ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀
Ìbànújẹ́ Ńlá Ni Ikú Èèyàn Ẹni Máa ń fà
“Lẹ́yìn ọdún mọ́kàndínlógójì [39] tí èmi àti Sophiaa ti ṣègbéyàwó, àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ kan gbẹ̀mí ẹ̀. Tẹbí-tọ̀rẹ́ dúró tì mí, mo sì tún ń wá nǹkan ṣe kó má bàa di pé mo kàn jókòó gẹlẹtẹ. Àmọ́, odindi ọdún kan ni ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára fi dà mí láàmú. Ìbànújẹ́ sorí mi kodò débi pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ara mi kì í balẹ̀. Kódà ní báyìí tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọdún mẹ́ta tó ti kú, inú mi máa ń ṣàdédé bà jẹ́ gan-an lẹ́kọ̀ọ̀kan.”—Kostas.
Ǹjẹ́ èèyàn ẹ kan ti kú rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kostas yìí ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà. Bóyá ni ohun míì wà tó ń fa ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára bí ikú ọkọ, aya, ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ ẹni. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń ṣèwádìí nípa ìrora táwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa ń ní gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé The American Journal of Psychiatry sọ pé “kò sóhun míì tó ń bani nínú jẹ́ tó ikú èèyàn ẹni.” Tí ìbànújẹ́ tó lagbára bá bá ẹnì kan tí èèyàn rẹ̀ kú, onítọ̀hún lè máa ronú pé: ‘Ṣé bí nǹkan á ṣe máa rí lọ rèé? Ṣé mo ṣì lè láyọ̀? Báwo ni mo ṣe lè rí ìtura?’
A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú Jí! yìí. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó bá jẹ́ pé èèyàn rẹ kan ṣẹ̀ṣẹ̀ kú lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àwọn àpilẹkọ tó kù máa sọ àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.
A gbà gbọ́ pé ohun tá a máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ báyìí á tu àwọn tó bá ń ṣọ̀fọ̀ nínú, á sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè rí ìtura.
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí.