“Ẹyẹ Tó Lẹ́wà Jù Lọ Tó Ń Gbé Inú Igbó”
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SWEDEN
ỌJỌ́ kan ní oṣù June ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mó máa rí “ẹyẹ tó lẹ́wà jù lọ tó ń gbé inú igbó,” bí àwọn kan ṣe ń pè é níbí. Ẹyẹ òwìwí ńlá aláwọ̀ eérú ni, tàbí ẹyẹ òwìwí Lapland bí wọ́n ṣe máa ń pè é nígbà mìíràn.
Ẹyẹ òwìwí ńlá tó lẹ́wà yìí ń gbé ní àwọn ibì kan ní Finland àti àríwá Sweden, bẹ́ẹ̀ sì ló ń gbé ní apá ìlà oòrùn jíjìnnà réré ní Siberia, Alaska, àti Kánádà. Ó máa ń fara pa mọ́, ó sì máa ń ṣòro láti rí i bí o kò bá mọ ibi tí ìtẹ́ rẹ̀ wà. Bí o bá lè mọ ibi tí ìtẹ́ rẹ̀ wà, wàá tún rí i pé ẹyẹ òwìwí kì í bẹ̀rù rárá.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọdẹ Yìí
Ó ṣeé ṣe fún mi láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa akọ ẹyẹ òwìwí Lapland tó lámì ṣíṣe kedere lára nígbà tó ń wá oúnjẹ kiri. Yóò ṣàdédé fò láti orí ẹ̀ka igi kan, yóò sì gbìyànjú láti gbé eku tí ó bá rí. Ǹjẹ́ ó rí i gbé? Bẹ́ẹ̀ ni o! Mo rí eku kékeré kan tó ń fì dirodiro láàárín àwọn èékánná rẹ̀ bó ṣe rọra ń fò lọ sókè rẹ̀mùrẹmu bó ti ń lo àwọn apá rẹ̀ tó fẹ̀ tó ogóje sẹ̀ǹtímítà láti ìkángun apá kan dé ìkejì.
Òwìwí Lapland kì í pamọ déédéé lọ́dọọdún bí ọ̀pọ̀ òwìwí mìíràn ti máa ń ṣe. Níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé àwọn eku kéékèèké nìkan ni ẹyẹ òwìwí ńlá yìí máa ń jẹ, láàárín àwọn ọdún mélòó kan tí irú oúnjẹ yìí kò bá fi bẹ́ẹ̀ sí, ẹyẹ yìí kò ní pamọ rárá. Ní àwọn ọdún mìíràn, nígbà tí oúnjẹ bá pọ̀ dáadáa, ó lè tó ọmọ mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó máa wà nínú ìtẹ́ kọ̀ọ̀kan.
Yíyan Akọ
Ìgbà ìrúwé ni òwìwí máa ń gùn, ṣe ni abo sì máa ń fara balẹ̀ yan akọ tí ó bá fẹ́, ṣùgbọ́n o, kì í ṣe bí akọ yẹn bá ṣe lẹ́wà tó ní ti gidi ló máa ń pinnu èyí tí yóò yàn, bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ obìnrin kì í wo ẹwà ní pàtàkì láti fẹ́ ọkọ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan tó máa ń kíyè sí ẹyẹ ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, akọ yẹn gbọ́dọ̀ fi hàn pé ògbójú ọdẹ lòun. Kí wọ́n tó wéwèé rárá pé kí àwọn mú ìdílé tàwọn jáde, ó gbọ́dọ̀ pèsè oúnjẹ fún abo yẹn.
Bí eku bá pọ̀ dáadáa, tí akọ yẹn sì jẹ́ “olùpèsè” tó jáfáfá, oúnjẹ tó bá pèsè yóò jẹ́ kí abo yẹn tóbi sí i. Bí abo yìí ṣe tóbi sí i yóò ṣiṣẹ́ nínú ara rẹ̀, yóò sì pinnu iye ẹyin tó máa yé.
Akọ yẹn nìkan ni yóò máa wá ṣọdẹ kiri, ìyẹn sì ń gba agbára gidigidi. Igbe ẹ̀bẹ̀ kíkankíkan tí èyí abo ń ké ni yóò máa fún akọ lágbára níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo agbára abo náà ni yóò máa fi yé ẹyin, tí yóò sì máa fi sàba lé e.
