Wíwo Ayé
Àlàyé Sí I Nípa Àwọn Tébi Ń Pa Lágbàáyé
Ìròyìn State of the World 2000 sọ pé: “Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) díwọ̀n pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan lágbàáyé—àwọn tó lọ́rọ̀ àti àwọn tí kò lọ́rọ̀—tó ń jìyà nítorí àìjẹunre kánú lọ́nà kan tàbí òmíràn.” Wọ́n fojú díwọ̀n pé ó lé ní bílíọ̀nù kan èèyàn jákèjádò ayé tó ní ìṣòro àìjẹunre kánú. Síwájú sí i, wọ́n ní bílíọ̀nù mélòó kan ni ‘ebi ń pa ṣùgbọ́n tí àwọn èèyàn kò mọ̀,’ èyí tó ń tọ́ka sí àwọn tó jọ pé wọ́n ń jẹun dáadáa ṣùgbọ́n tí àìsí àwọn fítámì àti èròjà pàtàkì já ní tànmọ́n-ọ̀n. Àjọ Worldwatch tó ń gbé ìròyìn ọlọ́dọọdún ti State of the World jáde sọ pé: “Èrò èké náà ṣì ń bá a lọ lónìí pé àìsí oúnjẹ ló ń fa ebi. Àmọ́, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé ìpinnu àwọn èèyàn ló ń fa ebi . . . Yálà àwọn èèyàn ń gbé ìgbésí ayé tó jọjú tàbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀, ipò tí a fi àwọn obìnrin sí láwùjọ, àti irú ọwọ́ tí àwọn ìjọba fi ń mú àwọn èèyàn wọn, ń ní ipa tó pọ̀ jù lọ lórí bóyá àwọn èèyàn ń rí oúnjẹ jẹ tàbí wọn kò rí jẹ ju ọ̀ràn bí nǹkan ọ̀gbìn ṣe pọ̀ tó ní orílẹ̀-èdè kan lọ.”
Àwọn Èèyàn Ń Fi Ọwọ́ Ara Wọn Para Wọn ní Ilẹ̀ Faransé
Ìwé ìròyìn Le Monde sọ pé: “Ìpín ọgbọ̀n lára àwọn àgbàlagbà ilẹ̀ Faransé ló ti gbèrò fífi ọwọ́ ara wọn pa ara wọn rí.” Lára àwọn tí a béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn nínú ìwádìí irú rẹ̀ àkọ́kọ́ yìí ní ilẹ̀ Faransé, ìpín mẹ́tàlá nínú ọgọ́rùn-ún ló sọ pé àwọn ti gbèrò àtipa ara àwọn rí, àwọn ìpín mẹ́tàdínlógún mìíràn sì jẹ́wọ́ pé àwọn ronú nípa rẹ̀ ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú gbogbo ọkàn. Bó ti wù kó rí, gẹ́gẹ́ bí Michel Debout, ọ̀jọ̀gbọ́n tí ń fi ìmọ̀ ìṣègùn wádìí ọ̀ràn òfin, ní ilé ìwòsàn yunifásítì ti Saint-Étienne, ti sọ, iye wọn ní ti gidi pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí pé ọ̀pọ̀ wọn ló ń gbé irú èrò bẹ́ẹ̀ pa mọ́ nítorí ìmọ̀lára ẹ̀bi. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò rí ọ̀ràn kí èèyàn pa ara rẹ̀ bí “ìwà ẹni táyé ti sú” tí àwọn ìṣòro tí ń bẹ láwùjọ ẹ̀dá fà dípò àwọn ipò inú ìdílé. Lọ́dọọdún, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́jọ èèyàn ló ti gbìyànjú láti pa ara wọn ní ilẹ̀ Faransé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìlá èèyàn ló sì fi ọwọ́ ara wọn pa ara wọn.
