Ìwà Àìláàánú Tí Ènìyàn Ń hù—Yóò Ha Dópin Láé Bí?
Wọ́n fún Livia Turco, tó jẹ́ Mínísítà Ètò Ìfìmọ̀ṣọ̀kan Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà ní Ítálì, ní ẹ̀dà Jí!, ìtẹ̀jáde March 8, 2000, tó jíròrò nípa ọ̀ràn ìfiniṣẹrú tó bani nínú jẹ́ pé ó ṣì ń bá a nìṣó láwọn ibì kan lágbàáyé. Ó sọ nínú lẹ́tà kan tó kọ sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ítálì pé:
“Àwọn oríṣi àṣà ìfiniṣẹrú lóde òní, tó kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ní pàtàkì, jẹ́ ìṣòro tó yẹ ká fún láfiyèsí gidigidi nítorí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ni ìyà ṣì ń jẹ.” Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Gbogbo ẹni tó bẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò dùn mọ́ni nínú yìí la mọrírì ọ̀rọ̀ wọn, tí èyí bá sì lè dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú tó pọ̀ gan-an bí àwọn tó ń ka [Jí!], á túbọ̀ gbéṣẹ́ gan-an.”
A dúpẹ́ fún pípín tí a ń pín iye tó lé ní ogún mílíọ̀nù ẹ̀dà Jí! kọ̀ọ̀kan ní èdè méjìlélọ́gọ́rin, bí àwọn ìṣòro tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ṣe rí nìkan kọ́ ni a fi ń tó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn létí, ṣùgbọ́n a tún ń kọ́ wọn ní ọ̀nà tí wọ́n lè gbà lo ohun tó wà nínú Bíbélì láti yanjú àwọn ìṣòro wọn.
Síbẹ̀, ìbéèrè náà ṣì wà pé, Bí Ọlọ́run bá wà ní tòótọ́, èé ṣe tó fi ń jẹ́ kí ìyà ńláǹlà máa jẹ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀? Ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá tí ọgbọ́n rẹ̀ hàn kedere nínú àwọn ohun àgbàyanu ìṣẹ̀dá, ṣùgbọ́n tó jọ pé kò fi ìyọ́nú hàn sí àwọn èèyàn lónìí?’ A dáhùn irú àwọn ìbéèrè yẹn lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? O lè rí ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ yìí gbà tí o bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
◻ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.