ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 11/15 ojú ìwé 12-13
  • Ìgbà Tó Yẹ Kó O Pa Dà Sọ́dọ̀ Àwọn Òbí Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Tó Yẹ Kó O Pa Dà Sọ́dọ̀ Àwọn Òbí Rẹ
  • Jí!—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
  • Ṣé Ó Ti Yẹ Kí N Kúrò Lọ́dọ̀ Àwọn Òbí Mi?
    Jí!—2010
  • Ṣé Mo Ti Tó Ẹni Tó Lè Lọ Dá Gbé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Owó Ná?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná?
    Jí!—2006
Àwọn Míì
Jí!—2015
g 11/15 ojú ìwé 12-13

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́

Ìgbà Tó Yẹ Kó O Pa Dà Sọ́dọ̀ Àwọn Òbí Rẹ

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ti tójú bọ́ máa ń fi ilé sílẹ̀ kí wọ́n lè máa dá gbé, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń rí i pé ìgboro kò dẹrùn, èyí sì máa ń mú kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn. Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí?

Kódà, tó o bá fẹ́ràn àwọn òbí rẹ, ó ṣì máa ṣòro fún ẹ láti pa dà sọ́dọ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Saraha sọ pé: “Bí mo ṣe ń dá gbé jẹ́ kí n mọ̀ pé mi ò kì í ṣe ọmọdé mọ́, torí pé èmi ni mò ń gbọ́ bùkátà ara mi. Àmọ́ nígbà tí mo pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí mi, ńṣe ló dá bíi pé mo pa dà di ọmọdé.” Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Richard nìyẹn, ó sọ pé: “Kò wù mí kí n pa dà sílé, ṣùgbọ́n owó ti tán lọ́wọ́ mi. Èyí mú kí n dà bí aláṣetì.”

Tí ọ̀rọ̀ tiẹ̀ náà bá rí báyìí, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe láti wà láyè ara rẹ.

OHUN TÓ FÀ Á

Ọ̀rọ̀ owó. Ó máa ń bá ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lójijì nígbà tí wọ́n bá rí i pé kò rọrùn láti gbọ́ bùkátà ara ẹni. Richard tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mi ò ní àjẹṣẹ́kù, torí gbogbo owó tí mò ń rí ni mo fi ń gbọ́ bùkátà ara mi.” Bí ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Shaina ṣe rí nìyẹn, ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24] ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé. Àmọ́, ó pa dà sílé lẹ́yìn ọdún kan ààbọ̀, ó sọ pé: “Mi ò mọ bí èèyàn ṣe ń ṣówó ná. Kò sówó lọ́wọ́ mi nígbà tí mo kúrò nílé, gbèsè ló sì bá mi pa dà wálé.”b

Ìṣòro iṣẹ́. Tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ rẹ, ó lè mú kó pọn dandan pé kó o pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Shaina nìyẹn, ó sọ pé: “Mo jáde nílé ìwé tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn, mo sì rí iṣẹ́. Àmọ́ nígbà tí iṣẹ́ náà bọ́ lọ́wọ́ mi, mi ò rí iṣẹ́ míì. Torí pé abúlé kan ni mò ń gbé, ó ṣòro láti rí iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ohun tí mo kọ́ nílé ìwé!”

Nǹkan ò rí bí wọ́n ṣe rò. Àwọn ọ̀dọ́ kan ò mọ̀ pé kò rọrùn láti ṣe iṣẹ́ téèyàn á fi máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Iṣẹ́ tí wọ́n sábà máa ń rí máa ń le ju bí wọ́n ṣe rò. Wọ́n rò pé táwọn bá ti ń dá gbé, káwọn máa jayé gbẹdẹmukẹ ló kù, àmọ́ ọ̀rọ̀ kì í rí bẹ́ẹ̀. Wọn ò mọ̀ pé àti dá gbé ò rọrùn rárá.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ pé o fẹ́ pa dà sílé. Ẹ jọ jíròrò àwọn nǹkan yìí: Báwo lo ṣe máa pẹ́ tó lọ́dọ̀ wọn? Àwọn ìnáwó wo ni wàá lè máa bójú tó nínú ilé? Àwọn iṣẹ́ ilé wo ni wàá máa ṣe? Àwọn nǹkan wo ni wàá ṣe kó o lè pa dà máa gbọ́ bùkátà ara rẹ? Láìka ọjọ́ orí rẹ sí, rántí pé o ti pa dà sábẹ́ àwọn òbí rẹ, òfin tí wọ́n bá sì fún ẹ lo gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé.—Ìlànà Bíbélì: Ẹ́kísódù 20:12.

