ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 2 ojú ìwé 6-7
  • 1. Ṣé Ọlọ́run Ló Lẹ̀bi Ìyà Tó Ń Jẹ Wá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1. Ṣé Ọlọ́run Ló Lẹ̀bi Ìyà Tó Ń Jẹ Wá?
  • Jí!—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì
  • Ronú Lórí Èyí
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2020
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ìbéèrè Kẹta: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Jẹ́ Kí Ìyà Máa Jẹ Mí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 2 ojú ìwé 6-7
Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan mú Bíbélì dání bó ṣe ń wàásù fáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì.

1. Ṣé Ọlọ́run Ló Lẹ̀bi Ìyà Tó ń jẹ Wá?

Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì

Ọ̀pọ̀ èèyàn ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run torí wọ́n gbà gbọ́ pé òun ló ń fìyà jẹ wá.

Ronú Lórí Èyí

Lọ́nà kan tàbí òmíì, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti kọ́ àwọn èèyàn pé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ wá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń sọ pé:

  • Àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lójijì jẹ́ ìyà tí Ọlọ́run fi ń jẹ wá.

  • Àwọn ọmọdé ń kú nítorí Ọlọ́run nílò àwọn áńgẹ́lì sí i lọ́run.

  • Ọlọ́run ń gbè sẹ́yìn àwọn kan nínú ogun, èyí sì ń fa ìyà tó pọ̀.

Àmọ́, ṣé kì í ṣe irọ́ ni ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń sọ nípa Ọlọ́run? Ṣé kì í ṣe pé Ọlọ́run ti kẹ̀yìn sí wọn?

TÓ O BÁ FẸ́ MỌ̀ SÍ I

Wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ó wà lórí ìkànnì jw.org.

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá.

Tó bá jẹ́ òun ló ń fà á, ìyẹn ta ko àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí Bíbélì sọ. Bí àpẹẹrẹ:

“[Ọlọ́run] ń ṣe ìdájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀. . . . Olódodo àti adúróṣinṣin ni.”​—DIUTARÓNÓMÌ 32:4.

“Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!”​—JÓÒBÙ 34:10.

‘Olódùmarè kì í yí ìdájọ́ po.’​—JÓÒBÙ 34:12.

Ọlọ́run ò tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀sìn tó ń parọ́ mọ́ ọn.

Lára irú ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ làwọn tó ń kọ́ni pé Ọlọ́run ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá àtàwọn ẹ̀sìn tó ń lọ́wọ́ nínú ogun àti ìwà ipá.

“Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ ní orúkọ mi. Mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn, mi ò sì bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké àti . . . ẹ̀tàn ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.”​—JEREMÁYÀ 14:14.

Jésù dẹ́bi fáwọn ẹ̀sìn tó ń ṣẹ̀tàn.

“Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ló máa wọ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tó wà ní ọ̀run nìkan ló máa wọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀ máa sọ fún mi ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Olúwa, Olúwa, ṣebí a fi orúkọ rẹ sọ tẹ́lẹ̀, a fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a sì fi orúkọ rẹ ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára?’ Àmọ́, màá sọ fún wọn pé: ‘Mi ò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin arúfin!’” ​—MÁTÍÙ 7:21-23.

Ṣé Ọlọ́run Ló Lẹ̀bi Ìyà Tó Ń Jẹ Wá?

Ká sọ pé bàbá kan ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáadáa, ó sì ń pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ yàyàkuyà, ó kó jáde nílé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwàkiwà. Ṣé bàbá yẹn ló lẹ̀bi ìwà burúkú tọ́mọ yẹn ń hù? Tọ́mọ náà bá ń jèrè iṣẹ́ burúkú ọwọ́ rẹ̀, ṣó lè sọ pé bàbá òun ló fà á? Bákan náà, a ò lè sọ pé Ọlọ́run ló lẹ̀bi ìyà tó ń jẹ wá.

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwa la lẹ̀bi ìyà tó ń jẹ wá?

Wo ìbéèrè 2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́