Kálukú Ń Ṣe Ẹ̀sìn Bó Ṣe Wù Ú
Ìwádìí kan tí olùwádìí ọ̀rọ̀ George Gallup Kékeré ṣe fi hàn pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ń wo ẹ̀sìn bí “àpòpọ̀ sàláàdì.” Ìwé ìròyìn National Post ti Kánádà sọ pé, dípò títẹ̀lé “àwọn ìlànà ètò ìgbàgbọ́ àbáláyé, àwọn ará [Àríwá] Amẹ́ríkà ‘ń fara balẹ̀ yan’ ohun tí wọ́n fẹ́ gbà gbọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ṣe àmúlùmálà àwọn èrò láti inú ẹ̀sìn kan tàbí kí wọ́n pa ẹ̀sìn méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pọ̀ láti ṣe ètò ohun tí olúkúlùkù yóò gbà gbọ́.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà ti sọ, ìwádìí náà tún fi hàn pé “ó hàn gbangba pé wọn kò ní ìmọ̀ nípa Bíbélì, àti àwọn lájorí ẹ̀kọ́ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ inú ẹ̀sìn wọn” àti pé “lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbàgbọ́ oréfèé ni ìgbàgbọ́ tí wọ́n sọ pé àwọn ní, tí àwọn èèyàn kò sì mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ìdí tí wọ́n fi gbà á gbọ́.” Reginald Bibby, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ nípa ìgbépọ̀ ẹ̀dá ní Yunifásítì Lethbridge, ní ìlú Alberta, ní orílẹ̀-èdè Kánádà, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ń tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti ìjọ Àgùdà àti Pùròtẹ́sítáǹtì, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń ṣe àṣàyàn ìgbàgbọ́, àṣà, àti àwọn iṣẹ́ àmọ̀dunjú—bí ìbatisí, ìgbéyàwó, àti ìsìnkú.”
Kọfí àti Oró Májèlé
Ìwé ìròyìn Australian sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí, kọfí lè mú “àwọn mẹ́táàlì tó lágbára, tó ti yọ́ tó jẹ́ ìpín méjìdínlọ́gọ́rin sí ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún bí òjé àti bàbà” kúrò nínú omi ẹ̀rọ “nítorí pé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ kọfí náà, tó ní àwọn mọ́lékù tí kò ní agbára mànàmáná lára ń fa àwọn mẹ́táàlì tó ní agbára mànàmáná lára mọ́ra.” Onímọ̀ nípa àyíká náà, Ọ̀mọ̀wé Mike McLaughlin, sọ pé: “Bí kọfí bá ṣe le sí, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe lè mú irú àwọn mẹ́táàlì bẹ́ẹ̀ kúrò.” Wọ́n fi tíì tí wọ́n dì sínú bébà ṣe irú àyẹ̀wò kan náà, ṣùgbọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé tíì ń yọ nǹkan bí ìdá mẹ́ta òjé kúrò, ó jọ pé kò fi bẹ́ẹ̀ ní agbára púpọ̀ lórí bàbà.
Ṣé A Lè Fi Yìnyín Mọ Ènìyàn Nígbà Sábáàtì?
Bí yìnyín ti pọ̀ gan-an nígbà òtútù tó kọjá ní Ísírẹ́lì ti gbé ìbéèrè tó gba ọgbọ́n láti dáhùn dìde fún àwọn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Júù, ìbéèrè náà ni pé: Ǹjẹ́ a fàyè gba jíju yìnyín luni lọ́jọ́ Sábáàtì? Fífi yìnyín mọ èèyàn ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn IsraelWire ti sọ, rábì àgbà ilẹ̀ Ísírẹ́lì tẹ́lẹ̀ rí, Mordehai Eliyahu, ti gbé àwọn ìtọ́sọ́nà kan jáde fún àwọn onígbàgbọ́ wọ̀nyẹn tí wọn kò mọ ohun tí a gbà láyè àti èyí tí a kò gbà láyè dájú. Rábì náà ṣàlàyé pé, fífi yìnyín mọ èèyàn jẹ́ “iṣẹ́,” kódà bó bá jẹ́ láti dára yá lásán ni. Nítorí náà, ọjọ́ Sábáàtì kò fàyè gba ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀ jíju yìnyín luni kì í ṣe iṣẹ́, nítorí náà, a fàyè gbà á. Ṣùgbọ́n àfi kan wà níbẹ̀ o. Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ kópa nínú eré náà gbọ́dọ̀ fohùn ṣọ̀kan pé nígbà tí àwọn bá ń ṣe eré jíju yìnyín luni náà, àwọn kò ní ju yìnyín lu àwọn tó ń kọjá lọ.
