ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 2 ojú ìwé 14-15
  • 5. Ṣé Ìyà Máa Dópin?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 5. Ṣé Ìyà Máa Dópin?
  • Jí!—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì
  • Ronú Lórí Èyí
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ìyà
    Jí!—2015
  • Ìbéèrè Kẹta: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Jẹ́ Kí Ìyà Máa Jẹ Mí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ojútùú Tó Kárí Ayé Sí Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 2 ojú ìwé 14-15
Ìdílé kan ń gbafẹ́ níbi odò. Wọ́n ń rẹ́rìn-⁠ín, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn.

5. Ṣé Ìyà Máa Dópin?

Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì

Tá a bá gbà pé ìyà máa dópin, ìrètí tá a ní yìí á mú kí ìgbésí ayé wa dáa sí i, á sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.

Ronú Lórí Èyí

Ó wu ọ̀pọ̀ èèyàn láti fòpin sí ìyà, àmọ́ agbára wọn ò gbé e. Kíyè sí àwọn nǹkan yìí:

Ìmọ̀ ìṣègùn ti tẹ̀ síwájú gan-an lóòótọ́, àmọ́ . . .

  • Àrùn ọkàn ló ṣì ń pa èèyàn tó pọ̀ jù lọ.

  • Àrùn jẹjẹrẹ ń pa àìmọye èèyàn lọ́dọọdún.

  • Bákan náà, nínú ìwé ìròyìn Frontiers in Immunology, ọ̀jọ̀gbọ́n David Bloom sọ́ pé: “Àwọn àrùn tó ń ranni tó ti wà tipẹ́, tó sì dà bíi pé wọ́n ti lọ tẹ́lẹ̀ tún ti wá ń yọjú léraléra, wọ́n sì ń han aráyé léèmọ̀.”

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè kan ní ọrọ̀ púpọ̀ . . .

  • Àìmọye ọmọdé ló ń kú lọ́dọọdún, àwọn tó wà ní agbègbè àwọn tálákà ló sì ń jìyà náà jù lọ.

  • Àìmọye èèyàn ló ń gbé níbi tí kò sí ètò ìmọ́tótó tó dáa.

  • Àìmọye èèyàn ni kò ní omi tó mọ́.

Pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń tẹnu mọ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó . . .

  • Títí di báyìí, wọ́n ṣì ń ta èèyàn ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀. Àwọn ijọba kan kò fìyà jẹ àwọn olubi náà. Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé ohun tó fà á ni pé àwọn orílẹ̀-èdè náà “kò mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ tàbí wọn ò lágbára láti mú àwọn ọ̀daràn náà.”

    TÓ O BÁ FẸ́ MỌ̀ SÍ I

    Wo fídíò Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run? Ó wà lórí ìkànnì jw.org.

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ọlọ́run ń bójú tó wa.

Ó máa ń dùn ún tá a bá ń jẹ̀rora, tínú wa sì bà jẹ́.

“[Ọlọ́run] kò gbójú fo ìyà tó ń jẹ ẹni tí ara ń ni, kò sì ṣàì ka ìpọ́njú rẹ̀ sí; kò gbé ojú rẹ̀ pa mọ́ fún un.”​—SÁÀMÙ 22:24.

“Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”​—1 PÉTÉRÙ 5:7.

Ìyà ṣì máa dópin.

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe gbogbo ohun tó ṣèlérí fún wa.

“Ọlọ́run . . . máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​—ÌFIHÀN 21:3, 4.

Ọlọ́run máa mú ohun tó ń fa ìyà tó ń jẹ wá kúrò.

Ó máa ṣe é nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀, èyí tó gbé kalẹ̀ lọ́run.

“Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé. A ò ní gbé ìjọba yìí fún èèyàn èyíkéyìí míì. . . . Òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.”​—DÁNÍẸ́LÌ 2:44.

Ṣé Ìyà Máa Dópin?

Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa dópin. Àmọ́ kì í ṣe nípasẹ̀ agbára èèyàn. Ìjọba èèyàn kàn ń gbìyànjú ni, Ọlọ́run nìkan ló lè mú gbogbo ohun tó ń fa ìyà kúrò. Ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́