ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g18 No. 2 ojú ìwé 13
  • 10 Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbọ́kàn Lé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 10 Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbọ́kàn Lé
  • Jí!—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ
  • ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ
  • OHUN TÓ O LÈ ṢE
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jẹ́ Káwọn Òbí Mi Fọkàn Tán Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Ò Fi Fọkàn Tán Mi?
    Jí!—2008
  • Fífọkàntánni Ló Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Èèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Màá Fi Ní Òmìnira Sí I?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Jí!—2018
g18 No. 2 ojú ìwé 13
Ọ̀dọ́bìnrin kan ń sanwó sí báǹkì kan

Tó o bá ń gbọ́rọ̀ sí àwọn òbí ẹ lẹ́nu, ṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń san gbèsè tó o jẹ báǹkì. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á túbọ̀ máa fọkàn tán ẹ

ÀWỌN Ọ̀DỌ́

10 Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbọ́kàn Lé

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ

Tí ọ̀dọ́ kan bá fẹ́ jẹ́ ẹni tó ṣeé gbọ́kàn lé, ó gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé òfin àwọn òbí rẹ̀, kó máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, kó sì máa sọ òtítọ́. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn òbí rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti ẹni tó bá gbà á sí iṣẹ́ máa gbẹ́kẹ̀ lé e.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Lọ́pọ̀ ìgbà, bí àwọn òbí ẹ bá ṣe gbọ́kàn lé ẹ tó ni wọ́n á ṣe fún ẹ lómìnira tó.

“Tó o bá fẹ́ káwọn òbí rẹ gbọ́kàn lé ẹ, o gbọ́dọ̀ máa fi hàn nínú ìwà ẹ pé o mọ ohun tó tọ́ láti ṣe àti pé o mọ nǹkan tó ò ń ṣe, ó sì yẹ kó o máa fi hàn bẹ́ẹ̀ tó o bá wà pẹ̀lú wọn àtìgbà tó ò bá sí pẹ̀lú wọn.”​—Sarahi.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Kí ó fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn láti inú ìwà rẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”​—Jákọ́bù 3:13.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Tó o bá fẹ́ káwọn òbi rẹ máa gbọ́kàn lé ẹ, tàbí tó bá wù ẹ́ kí wọ́n túbọ̀ máa fọkàn tán ẹ, àwọn nǹkan tó o lè ṣe rèé:

Jẹ́ olóòótọ́. Tó o bá ń purọ́, kò sẹ́ni tó máa fọkàn tán ẹ. Àmó tó o bá ń sọ òótọ́ ní gbogbo ìgbà, kódà nígbà tó o bá ṣe àṣìṣe, àwọn èèyàn máa fọkàn tán ẹ.

“Ó rọrùn láti jẹ́ olóòótọ́ tó o bá ń ṣe nǹkan dáadáa. Àmọ́ kì í rọrùn tó o bá ṣe nǹkan tó lè mú káwọn èèyàn máa fojú burúkú wò ẹ́. Síbẹ̀, tó o bá gbìyànjú láti jẹ́ olóòótọ́, àwọn èèyàn máa túbọ̀ fọkàn tán ẹ.”​—Caiman.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “A dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”​—Hébérù 13:18.

Jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn agbanisíṣẹ́ ló sọ pé “ẹni táwọn bá fẹ́ gbà sí iṣẹ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán.” Tó o bá jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán nísìnyí, á ṣe ẹ́ láàǹfààní tó o bá dàgbà.

“Àwọn òbí mi máa ń mọ̀ tí mo bá ṣe ohun tó yẹ kí n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tí mo bá ṣe àwọn iṣẹ́ ilé láì jẹ́ pé wọ́n sọ fún mi, inú wọn máa ń dùn. Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán mi.”​—Sarah.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìfohùnṣọ̀kan rẹ, mo sì mọ̀ pé ìwọ yóò tilẹ̀ ṣe ju àwọn ohun tí mo wí.’​—Fílémónì 21.

Jẹ́ onísùúrù. Ó lè rọrùn fún àwọn èèyàn láti tètè kíyè sí bó o ṣe ń dàgbà, àmọ́ ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò kí wọ́n tó lè mọ̀ bóyá o ní ìwà àgbà, o sì mọ ohun tó ò ń ṣe.

“Kì í ṣe ohun tó o bá ṣe lẹ́ẹ̀kàn ṣoṣo ló máa jẹ́ kí àwọn òbí rẹ àti àwọn míì fọkàn tán ẹ. Àmọ́ tó o bá ń hùwà dáadáa nìgbà gbogbo, tó o sì fi hàn pé o mọ ohun tí ò ń ṣe, wọ́n á fọkàn tán ẹ.”​—Brandon.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Ẹ fi ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.’ ​—Kólósè 3:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́