Ṣé Pé Ọpọlọ Àwọn Àgbàlagbà Ń Ṣẹ̀dá Sẹ́ẹ̀lì Iṣan Ọpọlọ Tuntun?
Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn èèyàn sábà máa ń rò pé wọ́n máa ń bí gbogbo sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ tí èèyàn ní jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ mọ́ ọn ni.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ọdún 1965 lọ́hùn-ún ni àwọn ìwádìí tí wọ́n lo àwọn ẹranko kan láti ṣe ti fi hàn pé ọpọlọ wọn ń ṣẹ̀dá àwọn sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ tuntun, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ nípa ètò iṣan ara lérò pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kì í ṣẹlẹ̀ lára ènìyàn. Ṣùgbọ́n láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá, ẹ̀rí ti wá pọ̀ rẹpẹtẹ tó ń fi hàn pé ọpọlọ ń ṣẹ̀dá àwọn sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ tuntun àti pé ó lè máa ṣàtúnṣe ara rẹ̀ léraléra. Lọ́dún tó kọjá, àwọn olùwádìí ṣàwárí pé a ń ṣẹ̀dá àwọn sẹ́ẹ̀lì tuntun, lápá ibi tó ní í ṣe pẹ̀lú rírántí nǹkan fúngbà díẹ̀, nínú ọpọlọ èèyàn. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ti wá gbà gbọ́ nísinsìnyí pé “ọpọlọ lè máa ṣàtúnṣe ara rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.”
Híhùwà Àìdáa Síni Nígbà Ọmọdé Lè Fa Akọ Másùnmáwo
Ìwé ìròyìn The Dallas Morning News sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí másùnmáwo tí àwọn obìnrin tí wọ́n ti fìyà jẹ tàbí tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe nígbà ọmọdé máa ń ní pọ̀ ju ti àwọn ẹlòmíràn lọ, ní gbogbo ìgbésí ayé wọn.” Àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Emory ní Atlanta fi bí ìwọ̀n omi ara tó ní í ṣe pẹ̀lú másùnmáwo ti pọ̀ tó àti bí ìṣiṣẹ́ ọkàn-àyà àwọn obìnrin tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe ṣe le tó wéra pẹ̀lú ti àwọn obìnrin tí wọn kò bá ṣèṣekúṣe, nígbà tí àwọn obìnrin náà bá ṣe iṣẹ́ tó ń fa àìfararọ. Àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe nígbà ọmọdé ni ìwọ̀n omi ara tó ní í ṣe pẹ̀lú másùnmáwo tiwọn ga jù, bákan náà ni ìwọ̀n ìṣiṣẹ́ ọkàn-àyà wọn túbọ̀ yára kánkán, tí wọ́n bá wà ní ipò tí kò fararọ. Àwọn olùwádìí náà sọ pé, “èròjà kẹ́míkà tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀nà tí ara wọ́n ń gbà hùwà padà, tó sì ń gbà ṣàkóso másùnmáwo lè ti ní àbùkù tí kò ṣeé tún ṣe,” ni ohun tí ìwé ìròyìn náà sọ.