Ṣíṣàwárí Ìtẹ́ Wọn
Mo fi awò mi wo akọ ẹyẹ tó lẹ́wà yìí bó ṣe ń fò lọ, fò bọ̀ lókè bí ó ti ń gbé oúnjẹ lọ. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo rí ìtẹ́ rẹ̀. Àwọn ẹyẹ òwìwí Lapland kì í kọ́ ìtẹ́ tiwọn ṣùgbọ́n ṣe ni wọ́n sábà máa ń gba àwọn ìtẹ́ onígi lọ́wọ́ àwọn ẹyẹ ọdẹ mìíràn tí ń gbé inú igbó. Bí kò bá sí ìtẹ́ kankan, ẹyẹ òwìwí lè lo kùkùté igi tó ti kú.
Nínú ìtẹ́ náà, mo rí àwọn ọmọ ẹyẹ méjì, tí ìyẹ́ wọn rí múlọ́múlọ́, tí wọ́n la ojú sílẹ̀ rekete, tí wọ́n sì ń wo gbogbo ohun tó wà láyìíká wọn tìyanutìyanu. Bí àwọn méjèèjì ṣe pohùn pọ̀ láti kígbe nítorí ebi, wọ́n yí ojú sí ìyá wọn tí ó jókòó sítòsí wọn, tí ó ń ṣọ́ wọn. Ó léwu láti sún mọ́ àwọn ọmọ wọ̀nyẹn ní àkókò yìí. Bí abo ẹyẹ náà bá lọ ronú pé ewu ń bẹ fún àwọn ọmọ òun, yóò rọra fò wá, yóò sì fi èékánná rẹ̀ tó mú bí abẹ ya ẹni tó wá síbẹ̀. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti ṣọ́ra, kí èèyàn sì jìnnà díẹ̀ sí ẹyẹ òwìwí bí èèyàn bá fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀.
Bíbọ́ Àwọn Ọmọ àti Kíkọ́ Wọn
Bí akọ bá ti dé ibi ìtẹ́ náà, a fi àgógó rẹ̀ gbé oúnjẹ náà kúrò níbi èékánná rẹ̀, yóò sì gbé eku náà fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. Bí wọ́n bá ti ń gbé oúnjẹ fún ọmọ ẹyẹ kan, ọmọ ẹyẹ tó kàn láti gba oúnjẹ yóò máa ké tòò.
Bí ọmọ ẹyẹ bá ti jẹ oúnjẹ tó ń yán hànhàn fún tán, yóò wá yí ìṣe rẹ̀ padà, tí yóò dà bí èyí tó ń pani lẹ́rìn-ín. Ìrísí ojú rẹ̀ tó ṣe rekete tó sì wà lójúfò títí di àkókò yẹn yóò yí padà, ọmọ ẹyẹ náà yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bíi pé ó ti mutí yó! Gbogbo agbára rẹ̀ ni yóò máa fi mú kí oúnjẹ yẹn dà nínú, kò sì ní pẹ́ tí yóò fi ká gúlútú, tí ìyẹ́ múlọ́múlọ́ yóò bò ó. Ṣùgbọ́n ojú ọmọ ẹyẹ tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe rekete díẹ̀díẹ̀, yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ lọ́wọ́ ipa tí oúnjẹ tí ó jẹ kẹ́yìn ní lórí rẹ̀, tó fi dà bíi pé ó mutí.
Àwọn nǹkan yóò máa bá a lọ báyìí títí di àárín oṣù June. Nígbà yẹn, àwọn ọmọ ẹyẹ yẹn yóò ti lo ọ̀sẹ̀ mẹ́rin, wọn yóò sì lè fò bàlàbàlà kúrò nínú ìtẹ́ wọn tí igbe ìyá wọn yóò mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, wọn yóò máa gun igi káàkiri nípa lílo òye gidigidi. Àwọn ẹranko tó lè pa wọ́n jẹ kò ní fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ níbẹ̀ tó bí wọn yóò ṣe pọ̀ lórí ilẹ̀.
Bó bá yá, àwọn ọmọ ẹyẹ náà yóò máa fi ìyẹ́ wọn fò látorí ẹ̀ka igi kan dé èkejì, wọ́n á máa kọ́ fífò. Bó bá ṣe díẹ̀, wọ́n á ti lè fò, kí wọ́n sì ṣọdẹ. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìrísí wọn yóò yí padà tí a óò fi lè sọ pé àwọn pẹ̀lú jẹ́ ‘ẹyẹ tó lẹ́wà tó ń gbé inú igbó.’
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
© Joe McDonald
© Michael S. Quinton
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]
© Michael S. Quinton
© Michael S. Quinton