ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 8/8 ojú ìwé 20-21
  • Àwọn Ohun Iyebíye Ojú Òfuurufú Áfíríkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ohun Iyebíye Ojú Òfuurufú Áfíríkà
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Dígí Aláwọ̀-Bíbì
  • Ó Jẹ́ Aláápọn àmọ́ Kò Dán Gbinrin
  • Gbígbé Ìtẹ́ Kọ́
  • “Ẹyẹ Tó Lẹ́wà Jù Lọ Tó Ń Gbé Inú Igbó”
    Jí!—2000
Jí!—1998
g98 8/8 ojú ìwé 20-21

Àwọn Ohun Iyebíye Ojú Òfuurufú Áfíríkà

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Kẹ́ńyà

Ọ̀DÀN ilẹ̀ Áfíríkà gbẹ, ó sì láwọ̀ ilẹ̀, ọwọ́ oòrùn mímúhánhán tí ń wá láti ibi ìlà agbedeméjì òbìrí ayé ń bà á dáradára. A la àárín ọwọ́ pípẹ̀ka àwọn igi wait-a-bit àti igi ẹlẹ́gùn-ún kéékèèké kọjá.

Lójijì, a kò lè lọ mọ́ rárá. Àwọ̀ bíbì kan tí a kófìrí ti gba àfiyèsí wa. Ẹyẹ kékeré kan, tí ó ní àwọ̀ mèremère gan-an, tí ó fi jọ pé oòrùn wà lábẹ́ àwọn ìyẹ́ rẹ̀ tíntìntín, wá sinmi lórí ẹ̀ka igi kaṣíà kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń tanná. Ohun iyebíye abìyẹ́ yìí ni wọ́n ń pè ní ẹyẹ àrọ̀nì.

Àwọn Dígí Aláwọ̀-Bíbì

Ó lé ní ọgọ́rùn-ún oríṣi ẹyẹ àrọ̀nì tó wà. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn wà ní apá ilẹ̀ olóoru Áfíríkà, àmọ́ a tún lè rí wọn ní Éṣíà, Australia, àti àwọn erékùṣù Pacific pàápàá. Bí àwọn ẹyẹ àrọ̀nì ṣe lẹ́wà lónírúurú ni oòrùn máa ń tàn lára wọn bí dígí aláwọ̀-bíbì, tí ó ń yọ òṣùmàrè tí ó ní àwọn àwọ̀ títànyòò: àwọ̀ pupa bíbì, àwọ̀ ìyeyè, àwọ̀ búlúù, àwọ̀ ewé àti àwọ̀ bàbà bíbì.

A sábà máa ń fi àwọn ẹyẹ àrọ̀nì wé àwọn ẹyẹ akùnyùnmù ti Amẹ́ríkà. Bí àwọn ẹyẹ akùnyùnmù, wọ́n ní àwọ̀ púpọ̀, wọ́n sì máa ń fa omiídùn òdòdó mu. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n tóbi ju àwọn ẹyẹ akùnyùnmù lọ, wọn kò sì mọ̀ ọ́n fò tó àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn láti Àríwá Amẹ́ríkà náà.

Lápapọ̀, ẹyẹ àrọ̀nì máa ń fa omiídùn òdòdó mu nípa dídúró lé orí yẹtuyẹtu òdòdó gangan, yóò sì ki àgógó rẹ̀ gígùn, tí ó tẹ̀ kọrọdọ bọ inú yẹtuyẹtu òdòdó náà lọ́hùn-ún. Àmọ́ bí òdòdó kan tí ó ní ìrísí roboto kan bá gùn jù, tí ẹnu rẹ̀ kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀, ẹyẹ àrọ̀nì lè lu ìdí òdòdó náà, kí ó sì fa omiídùn tí ó wà nínú rẹ̀. Wọ́n máa ń jẹ kòkòrò tí wọ́n bá gbé lára òdòdó àti ewé tí ó wà láyìíká rẹ̀ pẹ̀lú.

Àwọn akọ jẹ́ akọrin tí ó jáfáfá. Wọ́n ní òye kíkọ orin oríṣiríṣi láti orí dídún tssp ti ẹyẹ àrọ̀nì aláwọ̀-bíbì rírẹwà dé dídún tsik-tsik-tsik-tsik-tsit tree-tree-turrrr tí ń dùn mọ́ni ti ẹyẹ àrọ̀nì aláwọ̀ èse àlùkò mọ́ àwọ̀ ewé bíbì láti Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìró wọn ló máa ń fi hàn pé wọ́n wà nínú igbó dídí. Bí ó ti wù kí ó rí, gbàrà tí a bá ti rí wọn, wọn kì í ṣòro ṣàkíyèsí ní ọ̀nà jíjìn tí ó gbẹ, tí ó ní àwọ̀ ilẹ̀ nínú pápá Áfíríkà.

