Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná?
“Mo sábà máa ń rí i pé mo máa ń ṣètò bí màá ṣe ra nǹkan tí mi ò fi taratara nílò, àti nǹkan tó ṣeé ṣe kí owó mi máà ká, kìkì nítorí pé wọ́n fẹ́ tà á.”— Anna,a láti orílẹ̀-èdè Brazil.
“Nígbà míì, àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń sọ fún mi pé kí n jẹ́ ká jọ ṣe àwọn nǹkan kan tó máa gbọ́n mi lówó. Mo máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi, ká lè jọ gbádùn ara wa. A kì í fẹ́ sọ fún ara wa pé, ‘Ó dùn mí pé mi ò lè bá yín lọ.’”— Joan, láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà.
ṢÓ O máa ń rò pé owó ọwọ́ ẹ kì í tó ẹ ná? Ká ní owó táwọn òbí ẹ máa ń fún ẹ pọ̀ díẹ̀ jùyẹn lọ ni, ò bá lè ra nǹkan ìṣeré tó wù ẹ́ rà yẹn. Ká sọ pé owó táwọn òbí ẹ ń fún ẹ pọ̀ jùyẹn lọ ni, ò bá ra bàtà tó o rò pé o nílò yẹn. Àmọ́, dípò kó o jẹ́ kí àìlówó tó tó ẹ ná máa dà ẹ́ láàmú, o ò kúkú ṣe kọ́ bó o ṣe lè máa ṣọ́ owó tó bá wà lọ́wọ́ ẹ ná?
O lè fẹ́ dúró dìgbà tí wàá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé láàyè ara ẹ. Àmọ́, ńṣe nìyẹn á dà bí ìgbà téèyàn bẹ́ sódò láìmọ̀wẹ̀. Lóòótọ́ o, ó lè rọ́gbọ́n tá sí i níbi tó ti ń ṣe tàbútàbú káàkiri nínú omi o. Àmọ́, báwo ni ì bá ti dára tó bó bá kọ́kọ́ kọ́ béèyàn ṣe ń lúwẹ̀ẹ́ kó tó bẹ́ sódò!
Bákan náà, ìgbà tó dára jù lọ fún ẹ láti kọ́ béèyàn ṣe ń ṣọ́ owó ná ni kó tó di pé wàhálà àtirówó gbọ́ bùkátà á dojú kọ ẹ́. Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.” (Oníwàásù 7:12) Àmọ́, ó dìgbà tó o bá kọ́ bó o ṣe lè máa ṣọ́ owó ná kí owó tó lè máa dáàbò bò ẹ́. Ẹ̀kọ́ yìí á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé wàá mowó ná, á sì jẹ́ káwọn òbí ẹ ní ọ̀wọ̀ tó pọ̀ sí i fún ẹ.
Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Ṣọ́ Owó Ná
Ṣó o tiẹ̀ ti sọ fáwọn òbí ẹ rí pé kí wọ́n ṣàlàyé bí ọ̀ràn àbójútó ilé ṣe rí fún ẹ? Bí àpẹẹrẹ, ṣó o mọ iye tí iná àti omi ń ná wọn lóṣooṣù àti iye tí wọ́n ń ná sórí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, iye tí wọ́n fi ń ra oúnjẹ àti iye owó ilé tàbí ẹ̀yáwó tí wọ́n ń san padà fún báńkì? O lè rò pé mímọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ yẹn ti pọ̀ jù fún ẹ. Àmọ́, má gbàgbé pé gbogbo yín lẹ jọ gbádùn ẹ̀ o. Ó ṣe tán, bó o bá di ẹni ara ẹ, ìwọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí í náwó lé àwọn nǹkan yẹn lórí. Nítorí náà, ó yẹ kó o mọ bí owó tí wọ́n máa ń náni ṣe pọ̀ tó. Sọ fáwọn òbí ẹ pé ṣé wọ́n lè jẹ́ kó o rí díẹ̀ lára àwọn ìwé owó náà, kó o sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí wọn bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé owó tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn ìnáwó náà.
Òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i, ẹni òye sì ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá.” (Òwe 1:5) Anna, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé, “Bàbá mi kọ́ mi béèyàn ṣe ń ya owó tó máa ná sórí oríṣiríṣi nǹkan sọ́tọ̀, ó sì jẹ́ kí n rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn wà létòlétò nípa bó ṣe ń lo owó tó jẹ́ ti ìdílé.” Màmá Anna náà ò sì gbẹ́yìn, ó kọ́ ọ láwọn ẹ̀kọ́ mìíràn tó gbámúṣé. Anna sọ pé: “Mọ́mì jẹ́ kí n rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa nájà wò ní ọ̀nà méjì mẹ́ta. Bọ́wọ́ Mọ́mì bá tẹ owó kékeré, wọ́n á pitú tó pọ̀.” Ẹ̀kọ́ wo ni Anna ti rí kọ́ o? Ó sọ pé: “Ó ti wá ṣeé ṣe fún mi báyìí láti máa gbọ́ bùkátà ara mi. Mo máa ń náwó tìṣọ́ratìṣọ́ra, nítorí náà ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé mi ò ní kó sí gbèsè.”
Mọ̀ Pé Kò Rọrùn Láti Ṣọ́wó Ná
Ibi tọ́rọ̀ wá wà ni pé ṣíṣọ́ owó ná dùn-ún sọ lẹ́nu, àmọ́ ó ṣòroó ṣe, pàápàá jù lọ bó ò bá tíì máa dá gbé, tó sì jẹ́ pé àwọn òbí ẹ ń fún ẹ lówó tàbí tó ò ń rówó láti ibi iṣẹ́ kan. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òbí ẹ ló ń san ọ̀pọ̀ lára owó tẹ́ ẹ bá ná. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó o máa ná èyí tó pọ̀ jù lára owó tó ń wọlé fún ẹ bó o bá ṣe fẹ́. Owó sì máa ń dùn ún ná o jàre. Paresh, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Íńdíà náà gbà pé bó ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Owó ò ṣòro ná fún mi rárá, ṣe ló máa ń dùn mọ́ mi.” Bó ṣe rí lára Sarah tó wá láti ilẹ̀ Ọsirélíà náà nìyẹn. Ó sọ pé: “Ríra nǹkan máa ń mórí mi yá gan-an ni.”
Láfikún sí ìyẹn, àwọn ojúgbà ẹ tún lè máa yọ ẹ́ lẹ́nu pé kó o náwó kọjá agbára ẹ. Ellena, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún, sọ pé: “Láàárín àwọn ojúgbà mi, ká máa ra tibí ra tọ̀hún ti di eré ìnàjú pàtàkì. Bá a bá jọ jáde báyìí, ṣe ló dà bíi pé a ti wá gbà láàárín ara wa pé àfi bá a bá ń náwó la tó lè gbádùn ara wa.”
Kò sí ẹ̀dá tí kì í wù pé kóun àtàwọn ọ̀rẹ́ òun jọ gba tara àwọn. Ṣùgbọ́n, bi ara ẹ léèrè pé, ‘Ṣé ohun tó ń mú kí èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi jọ máa náwó ni pé agbára mi gbé e àbí mo ronú pé mo gbọ́dọ̀ náwó?’ Nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ máa gbayì lójú àwọn ọ̀rẹ́ àti alábàákẹ́gbẹ́ wọn ni wọ́n ṣe ń náwó. Bó o bá ń ronú báyìí, o ò ní pẹ́ kó sí gbèsè, àgàgà tó o bá tún wá lọ ní káàdì ìrajà. Ẹnì kan tó ń gbani nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìnáwó, Suze Orman, kìlọ̀ pé: “Bó bá ń wù ọ́ pé kó o máa fi ohun tó o ní ṣe fọ́rífọ́rí, dípò kó o jẹ́ kí wọ́n mọyì ẹ nítorí àwọn ànímọ́ rere tó o ní, àfàìmọ̀ ni lílo káàdì ìrajà ó fi ní dá ọ ní gbèsè.”
Dípò ti wàá fi máa ná gbogbo owó tó wà nínú káàdì ìrajà ẹ tàbí tí wàá fi ná gbogbo owó oṣù ẹ tán láàárín ọjọ́ kan ṣoṣo, o ò kúkú ṣe gbìyànjú láti ṣe bíi ti Ellena? Ó sọ pé: “Bí mo bá báwọn ọ̀rẹ́ mi lọ sóde, màá ti mọ̀ nínú ara mi pé mi ò ní ná ju iye pàtó kan lọ. Tààràtà lowó oṣù mi máa ń kọjá lọ sí báńkì, kìkì iye tí màá ná lóde tá à ń lọ ni màá sì mú dání. Mo tún rí i pé ó bọ́gbọ́n mu láti máa bá àwọn ọ̀rẹ́ mi tí kì í náwó nínàákúnàá lọ sọ́jà, àwọn tó máa gbà mí níyànjú pé kí n nájà káàkiri, kí n má sì máa ra ohun tí mo bá kọ́kọ́ rí.”—Òwe 13:20.
