ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g16 No. 2 ojú ìwé 12-13
  • Àníyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àníyàn
  • Jí!—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé ó burú kéèyàn máa ṣàníyàn?
  • Bó o ṣe lè borí àníyàn àṣejù
  • Ǹjẹ́ a máa bọ́ lọ́wọ́ ṣíṣàníyàn?
  • Kó Gbogbo Àníyàn Rẹ lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ẹ Kó Gbogbo Àníyàn Yín Lé Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Àníyàn?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Àwọn Ọkùnrin Tó Ń Ṣàníyàn Lọ́wọ́?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Jí!—2016
g16 No. 2 ojú ìwé 12-13

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Àníyàn

Ọ̀nà méjì ni àníyàn pín sí. Ọ̀kan dáa, àmọ́ ìkejì burú. Bíbélì ṣàlàyé bá a ṣe lè dá àníyàn méjèèjì mọ̀.

Ṣé ó burú kéèyàn máa ṣàníyàn?

ÒÓTỌ́ Ọ̀RỌ̀

Àníyàn máa ń mú kí èèyàn máa kọ́kàn sókè, kẹ́rù máa bani, kéèyàn sì máa ronú ju bó ṣe yẹ lọ. Gbogbo wa la máa ń ṣàníyàn torí pé kò sẹ́ni tó mọ bí ọ̀la ṣe máa rí nínú ayé yìí.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Títí di ìgbà wo ni ọkàn mi yóo gbọgbẹ́ tí ìbànújẹ́ yóo gba ọkàn mi kan, ní gbogbo ìgbà?” (Sáàmù 13:2 Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀) Kí ló jẹ́ kí Dáfídì lè fara da àwọn ìṣòro rẹ̀? Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún un, ó sì gbà pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni Ọlọ́run ní sí òun. (Sáàmù 13:5; 62:8) Ọlọ́run tiẹ̀ rọ̀ wá pé ká kó àníyàn wa fún òun. Ó sọ nínú 1 Pétérù 5:7 pé: ‘Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.’

Ìyá àgbàlagbà kan jókòó sẹ́nu ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ sì ń tún ọgbà rẹ̀ ṣe

Tá a bá ń ṣe nǹkan fún àwọn èèyàn tá a fẹ́ràn, kò ní jẹ́ ká máa ṣàníyàn jù nípa wọn

Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti gbé àníyàn kúrò lọ́kàn ni pé ká ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ní “àníyàn fún gbogbo àwọn ìjọ,” ohun tó ṣe ni pé ó tù wọ́n nínú, ó sì fún wọn ní ìṣírí. (2 Kọ́ríńtì 11:28) Nípa bẹ́ẹ̀, àǹfààní ni àníyàn rẹ já sí, torí pé ìyẹn ló mú kó lè pèsè ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò. Àwa náà lè ṣe bíi tiẹ̀. Àmọ́, tá a bá ní ẹ̀mí ìdágunlá, tí a ò sì bìkítà, ńṣe nìyẹn máa fi hàn pé a ò nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.—Òwe 17:17.

“Kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”—Fílípì 2:4.

Bó o ṣe lè borí àníyàn àṣejù

ÒÓTỌ́ Ọ̀RỌ̀

Àwọn èèyàn lè máa ṣàníyàn nípa ìwà àìtọ́ tí wọ́n ti hù sẹ́yìn, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tàbí ọ̀rọ̀ owó.a

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Àníyàn nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá: Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, kí àwọn kan tó di Kristẹni, wọ́n ti jẹ́ ọ̀mùtípara, alọ́nilọ́wọ́gbà, oníṣekúṣe àti olè. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Àmọ́ dípò tí wọ́n á fi máa ronú lórí irú ìgbésí ayé tí wọ́n ti gbé sẹ́yìn, ńṣe ni wọ́n jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò tọ́, wọ́n sì gbà pé Ọlọ́run á fi àánú hàn sáwọn. Sáàmù 130:4 sọ pé: “Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ [Ọlọ́run].”

Àníyàn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú: Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀.” (Mátíù 6:25, 34) Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Ohun tó ní lọ́kàn ni pé ìṣòro tá a ní lónìí nìkan ni ká ronú nípa ẹ̀. Ká má ṣe dá kún ìṣòro náà nípa dída ìṣòro ti òní pọ̀ mọ́ ti ọlà. Torí pé ìyẹn kò ní jẹ́ ká lè ronú lọ́nà tó já geere, ó sì lè mú ká kù gìrì ṣe ìpinnu. Ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé ọ̀pọ̀ nǹkan tá à ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ kì í sábà ṣẹlẹ̀.

Àníyàn nípa owó: Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan láyé ìgbàanì gbàdúrà pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀.” (Òwe 30:8) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí òun ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan tí òun ní, ìyẹn sì ni inú Ọlọ́run dùn sí. Hébérù 13:5 sọ pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí òun ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’” Owó lè tán nígbàkigbà, àmọ́ Ọlọ́run kì í já àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e kulẹ̀, tí wọ́n sì ń gbé ìgbé ayé ṣe-bí-o-ti-mọ.

“Èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.”​—Sáàmù 37:25.

Ǹjẹ́ a máa bọ́ lọ́wọ́ ṣíṣàníyàn?

OHUN TÁWỌN ÈÈYÀN SỌ

Nínú ìròyìn kan tí akọ̀ròyìn kan tó ń jẹ́ Harriet Green gbé jáde nínú ìwé ìròyìn The Guardian lọ́dún 2008, ó sọ pé: “Àkókò táwọn èèyàn ń ṣàníyàn gan-an la wà yìí.” Lọ́dún 2014, Patrick O’Connor sọ nínú ìwé ìròyìn The Wall Street Journal pé, “Àwọn ará Amẹ́ríkà ti wá ń ṣàníyàn kọjá bó ṣe yẹ báyìí.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” (Òwe 12:25) Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ “ọ̀rọ̀ rere” tó dára jù lọ tó lè múni lọ́kàn yọ̀. (Mátíù 24:14) Ìjọba Ọlọ́run ló máa ṣe gbogbo ohun tí àwa èèyàn kò lè ṣe. Ó máa mú àníyàn kúrò pátápátá àti ohun tó ń fà á, títí kan àìsàn àti ikú! Ìwé Ìṣípayá 21:4 sọ pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

“Kí Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìrètí fi ìdùnnú àti àlàáfíà gbogbo kún inú yín nípa gbígbàgbọ́ yín.”​—Róòmù 15:13.

a Ó máa dáa kí àwọn tó ní ìṣòro àníyàn tó lékenkà lọ rí dókítà. Ìwé ìròyìn Jí! kò sọ pé irú ìtọ́jú báyìí ni kéèyàn gbà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́