ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 40
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Àníyàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Àníyàn?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí ló máa ń mú kó o ṣàníyàn?
  • Ṣé ó burú kí èèyàn máa ṣàníyàn?
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Kó Gbogbo Àníyàn Rẹ lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ẹ Kó Gbogbo Àníyàn Yín Lé Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àníyàn
    Jí!—2016
  • Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Àwọn Ọkùnrin Tó Ń Ṣàníyàn Lọ́wọ́?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 40
 Ọ̀dọ́kùnrin kan ń ṣàníyàn nílé ìwé

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo ni mo ṣe lè borí àníyàn?

  • Kí ló máa ń mú kó o ṣàníyàn?

  • Ṣé ó burú kí èèyàn máa ṣàníyàn?

  • Ohun tó o lè ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Kí ló máa ń mú kó o ṣàníyàn?

Ǹjẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn tó sọ̀rọ̀ nísàlẹ̀ yìí ló máa ń rí lára tìrẹ náà?

“Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú pé: ‘Tó bá ṣẹlẹ̀ pé . . . ?’ ‘Tí jàǹbá ọkọ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa ńkọ́?’ ‘Àbí tí ọkọ̀ òfuurufú tí a wọ̀ bá lọ já ńkọ́?’ Mo máa ń ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan táwọn èèyàn kì í ronú kàn rárá.”​—Charles.

“Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣàníyàn, ṣe lọ̀rọ̀ mi dà bí nǹkan tó ń yí tí kò kúrò lójú kan. Gbogbo ara ni mo fi ń ṣiṣẹ́ síbẹ̀ kò yọ!”​—Anna.

“Táwọn èèyàn bá sọ pé Ọlọ́run bá mi ṣe é tí mo ṣì wà nílé ìwé, mo máa ń rò ó pé, ‘Wọn ò mọ̀ bí wàhálà tí mò ń dojú kọ nílé ìwé ṣe pọ̀ tó!’”​—Daniel.

“Ṣe lọ̀rọ̀ mi dà bí iná ààrò tó ń jó tí kò tí ì mọ ìkòkò tí wọ́n máa gbé sórí òun. Mi ò kì í yé ronú lórí kí ló tún fẹ́ ṣẹlẹ̀ báyìí àbí kí ló tún kù tí mo fẹ́ ṣe.”​—Laura.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Àsìkò tí Bíbélì pè ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bí àwọn àgbàlagbà ṣe ń ṣàníyàn bẹ́ẹ̀ làwọn ọ̀dọ́ náà ń ṣàníyàn.

Ṣé ó burú kí èèyàn máa ṣàníyàn?

Rárá. Kódà, Bíbélì sọ pé ó tọ̀nà kí àwọn èèyàn máa ṣàníyàn nípa bí wọ́n ṣe lè tẹ́ ẹni tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ lọ́rùn.​—1 Kọ́ríńtì 7:​32-34; 2 Kọ́ríńtì 11:28.

Ká sòótọ́, àníyàn máa ń jẹ́ kéèyàn lè tètè gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o fẹ́ ṣe ìdánwò nílé ìwé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀. Àníyàn ló máa jẹ́ kó o tètè bẹ̀rẹ̀ sí kàwé láti ọ̀sẹ̀ yìí, ìyẹn sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gba máàkì tó dáa!

Dé ìwọ̀n àyè kan àníyàn máa ń jẹ́ kí èèyàn lè sá fún ewu. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Serena sọ pé “o lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn torí pé ohun tí kò tọ́ lò ń ṣe tó sì yẹ́ kó o ṣàtúnṣe kí ẹ̀rí ọkàn rẹ lè mọ́.”​— Fi wé Jákọ́bù 5:14.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Ó dáa kó o máa ṣàníyàn tó bá ṣáà ti jẹ́ kó o lè gbé ìgbésẹ̀ lórí ohun tó tọ́.

Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ohun tí kò tọ́ lò ń rò lọ́kàn bí o ṣe ń ṣàníyàn ńkọ́?

