4. Ṣé Látìbẹ̀rẹ̀ Ni Ọlọ́run Ti Dá Wa Pé Ká Máa Jìyà?
Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì
Tá a bá mọ ìdáhùn ìbéèrè yìí, á mú kí ìgbésí ayé wa máa dáa sí i.
Ronú Lórí Èyí
Ṣó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run tó dá ayé tó rẹwà yìí ló ń fìyà jẹ wá?
Torí ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, àwọn tí kò lẹ́sìn máa ń sọ pé ìkà ni Ọlọ́run tàbí kí wọ́n tiẹ̀ sọ pé kò sí Ọlọ́run rárá. Wọ́n gbà pé ọ̀kan nínú ohun mẹ́ta yìí ló fà á tí ìyà fi ń jẹ aráyé (1) Ọlọ́run ò lágbára láti fòpin sí ìyà (2) Ọlọ́run ò fẹ́ láti fòpin sí i (3) Ọlọ́run ò sí.
Ṣé àwọn nǹkan tó fà á tá a fi ń jìyà nìyẹn lóòótọ́?
TÓ O BÁ FẸ́ MỌ̀ SÍ I
Wo fídíò Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì? Ó wà lórí ìkànnì jw.org.
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ọlọ́run ò dá wa pé ká máa jìyà.
Ó fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa.
“Kò sí ohun tó dáa fún [èèyàn] ju pé kí wọ́n máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ayé wọn, àti pé kí kálukú máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—ONÍWÀÁSÙ 3:12, 13.
Nígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn, ó fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò.
Kò fẹ́ kí àwọn àti àtọmọdọ́mọ wọn máa jìyà.
“Ọlọ́run sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.’” —JẸ́NẸ́SÍSÌ 1:28.
Àwọn òbí wa àkọ́kọ́ mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run.
Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi fa ọ̀pọ̀ ìyà sórí ara wọn àti gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn.
“Bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé, tí ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn torí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—RÓÒMÙ 5:12.a
Ọlọ́run ò dá àwa èèyàn pé ká máa darí ara wa láìsí ìtọ́sọ́nà rẹ̀.
Bí Ọlọ́run kò ṣe dá àwa èèyàn láti máa gbé lábẹ́ omi, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣe dá wa láti máa darí ara wa.
“Kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—JEREMÁYÀ 10:23.
Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa jìyà.
Ìgbé ayé ìrọ̀rùn ló fẹ́ ká máa gbé, kò fẹ́ ká níṣòro rárá.
“Ká ní o fetí sí àwọn àṣẹ mi ni! Àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò.”—ÀÌSÁYÀ 48:18.
a Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ṣẹ̀” kì í tọ́ka sí ìwà burúkú tẹ́nì kan hù nìkan, ó tún ń tọ́ka sí ohun tí gbogbo èèyàn ti jogún.