Ó Jẹ́ Aláápọn àmọ́ Kò Dán Gbinrin

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé akọ ẹyẹ àrọ̀nì jojú ní gbèsè, ìró rẹ̀ sì gbádùn mọ́ni, abo rẹ̀ kéré jù ú lọ, kò sì ní àwọ̀ títàn. Èyí ló fà á tí àwọn olùwo-ẹyẹ àti àwọn ayàwòrán kì í fi í sábà ṣú já a. Ní gidi, ìgbà tí ó bá wà pẹ̀lú akọ ni a sábà máa ń ṣàkíyèsí rẹ̀. Àmọ́, bí abo kò tilẹ̀ ní àwọ̀, ó jẹ́ aláápọn.

Abo ni ó sábà máa ń kọ́ ìtẹ́, tí ó sì máa ń ṣe èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ títọ́ ọmọ. Bí abo ti ń ṣiṣẹ́ ìtẹ́ kíkọ́ lọ́wọ́, akọ yóò máa wò yíká, yóò múra tán láti lé àwọn ayọjúràn kúrò ní ibi tí wọ́n ń kọ́ ìtẹ́ náà sí.

Gbígbé Ìtẹ́ Kọ́

Ìtẹ́ ẹyẹ àrọ̀nì kò jojú ní gbèsè. Wọ́n wulẹ̀ máa ń rí bí pàǹtírí tí ẹ̀fúùfù gbá jọ tí ó sì jù lu ẹ̀ka igi kaṣíà kan. Fọ́nrán igi tí wọ́n hun, tí wọ́n wá fi okùn aláǹtakùn so ni àwọn ẹyẹ àrọ̀nì fi ṣe ìtẹ́ tí ó jọ ìbọ̀sẹ̀ sísorọ̀, tí ó nírìísí yìnyín. Wọ́n fìṣọ́ra lo àwọn èèhù ẹ̀ka tín-tìn-tín, ewé gbígbẹ, ègé èèhọ̀n, àti lọ́pọ̀ ìgbà, èèpo hóró èso kan tàbí méjì tí ó so rọ̀ láfikún sí gbogbo èyí tí a kà sílẹ̀ yìí láti ṣe ìta ìtẹ́ náà lọ́ṣọ̀ọ́.

Ìhùhù kíkúnná inú igi, ewéko fúlọ́fúlọ́, ìyẹ́, àti àwọn èlò tó rọ̀ lọ́wọ́ mìíràn ni wọ́n fi tẹ́ inú ìtẹ́ náà. Ihò kékeré tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, lápá òkè, ni wọ́n ń bá wọnú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni abo máa ń dá sàba. Bí ó bá jókòó nínú ìtẹ́ rẹ̀ tí ó nírìísí píà, a sábà máa ń rí àgógó rẹ̀ gígùn, tí ó tẹ̀ kọrọdọ tí ó yọ síta láti ojú ihò ìtẹ́ náà. Ẹyin méjì tàbí mẹ́ta ló máa ń yé, yóò sì pa á láàárín nǹkan bí ọjọ́ 14. Bí àwọn ọmọ bá fò kúrò nínú ìtẹ́, wọ́n sábà máa ń ní àwọ̀ tí kò jójú ní gbèsè bí ti ìyá wọn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí àwọn akọ ṣe ń dàgbà sí i, wọ́n máa ń ní àwọn ìyẹ́ rírẹwà tí yóò fi wọ́n hàn bí ẹyẹ aláwọ̀ mèremère, tí ó tàn.

Ẹyẹ àrọ̀nì tún jẹ́ àpẹẹrẹ ìpèsè yanturu àti onírúurú láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá onílàákàyè kan. Ẹwà àwọ̀ wọn àti ìhùwà àdánidá wọn mú wa ní ìmọrírì ńláǹlà fún Ẹlẹ́dàá wọn. Àwọn ẹyẹ àrọ̀nì wá tipa bẹ́ẹ̀ wà lára àwọn tí Bíbélì pàṣẹ fún pé: “Ẹ yin Jèhófà láti ilẹ̀ ayé, . . . ẹyin ohun tí ń rákò àti ẹ̀yin ẹyẹ abìyẹ́lápá.” “Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà.” (Sáàmù 148:7, 10; 150:6) Ó yẹ kí àwọn ohun iyebíye ojú òfuurufú Áfíríkà wọ̀nyí sún wa láti yin Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ tí ó ṣẹ̀dá wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́