Ọkùnrin kan ran ọ̀dọ́kùnrin kan lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà jáde kúrò níbi tó sọnù sí

Ṣe ni àníyàn máa ń jẹ́ kó dà bíi pé o sọnù sí àárín àdúgbò kan tí o kò dé rí, ṣùgbọ́n tí ẹnì kan wá fi ọ̀nà hàn ẹ́

Àpẹẹrẹ: Richard tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé: “Ọkàn mi ò kí ń balẹ̀ tí mo bá ronú lórí oríṣiríṣi ohun tó lè ṣẹlẹ̀ téèyàn bá wà lábẹ́ ipò tó nira, tí mi ò bá sì dáwọ́ ìrònú yìí dúró, màá bẹ̀rẹ̀ si ní ṣàníyàn.”

Bíbélì sọ pé, “ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” (Òwe 14:30) Àníyàn tún lè fa àìsàn sí èèyàn lára irú bíi, ẹ̀fọ́rí, òòyì, inú rírun, àti kí ọkàn èèyàn máa lù kìkì.

Kí lo lè se tó bá ṣẹlẹ̀ pé àníyàn kì í ṣe ẹ́ láǹfààní kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló ń pa ẹ́ lára?

Ohun tó o lè ṣe

  • Wò ó bóyá àníyàn tí ò ń ṣe tọ̀nà. “Ọ̀tọ̀ ni kí ojúṣe èèyàn jẹ ẹ́ lógún, ọ̀tọ̀ sì ni kí èèyàn máa ṣàníyàn jù bó ṣe yẹ lọ. Ṣe lọ̀rọ̀ ẹni tó ń ṣàníyàn dà bí ẹni tó ń pọn omi sínú apẹ̀rẹ̀, á kàn máa pọn ọ́n lọ náà ni kò ní kún. Wà á kan máa ṣàníyàn ṣá á ni kò ní yanjú ìṣòro rẹ.”​—Katherine.

    Bíbélì sọ pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?”​—Mátíù 6:27.

    Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Kàkà kí àníyàn yanjú ìṣòro rẹ ṣe ló tún máa dá kún un tàbí kó di ìṣòro rẹ.

  • Má kó ohun tó pọ̀ jù sọ́kàn. “Rò ó wò ná. Ṣé ọ̀la ni ohun tí ò ń ṣàníyàn lé máa yanjú? ṣé oṣù kan ni? ṣé ọdún kan ni? àbí ọdún márùn ún sí ìsinyìí?”​—Anthony.

    Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.”​—Mátíù 6:34.

    Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Kò bọ́gbọ́n mu láti máa ronú lórí àwọn ìṣòro tá a lè kojú lọ́jọ́ iwájú tó sì jẹ́ pẹ́ èyí tó pọ̀ jù nínú rẹ̀ ló lè má wáyé.

  • Kọ́ bí o kò ṣe ní máa ṣe kọjá agbára rẹ. “Ohun tó dára jù ni pé dé ìwọ̀n àyè kan máa múra sílẹ̀ fún àwọn ipò kan pàtó, ṣùgbọ́n máa ní in lọ́kàn pé àwọn ipò míì wà tó kọjá agbára rẹ.”​—Robert.

    Bíbélì sọ pé: “Eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, . . . bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá; nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”​—Oníwàásù 9:11.

    Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé o kò ní lè ṣe nǹkankan sí àwọn ìṣòro rẹ, ṣùgbọ́n o lè yí ojú tó o fi ń wò wọ́n padà.

  • Máa ronú lórí ohun tó ṣe pàtàkì jù. “Mo ti wá rí i pé ohun tí ìṣòro mi jẹ́ ló yẹ kí n kọ́kọ́ mọ̀ kì í ṣe àwọn nǹkan míì tí kò pọn dandan. Ó yẹ kí n mọ àwọn ìgbésẹ̀ tí mo fẹ́ gbé àti àwọn ohun tí màá fi ṣíwájú.”​—Alexis.

    Bíbélì sọ pé: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:​10.

    Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Àníyàn kì í bo àwọn kan mọ́lẹ̀ torí wọ́n mọ èyí tó yẹ kí wọ́n fi ṣíwájú nínú àwọn àníyàn wọn.

  • Bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. “Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá, àníyàn ni mo máa bá délé láti ilé ìwé, àníyàn yìí kan náà ni màá tún gbé lọ sí ilé ìwé lọ́jọ́ kejì. Àwọn òbí mi máa ń fetí sílẹ̀ bí mo bá ṣe ń sọ ohun tó ń ṣe mí. Inú mi ń dùn pé mo wọ́n wà nítòsí mi. Mo lè fọkàn tán wọn ki n sì bá wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà. Ó máa ń jẹ́ kí n lè gbara dì fún ọjọ́ kejì.”​—Marilyn.

    Bíbélì sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.”​—Òwe 12:25.

    Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Àwọn òbí ẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan lè sọ àwọn ohun tó o lè ṣe láti dín bí o ṣe ń ṣàníyàn kù.

  • Gbàdúrà. “Bí mo ṣe máa ń gbàdúrà tí mo sì máa ń sọ̀rọ̀ sókè débi tí màá máa fetí ara mi gbọ́ ti ràn mí lọ́wọ́. Ó jẹ́ kì n lè sọ ohun tí àníyàn mi jẹ́ síta dípò tí màá fi ma máa dáa rò lọ́kàn. Ó tún jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà lágbára ju àwọn àníyàn mi lọ.”​—Laura.

    Bíbélì sọ pé: “Ẹ . . . kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.”​—1 Pétérù 5:7.

    Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Àdúrà gbígbà kìí ṣe ọ̀nà tí a lè gbà yanjú ìṣòro wa fúnra wa. Ó jẹ́ ọ̀nà tí a gbà ń bá Jèhófà Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ní tààràtà, ẹni tó ṣèlérí pé: “Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.”​—Aísáyà 41:10.

Nígbà tí Àníyàn bá lágbára jù

Àwọn ọ̀dọ́ kan ń dojú kọ àníyàn tó lágbára gan an. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jenna sọ pé: “Torí pé mò ń ṣàníyàn, àìmọye ìgbà ni orí á máa fọ́ mi, tó jẹ́ pé mi ò ní lè pọkàn pọ̀, màá kàn máa sùn ni ìgbà míì sì wà tí mi ò ní rí oorun sùn, mi ò ní lè jẹun, tí ń bá sì tún máa jẹun àjẹjù ni màá tún jẹ gbogbo ìgbà ni nǹkan ń tojú sú mi. Ṣe làwọn ìṣòrò tí kò tó nǹkan máa ń dà bí òkè ńlá lójú mi.”

Tí o bá rí i pé o ò kí ń yé ṣàníyàn tàbí àníyàn tí ò ń ṣe ti pọ̀ jù, ohun tó máa dára jù ni pé kó o lọ ṣàyẹ̀wò ara rẹ nílé ìwòsàn. Ohun tí Jenna ní ti ẹ̀ ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “lẹ́yìn tí mo gba ìtọ́jú mó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tó bójú mu mo sì lè ṣèkáwọ́ ara mi tí ń bá ti fẹ́ máa ṣàníyàn.”

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ

Carissa

“Tí n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàníyàn, mo máa ń sọ ohun tí mò ń ṣàníyàn lé lórí gan-an fún Jèhófà nínú àdúrà. Ìgbà tí mo sì ti mọ pé mo ti fi ìṣòro mi síkàáwọ́ Jèhófà mo máa ń rí oorun sùn dáadáa lálẹ́ torí pé òun nìkan náà ni mo lè kó gbogbo àníyàn ìgbésí ayé mi lé.”​—Carissa.

Samantha

“Mo máa ń bi ara mi pé, ‘kí nìdí tí mò ń yọ ara mi lẹ́nu lórí àwọn nǹkan tí mi ò lè dá yanjú ní báyìí àbí tí kò ti ẹ̀ lè yanjú láéláé?’ Mo wá ronú kan ọrọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 6:27. Èyí ló ràn mí lọ́wọ́ láti gbára lé Jèhófà kí n sì fetí sí àwọn ìmọ̀ràn rẹ.”​—Samantha.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́