MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò
Kéèyàn fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò gba pé kẹ́ni náà gbìyànjú láti lóye bí ẹnì kan ṣe ń ronú, ìmọ̀lára tẹ́ni náà ní, ohun tó kà sí pàtàkì àti ohun tó ń jẹ ẹni náà lọ́kàn. Àwọn èèyàn máa mọ̀ tá a bá gba tiwọn rò, torí wọ́n á rí i pé ó wù wá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Tá a bá ń fọ̀rọ̀ ro ara wa wò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ṣe là ń fara wé Jèhófà tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì ń tọ́jú wa, ìyẹn á sì mú káwọn èèyàn wá sìn ín.—Flp 2:4.
Tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nìkan kọ́ ló yẹ ká máa fọ̀rọ̀ àwọn míì ro ara wa wò, ó tún gbọ́dọ̀ hàn lójú wa, nínú ìwà wa, bá a ṣe ń sọ̀rọ̀, bá a ṣe ń tẹ́tí sáwọn míì àti bá a ṣe ń fara ṣàpèjúwe. Tá a bá ń ronú nípa bá a ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́, ìyẹn máa fi hàn pé a gba tiẹ̀ rò. Àá ronú nípa bí nǹkan ṣe rí fẹ́ni náà, ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí àtohun tó gbà gbọ́. Àá fún un láwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́, àá sì pèsè ìrànlọ́wọ́ tó nílò, àmọ́ a ò ní fi dandan mú un pé kó yí èrò ẹ̀ pa dà. Táwọn èèyàn bá fi ìmọ̀ràn tá a fún wọn sílò, àá túbọ̀ láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀—TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ—MÁA FỌ̀RỌ̀ RO ARA Ẹ WÒ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ni Neeta ṣe gba ti Jade rò nígbà tí Jade pẹ́ dé?
Báwo ni Neeta ṣe gba ti Jade rò nígbà tí Jade sọ pé òun ò ní lè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́?
Tá a bá ń gba tàwọn èèyàn rò, ó máa wù wọ́n láti wá sin Jèhófà
Báwo ni Neeta ṣe gba ti Jade rò nígbà tí Jade sọ pé iṣẹ́ pọ̀ fóun láti ṣe, òun ò sì mọ bóun ṣe lè yanjú ẹ̀?