Àwọn Àpò Àgbépọ̀nyìn Tó Wúwo
Ìwádìí kan tí Àjọ Àwọn Oníṣẹ́ Abẹ Títo Egungun Ara ní Amẹ́ríkà ṣe ti fi hàn pé ìṣòro ẹ̀yìn àti èjìká ríro tó ń ṣe àwọn ọmọdé ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àpò àgbépọ̀nyìn wíwúwo tí àwọn ọmọdé kan ń gbé. Tí àwọn ọmọdé kan bá ti ko ìwé ilé ẹ̀kọ́, oúnjẹ àti ohun mímu, àwọn ohun èlò orin, àti àwọn aṣọ díẹ̀ tí wọ́n lè fi pààrọ̀, wọn máa ń pọ̀n ọ́n sẹ́yìn, ẹrù náà sì ń wúwo tó kìlógíráàmù méjìdínlógún. Àwọn onímọ̀ nípa ìtọ́jú àrùn àwọn ọmọdé kìlọ̀ pé ó lè wá yọrí sí pé kí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ máa ní ìṣòro ẹ̀yìn ríro gan-an, títí kan kí eegun ẹ̀yìn wọn tẹ̀, bí wọ́n bá ń pọn ẹrù tó wúwo tó bẹ́ẹ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ lójoojúmọ́. Ìwé ìròyìn Excelsior ti Ìlú Ńlá Mẹ́síkò sọ pé, àwọn ògbóǹtagí kan gba àwọn ọ̀gá ilé ìwé àti àwọn olùkọ́ nímọ̀ràn pé kí ìwọ̀n àpò àgbépọ̀nyìn tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń gbé má ṣe ju ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n ara ọmọ tó gbé e lọ tàbí kí wọ́n máa gbé wọn “sínú ohun ìrìnnà, tàbí kí wọ́n ní bẹ́líìtì tí wọn yóò máa gbé e kọ́ níbàdí, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ gbé tìmùtìmù lé ẹ̀yìn kí wọ́n tó gbé àpò náà lé e.”
Wáìnì Tó Ti Pẹ́ Tó Ọ̀rúndún Mẹ́ta
Ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé wọ́n rí ìgò wáìnì méjì nínú pàǹtí àwókù ilé kan tí wọ́n wó nílùú London lọ́dún 1682. Ìdérí ọ̀kan lára wọn ti jẹrà, wáìnì inú rẹ̀ sì ti kan; ṣùgbọ́n ìdérí èkejì, ṣì wà níbẹ̀ nítorí tí irin àti gọ́ọ̀mù tí wọ́n fi lẹ̀ ẹ́ kò jẹ́ kó ṣí rárá. Níbi àyẹ̀wò àkànṣe kan tí wọ́n ṣe láti tọ́ àwọn ọtí wò níbi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti London, àwọn ògbógi onímọ̀ nípa wáìnì tọ́ díẹ̀ tí wọ́n fi abẹ́rẹ́ fà lára ọtí tó ti wà fún ọ̀rúndún mélòó kan yìí wò. Wọ́n sọ pé ó lè jẹ́ ọtí Madeira ni, wọ́n sì sọ pé “àkọ̀tun ni, kò le jù, ó dára lẹ́nu, ó sì gbádùn mọ́ni.”
Àwọn Odò Àgbáyé Wà Nínú Ìṣòro Ńláǹlà
Ìwé ìròyìn USA Today sọ pé: “Ó lé ní ìdajì lára àwọn odò pàtàkì tó wà lágbàáyé tó ti ń gbẹ tàbí kí wọ́n ti bà á jẹ́.” Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Omi Lágbàáyé fún Ọ̀rúndún Kọkànlélógún sọ pé, ọ̀pọ̀ ibi tí odò ń ṣàn gbà “ló ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ tán, tí wọ́n sì ti sọ dìbàjẹ́” nítorí lílo ilẹ̀ àti omi ní àlòjù àti ní ìlòkulò. Àjọ náà sọ pé, bíba àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àdánidá yìí jẹ́ ń “wu ìlera àti ọ̀nà ìgbọ́bùkátà àwọn èèyàn tí wọ́n gbára lé wọn fún bíbomirin oko, fún mímu àti fún fífi ṣiṣẹ́ léwu.” Ká ṣì máa dúpẹ́ pé lára ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta odò pàtàkì tó wà jákèjádò ayé, odò méjì ṣì wà tó “mọ́ tónítóní,” àwọn ni odò Amazon ní Gúúsù Amẹ́ríkà àti odò Kóńgò ní Áfíríkà. Kí ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀? Ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ kò pọ̀ nítòsí bèbè odò méjèèjì.”