Lóye Ohun Táwọn Òbí Ń Kọ́ Ẹ Bí Wọ́n Bá Sọ Pé Rárá
Ká tiẹ̀ ní àwọn òbí ẹ kì í fún ẹ lówó, tí owó kankan ò sì tíì máa wọlé fún ẹ, o ṣì lè kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì nípa béèyàn ṣe ń tọ́jú owó nígbà tó o ṣì ń gbé lọ́dọ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá ní káwọn òbí ẹ fún ẹ lówó tàbí tó o ní kí wọ́n ra àwọn nǹkan kan fún ẹ, wọ́n lè sọ fún ẹ pé ààyè ẹ̀ ò yọ. Kí nìdí? Ó lè jẹ́ pé ìdí kan tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé ohun tó ò ń fẹ́ ti pọ̀ ju ohun tówó ìdílé lè ká lọ. Nítorí náà, bí wọ́n bá sọ pé ààyè ẹ̀ ò yọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè wù wọ́n láti ṣe ohun tó o fẹ́ fún ọ, ńṣe làwọn òbí ẹ ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún ẹ lórí béèyàn ṣe lè ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Bẹ́ẹ̀ sì rèé ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe pàtàkì kéèyàn má bàa máa náwó nínàákúnàá.
Ká tiẹ̀ ní àwọn òbí ẹ lè ṣe gbogbo ohun tó o bá béèrè. Síbẹ̀, wọ́n ṣì lè sọ fún ẹ pé ààyè ẹ̀ ò yọ. O lè rò pé wọ́n ń ṣahun ni. Ṣùgbọ́n, rò ó wò ná: Ó lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ń gbìyànjú láti kọ ẹ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé kò dìgbà tọ́wọ́ ẹ bá tẹ gbogbo ohun tó o fẹ́ kó o tó láyọ̀. Ìyẹn ni Bíbélì fi sọ pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.”—Oníwàásù 5:10.
A lè rí òótọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ yìí bá a bá kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ táwọn òbí wọn ń ra gbogbo ohun tí wọ́n bá ṣáà ti fẹ́ fún wọn. Àwọn ọ̀dọ́ náà kì í pẹ́ rí i pé àwọn kì í fi bẹ́ẹ̀ nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Bó ti wù kí ohun tí wọ́n kó jọ sílé pọ̀ tó, á ṣáà máa ṣe wọ́n bíi kí wọ́n tún ra ohun kan kún un. Bó bá wá yá, àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ pé gbogbo ohun tí wọ́n bá ṣáà ti fẹ́ ni wọ́n máa ń rà fún wọn á wá dàgbà di aláìmoore. Àbájọ tí Sólómọ́nì fi kìlọ̀ pé: “Bí ènìyàn bá ń kẹ́ ìránṣẹ́ [tàbí ọmọ] rẹ̀ ní àkẹ́jù láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ní ìkẹyìn ìgbésí aye rẹ̀, yóò di aláìmọ ọpẹ́ dá pàápàá.”—Òwe 29:21.
Bí Àkókò Lowó Rí
Àwọn kan wà tí wọ́n máa ń sọ pé, Owó ni àkókò. Èyí fi hàn pé ó gba àkókò láti ṣiṣẹ́ owó àti pé béèyàn bá ń fàkókò ṣòfò, bí ẹní ń fowó ṣòfò ni. Bọ́rọ̀ yìí ṣe rí gan-an lòdì kejì ẹ̀ náà rí, ìyẹn ni pé àkókò ni owó. Bó o bá fowó ẹ ṣòfò, àkókò tó o fi wá owó yẹn lo fi ṣòfò yẹn. Bó o bá mọ bí wàá ṣe máa ṣọ́ owó ẹ ná, ó dájú pé wàá mọ bí wàá ṣe máa ṣọ́ àkókò ẹ lò. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
Gbé ohun tí Ellena sọ yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń ṣọ́ owó ná ń jẹ́ kí n lè pinnu iye tó yẹ kó máa wọlé fún mi. Nítorí pé mo ní ìṣètò tó gbámúṣé nípa bí màá ṣe máa náwó, tí n kì í sì í ná kọjá iye yẹn, kò di dandan pé kí n máa fàkókò gbọọrọ ṣiṣẹ́ kí n bàa lè san gbèsè gọbọi. Ó túbọ̀ rọrùn fún mi láti máa pinnu bí màá ṣe lo àkókò mi àti bí màá ṣe máa gbé ìgbé ayé mi.” Àbí kò wu ìwọ náà pé kó o lè máa pinnu bí wàá ṣe máa gbé ìgbé ayé ẹ?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti ṣọ́ owó ẹ ná? Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
◼ Kí nìdí tó fi yẹ kó o sá fún ìfẹ́ owó?—1 Tímótì 6:9, 10.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
ṢÉ ÀNÍKÚN OWÓ LÓ MÁA TÁN ÌṢÒRO MI?
