Ohun Alààyè Inú Igbó Lágbàáyé ti sọ, nǹkan bí 65,000 ẹranko rhino dúdú ló wà ní Áfíríkà ní ọdún 1970. Iye tó wà lónìí kò tó 2,500. Àwọn apẹran-láìgbàṣẹ tí wọ́n ń pa àwọn ẹranko rhino náà nítorí awọ àti ìwo wọn ló mú kí iye wọn dín kù tó bẹ́ẹ̀. Ní ọjà fàyàwọ́, ìwo ẹranko rhino níye lórí ju iye góòlù tí ó tẹ̀wọ̀n tó o lọ. Èé ṣe tí ó fi jọ àwọn ènìyàn lójú tó bẹ́ẹ̀?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Ìlà-Oòrùn Jíjìnnà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé ìwo tí wọ́n lọ̀ di lẹ́bú lè dẹwọ́ àrùn ibà. Àyẹ̀wò oníkẹ́míkà tí fi hàn pé èyí lè jẹ́ òtítọ́, àmọ́, kìkì tí ìwọ̀n tí a lò bá pọ̀ ju èyí tí a ń rí nínú àwọn egbòogi ìwòyí lọ ni. Lótìítọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ egbòogi mìíràn ló wà tí ń dẹwọ́ àrùn ibà.
Àwọn ènìyàn tún máa ń wá ìwo ẹranko rhino nítorí àwọn àṣà tí ó wọ́pọ̀ ládùúgbò. Ní orílẹ̀-èdè kan ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, ohun kan tí àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí ni ọ̀bẹ aláṣóró títẹ̀ kọdọrọ tí ó jẹ́ àmì jíjẹ́ ọkùnrin. Ọ̀bẹ aláṣóró tí wọ́n fi ìwo ẹranko rhino ṣe èèkù rẹ̀ jọ wọ́n lójú gan-an tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ń rà á múra tán láti ra èèkù tí wọ́n fi ìwo tuntun ṣe ní 580 dọ́là, wọ́n sì múra tán láti ra èèkù tí wọ́n fi ìwo àtọdúnmọ́dún kan ṣe ní 1,200 dọ́là.
Nítorí ìpẹran-láìgbàṣẹ, Kẹ́ńyà ti pàdánù ẹranko rhino tí ó lé ní ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún láàárín àkókò tí kò tó 20 ọdún. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, iye náà ti lọ sílẹ̀ sí 400 láti 20,000. Nítorí ìgbésẹ̀ ìdáàbòbò fífẹsẹ̀múlẹ̀ tí wọ́n ń gbé láti ìgbà náà wá, àwọn ẹranko rhino ti pọ̀ tó 450. Kẹ́ńyà ti di ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ta péré, tí iye ẹranko rhino dúdú kò dín kù tàbí tí ó ti ń pọ̀ sí i, ní Áfíríkà. Nítorí náà, ó jọ pé ọjọ́ iwájú yóò ṣẹnure fún Magnette àti Magnum, àwọn tí ń tọ́jú wọn sì nírètí pé tó bá yá, wọn óò lọ bá àwọn ẹranko rhino tí wọ́n wà ní àgbègbè náà, wọn óò sì pẹ́ láyé pẹ̀lú inú dídùn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Magnum (lápá òsì), àti Magnette ní ọmọ oṣù mẹ́rin