ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 3 ojú ìwé 6-7
  • Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò
  • Jí!—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro
  • Ìlànà Bíbélì
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò
  • Ohun To O Lè Ṣe
  • Ẹ̀mí Ìfọ̀rọ̀rora- Ẹni-Wò—Ń Jẹ́ Ká Ní Ojú Àánú àti Ìyọ́nú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Ṣé Ọlọ́run Mọ Bí Nǹkan Ṣe Máa Ń Rí Lára Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
  • Ìdílé Aláyọ̀ àti Ọ̀rẹ́ Àtàtà
    Jí!—2019
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 3 ojú ìwé 6-7
Ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù kan àti ọmọ ilẹ̀ Íńdíà kan jókòó ti ara wọn nínú ọkọ̀ òfurufú. Inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe jọ ń sọ̀rọ̀.

Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò

Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro

Tó bá jẹ́ pé báwọn kan ṣe yàtọ̀ sí wa là ń rò ṣáá, ìyàtọ̀ tá a rí yẹn lè wá di àbùkù. Àá wá máa ṣe ẹ̀tanú sáwọn tó yàtọ̀ sí wa torí pé a gbà pé èèyàn tí kò dáa ni wọ́n. Èrò tí kò dáa tá a ní nípa wọn yìí á wá mú kó ṣòro fún wa láti máa gba tiwọn rò. Èyí fi hàn pé tá ò bá lẹ́mìí ìgbatẹnirò, ó lè mú ká ní ẹ̀tanú sáwọn èèyàn tàbí ká kórìíra wọn.

Ìlànà Bíbélì

“Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.”​—RÓÒMÙ 12:15.

Kí la rí kọ́? Ohun tí ìlànà Bíbélì yìí ń kọ́ wa ni pe ká máa gba tàwọn èèyàn rò. Ohun tí ìgbatẹnirò túmọ̀ sí ni pé kéèyàn fi ara ẹ̀ sípò àwọn ẹlòmíì, kó sì fi ọ̀rọ̀ wọn ro ara ẹ̀ wò.

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò

Tá a bá fi ara wa sípò ẹlòmíì, àá rí bí ọ̀rọ̀ àwa àti ẹni náà ṣe jọra. A lè wá rí i pé bákan náà ni nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Ta a bá ń gba tàwọn ẹlòmíì rò, á jẹ́ ká rí i pé inú ìdílé kan náà ni gbogbo èèyàn ti wá láìka ibi tí wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà sí. Tá a bá ń ronú lórí bí ọ̀rọ̀ wa ṣe jọra, ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa fojú burúkú wò àwọn èèyàn.

Tá a bá ń gba tàwọn èèyàn rò á jẹ́ ká lè máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Anne-Marie tó wá láti Senegal máa ń fojú burúkú wo àwọn èèyàn kan táwọn èèyàn ò kà sí. Ó ṣàlàyé pé ìgbà tóun bẹ̀rẹ̀ sí í gba tiwọn rò lèrò òun yí pa dà, ó ní: “Nígbà tí mo rí ìyà tó ń jẹ àwọn tí wọn ò kà sí yìí, mo bi ara mi pé, ‘Báwo ló ṣe máa rí lára mi tó bá jẹ́ pé èmi ni irú ìyà yìí ń jẹ?’ ” Èyí mú kí n wá rí i pé mi ò sàn jù wọ́n lọ àti pé gbogbo ohun tí mo ní kì í ṣe mímọ̀-ọ́n-ṣe mi. Ó dájú pé tá a bá ń sapá láti mọ ìṣòro táwọn kan ní, ńṣe làá máa bá wọn dárò, a ò ní máa dá wọn lẹ́jọ́.

Ohun To O Lè Ṣe

Tó o bá ń fojú burúkú wo àwọn ẹ̀yà kan, sapá láti wo bí ọ̀rọ̀ ìwọ àtàwọn èèyàn náà ṣe jọra. Bí àpẹẹrẹ, fojú inú wo bó ṣe máa rí lára wọn:

Tá a bá ń gba tàwọn ẹlòmíì rò, á jẹ́ ká rí i pé inú ìdílé kan náà ni gbogbo èèyàn ti wá

  • tí wọ́n bá ń jẹun pẹ̀lú ìdílé wọn

  • tí wọ́n bá parí iṣẹ́ àṣekára ọjọ́ kọ̀ọ̀kan

  • tí wọ́n bá wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn

  • tí wọ́n bá ń gbọ́ orin tí wọ́n fẹ́ràn gan-an

Lẹ́yìn náà, kó o wá fi ara ẹ sípò wọn. Bi ara ẹ pé:

  • ‘Báwo ló ṣe máa rí lára mi tẹ́nì kan bá fojú ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan wò mí?’

  • ‘Báwo ló ṣe má rí lára mi táwọn èèyàn bá dá mi lẹ́bi láì tíì mọ irú ẹni tí mo jẹ́?’

  • ‘Tó bá jẹ́ pé èmi ni mo wá látinú ẹ̀yà táwọn èèyàn ń fojú burúkú wò yẹn, irú ìwà wo ni màá fẹ́ káwọn èèyàn máa hù sí mi?’

Ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù àti ọmọ ilẹ̀ Íńdíà kan náà yẹn ń fi àwòrán han ara wọn nípa àwọn ibi tọ́rọ̀ wọn ti jọra, ìyẹn ìdílé, eré ìdárayá àti iṣẹ́ wọn.

Ohun Tí Ẹnì Kan Sọ: Robert (Singapore)

“Nígbà kan, èrò mi nípa àwọn odi ni pé wọ́n jẹ́ ẹ̀dá tọ́rọ̀ wọn ò bá tayé mu, wọn ò mọ nǹkan kan, wọ́n sì máa ń bínú lódìlódì. Torí náà, ńṣe ni mo máa ń sá fún wọn. Àmọ́, mi ò rò ó rárá pé ẹ̀tanú ló jẹ́ kí n nírú èrò yẹn, torí pé mi ò kúkú ṣèkà fún wọn.

“Nígbà tí mo fọ̀rọ̀ àwọn odi ro ara mi wò ni ẹ̀tanú tí mo ní sí wọn tó kúrò lọ́kàn mi. Bí àpẹẹrẹ, ohun tó jẹ́ kí n gbà pé àwọn odi ò mọ nǹkan kan ni pé tí mo bá ń bá wọn sọ̀rọ̀, ńṣe ni wọ́n á kàn máa wò mí duu. Torí náà, mo wá ronú nípa bó ṣe máa rí lára mi tẹ́nì kan bá ń bá mi sọ̀rọ̀ àmọ́ tí mi ò gbọ́ torí pé odi ni mí. Ó dájú pé màá kàn máa wò duu náà ni! Tí mo bá tiẹ̀ fi ẹ̀rọ téèyàn fi ń gbọ́ràn sétí, ó ṣì máa hàn lójú mi pé ‘ohun tẹ́ni náà ń sọ ò yé mi.’ Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé kì í ṣọ̀rọ̀ pé ohun tẹ́ni yẹn ń sọ ò yé mi, mi ò tiẹ̀ gbọ́ rárá ni.

“Nígbà tí mo fi ara mi sípò àwọn odi, ńṣe ni gbogbo ìkórìíra ti mo ní sí wọn pòórá.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́