ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 3 ojú ìwé 12-13
  • Máa Fìfẹ́ Hàn Sáwọn Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fìfẹ́ Hàn Sáwọn Èèyàn
  • Jí!—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro
  • Ìlànà Bíbélì
  • Ohun Tó O Lè Ṣe
  • Wọ́n Borí Ìkórìíra
    Jí!—2020
  • Ṣé O Ní Ìkórìíra?
    Jí!—2020
  • Mo Fẹ́ Jà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn
    Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
  • Ìgbà Wo Ni Ayé Yìí Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀tanú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 3 ojú ìwé 12-13
Obìnrin ọmọ ilẹ̀ Íńdíà kan di ìyá àgbàlagbà kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù mú bí wọn ṣe jọ ń gun àtẹ̀gùn ilé, ó sì bá a gbé nǹkan tó lọ rà lọ́jà.

Máa Fìfẹ́ Hàn Sáwọn Èèyàn

Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro

Ẹ̀tanú àti ìkórìíra kì í tètè kúrò lọ́kàn èèyàn. Bó ṣe máa ń gba àkókò àti ìsapá láti mú kòkòrò àrùn kúrò lára èèyàn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń gba àkókò àti ìsapá kí ìkórìíra tó lè kúrò lọ́kàn ẹni. Kí lo máa ṣe láti mú ẹ̀tanú àti ìkórìíra kúrò lọ́kàn rẹ?

Ìlànà Bíbélì

Collage: 1. Ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Éṣíà kan di ilẹ̀kùn mú fún ọkùnrin adúláwọ̀ kan tó gbé ife kọfí lọ́wọ́. 2. Ọkùnrin adúláwọ̀ yẹn fún àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ní kọfí, títí kan obìnrin ọmọ ilẹ̀ Íńdíà tá a sọ lẹ́ẹ̀kan.

“Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”​—KÓLÓSÈ 3:14.

Kí la rí kọ́? Tá a bá ń ṣohun rere sáwọn èèyàn, á mú ká wà níṣọ̀kan. Bó o bá ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀tanú àti ìkórìíra á máa kúrò lọ́kàn rẹ. Bó o bá ṣe ń nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa ní èrò tó dáa nípa wọn.

Ohun Tó O Lè Ṣe

Collage: 1. Obìnrin ọmọ ilẹ̀ Íńdíà kan di ìyá àgbàlagbà kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù mú bí wọn ṣe jọ ń gun àtẹ̀gùn ilé, ó sì bá a gbé nǹkan tó lọ rà lọ́jà. 2. Ìyá àgbàlagbà tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù yẹn gbé bisikí ìtì wá fún aráalé rẹ̀, ìyẹn ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Éṣíà tá a sọ lẹ́ẹ̀kan.

Ronú nípa àwọn ọ̀nà tó o lè gbà fìfẹ́ hàn sáwọn tó ò ń fojú burúkú wò. Kò dìgbà tó o bá ṣe àwọn nǹkan ńlá. Gbìyànjú kó o ṣe ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ohun yìí:

Tó o bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, kódà láwọn ọ̀nà kéékèèké, ìkórìíra máa kúrò lọ́kàn ẹ

  • O lè di ilẹ̀kùn mú fún wọn tàbí kó o dìde kí ọ̀kan lára wọn lè jókòó sáyè rẹ nínú ọkọ̀ èrò tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sáyè ìjókòó mọ́.

  • Gbìyànjú láti máa bá wọn sọ̀rọ̀ bí wọn ò tiẹ̀ lè sọ èdè rẹ dáadáa.

  • Ní sùúrù fún wọn tí wọ́n bá ṣe nǹkan tí kò yé ẹ.

  • Máa bá wọn kẹ́dùn tí wọ́n bá ń sọ ìṣòro wọn fún ẹ.

Ohun Tí Ẹnì Kan Sọ: Nazaré (Guinea-Bissau)

“Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mo kórìíra àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè wa. Wọ́n sọ fún mi pé ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń parọ́ gbowó ìrànwọ́ lọ́wọ́ ìjọba àti pé ọ̀daràn ni wọ́n. Ìyẹn mú kó ṣòro fún mi láti máa fojú èèyàn gidi wò wọ́n. Mi ò tiẹ̀ rò ó rárá pé ẹ̀tanú ló mú kí n nírú èrò yẹn sí wọn, torí pé bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń fojú burúkú wò wọ́n náà nìyẹn.

“Àmọ́ nígbà tó yá, mo wá rí i pé ẹ̀tanú ló mú kí n máa fójú burúkú wo àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ló mú kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn. Ní báyìí, mi ò kì í sá fún wọn mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo máa ń kí wọn, mo sì máa ń bá wọn sọ̀rọ̀. Mo sapá láti mọ̀ wọ́n lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ní báyìí, mo ti ń fojú tó dáa wò wọ́n, mi ò sì fura sí wọn mọ́.”

“Mo Fẹ́ Jà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn”

Rafika Morris.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Rafika dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ajìjàgbara láti gbógun ti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìwà ìrẹ́jẹ. Àmọ́, nígbà tó lọ sí àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó wá rí ìṣọ̀kan tó ti ń wá tipẹ́.

Wo fídíò Rafika Morris: Mo Fẹ́ Jà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Wá fídíò náà lórí ìkànnì jw.org.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́