Ṣé kó o ṣáà ti lówó púpọ̀ sí i lọ́wọ́ ló máa tán ìṣòro níná tó ò ń náwó nínàákúnàá? Agbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn owó níná, Suze Orman, sọ pé: “Gbogbo wa la máa ń ronú pé bówó tó ń wọlé fún wa bá pọ̀ sí i, ìṣòro ìṣúnná owó tán nìyẹn, àmọ́ ọ̀rọ̀ kì í sábàá rí bẹ́ẹ̀.”
Àpẹẹrẹ kan rèé: Bó o bá ń wakọ̀, tí ọkọ̀ náà sì ń yà bàrà sọ́tùn-ún sósì mọ́ ẹ lọ́wọ́, tàbí tó jẹ́ pé ńṣe lo máa ń dijú wakọ̀, ṣé ọ̀nà tó o lè gbà kòòré jàǹbá ni pé kó o túbọ̀ rọ epo sínú mọ́tò rẹ? Ṣó o rò pé wàá lè délé láyọ̀? Bọ́rọ̀ owó níná náà ṣe rí nìyẹn. Bó ò bá kọ́ béèyàn ṣeé ṣúnwó ná, àníkún owó ò lè tán ìṣòro rẹ.
[Àpótí/Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 15]
MÁA ṢỌ́ OWÓ NÁ
Ó tó èló tó o ná lóṣù tó kọjá? Kí lo náwó ọ̀hún lé lórí? Ṣé pé o ò lè sọ ohun tó o ná an lé lórí? Ọgbọ́n tó o lè dá rèé tí wàá fi máa ṣọ́ bó o ṣe ń náwó kó tó di pé o di onínàákúnàá.
◼ Máa kọ àkọsílẹ̀. Ó kéré tán, láàárín oṣù kan, máa kọ àkọsílẹ̀ iye owó tó ń wọlé fún ẹ àti ọjọ́ tó o rí owó náà gbà. Kọ ohun tó o bá rà àti iye tó o fi rà á sílẹ̀ níkọ̀ọ̀kan. Níparí oṣù yẹn, ṣe àròpọ̀ gbogbo owó tó wọlé fún ẹ àti iye owó tó o ná.
◼ Ṣètò bí wàá ṣe máa náwó ẹ. Mú ìwé kan tí wọn ò kọ nǹkan kan sí, fa ìlà láti dá a sí òpó mẹ́ta. Kọ gbogbo owó tó o retí pé kó wọlé fún ẹ lóṣù sínú òpó ìlà àkọ́kọ́. Nínú òpó ìlà kejì, ṣe àkọsílẹ̀ bó o ṣe fẹ́ ná owó ẹ síbẹ̀; o lè tẹ̀ lé àwọn ohun tó wà nínú àkọsílẹ̀ rẹ láti ṣe èyí. Bí oṣù yẹn ti ń lọ, wá kọ iye owó tó o ná gan-an sórí àwọn ohun tó o ti wéwèé láti rà sínú òpó ìlà kẹta. Tún kọ gbogbo owó tó o ná láìròtẹ́lẹ̀ síbẹ̀.
◼ Tún èrò ẹ pa. Bó o bá ń ná ju iye tó o rò tẹ́lẹ̀ lọ sórí àwọn ohun kan tó o rà tí gbèsè sì ṣẹ́ jọ sí ẹ lọ́rùn, tún èrò pa. San gbèsè tó wà lọ́rùn ẹ. Máa ṣọ́ bó o ṣe ń náwó.
[Àtẹ Ìsọfúnnni]
Gé èyí kó o sì máa lò ó!
Ètò Ìnáwó Mi Lóṣooṣù
Owó tó ń wọlé Iye tí mo fẹ́ ná Iye tí mo ná
owó táwọn òbí ń fún ẹ oúnjẹ
iṣẹ́ àfipawọ́ aṣọ
àwọn nǹkan míì fóònù
eré ìdárayá
ìdáwó
owó tí mò ń fi pa mọ́
àwọn nǹkan míì
Àròpọ̀ Àròpọ̀ Àròpọ̀
₦ ₦ ₦
[Àwòrán]
Má ṣe gbàgbé pé bó o bá fowó ṣòfò, àkókò tó gbà ẹ́ láti fi ṣiṣẹ́ owó náà lo fi ṣòfò yẹn o