Kọ́ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná. Ìwé kan tó ń jẹ́ The Complete Guide to Personal Finance: For Teenagers and College Students sọ pé: “Béèyàn ṣe ń náwó ló máa pinnu bóyá ó máa ní àkójọ tàbí kò ní lákòójọ. . . . Ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn má ṣe máa náwó sórí ohun tí kò wúlò fún un.”—Ìlànà Bíbélì: Lúùkù 14:28.

Gba ìmọ̀ràn. Àwọn òbí rẹ àtàwọn àgbàlagbà míì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ béèyàn ṣe ń fowó pamọ́ àti béèyàn ṣe ń gbé ìṣirò lé owó tó bá fẹ́ ná. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Marie sọ pé: “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ní láti kọ́ béèyàn ṣe ń náwó. Èmi àti ọ̀rẹ́ mi jọ kọ gbogbo ohun tí mo máa ń náwó lé lórí sílẹ̀. Ó yà mí lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ nǹkan tí mò ń náwó lé ni kò ṣe pàtàkì! Mo tún kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tó máa wúlò fún mi tí mo bá ń dá gbé, ìyẹn kí n má ṣe máa ná ìná àpà.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 13:10.

Kì í ṣe irú iṣẹ́ tí ò ń ṣe ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe pé kó o di ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá ń ṣe

Wá iṣẹ́. Má kàn jókòó gẹlẹtẹ, lọ wá iṣẹ́. Àmọ́ o, àwọn kan lè máa sọ fún ẹ pé iṣẹ́ tó bá wù ẹ́ ló yẹ kó o wá. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ tó wù ẹ́ nìkan lò ń wá, ó ṣeé ṣe kó o pàdánù àwọn iṣẹ́ míì tó ń yọjú. Dípò tí wàá fi máa wá irú iṣẹ́ kan pàtó, á dáa kó o ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá rí. Ó ṣe tán, ọ̀nà kan ò wọjà. Fi sọ́kàn pé, kì í ṣe irú iṣẹ́ tí ò ń ṣe ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe pé kó o di ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá ń ṣe. Torí náà, bó o bá ṣe ń mọ iṣẹ́ rẹ sí i, tó o sì já fáfá lẹ́nu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ máa gbádùn iṣẹ́ náà sí i. Kò dìgbà tó o bá ṣe iṣẹ́ tó wù ẹ́ kó o tó gbádùn iṣẹ́ tó ń ṣe!

a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

b Àwọn ọmọléèwé gíga lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sábà máa ń nírú ìṣòro yìí. Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé, gbèsè tó máa ń wà lọ́rùn àwọn ọmọ tó yáwó lọ sí iléèwé máa ń tó $33,000 [nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà ààbọ̀ náírà] nígbà tí wọ́n bá fi máa jáde nílé ìwé.

FI ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN

  • “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” —Ẹ́kísódù 20:12.

  • “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?”—Lúùkù 14:28.

  • “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.”—Òwe 13:10.

FÚN ÀWỌN ÒBÍ

Lo àǹfààní àkókò táwọn ọmọ rẹ wà lọ́dọ̀ rẹ láti kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí wọ́n máa nílò tí wọ́n bá ń dá gbé. O gbọ́dọ̀ kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa náwó (èyí ní nínú, kí wọ́n máa ṣọ́wó ná, kí wọ́n sì yẹra fún jíjẹ gbèsè). Tún kọ́ wọn ní iṣẹ́ ilé (èyí ní nínú, dídáná, fífọ aṣọ àti lílọ aṣọ àti ṣíṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lára mọ́tò). Ó sì tún ṣe pàtàkì kó o kọ́ wọn níwà ọmọlúàbí (èyí ní nínú bíbá àwọn èèyàn gbé ní ìrẹ́pọ̀).

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo ojú ìwé 305 àti 306 nínú ìwé “Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́,” Apá Kìíní. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo. Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́