ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g21 No. 2 ojú ìwé 10-12
  • Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ọkọ àti Aya?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ọkọ àti Aya?
  • Jí!—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
  • OHUN TÓ O LÈ ṢE
  • Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Gbà Ẹ́ Lọ́kàn
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Fi Iṣẹ́ Sílẹ̀ “Síbi Iṣẹ́“
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ẹ Máa Wáyè fún Ara Yín
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ohun Táwọn Tọkọtaya Àgbàlagbà Lè Máa Ṣe Tí Wọn Ò Fi Ní Kọra Wọn Sílẹ̀
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
Àwọn Míì
Jí!—2021
g21 No. 2 ojú ìwé 10-12
Ọkùnrin kan wà níbi tó ti fẹ́ wọ ọkọ̀ òfúrufú, ó ń fi fídíò bá ìyàwó ẹ̀ tó wà nílé sọ̀rọ̀.

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe Fún Ọkọ Àti Aya?

Táwọn tọkọtaya bá lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lọ́nà tó dáa, ó lè mú kí ìfẹ́ àárín wọn túbọ̀ lágbára. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń jẹ́ kí tọkọtaya bá ara wọn sọ̀rọ̀ lóòrèkóòrè, bí wọ́n ò tiẹ̀ sí nítòsí ara wọn.

Àmọ́, àwọn tọkọtaya kan máa ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lọ́nà tí kò dáa, ìyẹn sì ti mú kí wọ́n . . .

  • má ṣe ráyè fún ara wọn mọ́.

  • máa gbé iṣẹ́ wálé láìjẹ́ pé ó pọn dandan.

  • máa fura sí ara wọn, kí wọ́n má sì fọkàn tán ara wọn mọ́.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ọkọ àtìyàwó dùbúlẹ̀ sórí bẹ́ẹ̀dì lọ́gànjọ́ òru, kálukú ń tẹ fóònù ẹ̀.

ÀKÓKÒ TẸ́ Ẹ FI WÀ PA PỌ̀

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Michael sọ pé: “Nígbà míì témi àtìyàwó mi bá wà pa pọ̀, kì í ráyè tèmi rárá, torí fóònù ló kàn máa ń tẹ̀ ní tiẹ̀, á sì máa sọ pé, ‘Mi ò tíì ráyè wo fóònù yìí látàárọ̀.’ ” Lórí ọ̀rọ̀ yìí, baálé ilé kan tó ń jẹ́ Jonathan sọ pé: “Ọkọ àtìyàwó lè máa gbé pọ̀ lóòótọ́, àmọ́ ó lè dà bíi pé ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń gbé.”

RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọ̀rọ̀ àti ìpè tó ń wọlé sórí fóònù ẹ kì í jẹ́ kó o ráyè gbọ́ ti ọkọ tàbí ìyàwó ẹ?​—ÉFÉSÙ 5:33.

IṢẸ́

Iṣẹ́ àwọn kan máa ń gba pé kí wọ́n máa gba ìpè àti lẹ́tà lórí fóònù wọn lóòrèkóòrè, kódà lẹ́yìn tí wọ́n ti kúrò níbiṣẹ́. Àmọ́, ó ṣì ṣòro fáwọn kan tí iṣẹ́ wọn ò le tó bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ kọ́rọ̀ iṣẹ́ wọn mọ síbi iṣẹ́. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Lee sọ pé: “Nígbà tí mo bá wà pẹ̀lú ìyàwó mi, ó ti mọ́ mi lára kí n máa wo gbogbo ọ̀rọ̀ àti lẹ́tà tó ń wọlé sórí fóònù mi láti ibiṣẹ́.” Ìyàwó ilé kan tó ń jẹ́ Joy sọ pé: “Àtilé ni mo ti ń ṣiṣẹ́, torí náà, ó máa ń ṣòro fún mi láti ṣíwọ́ lásìkò. Téèyàn ò bá ṣọ́ra, kò ní ráyè fún ẹnì kejì ẹ̀.”

RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé o máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀?​—LÚÙKÙ 8:18.

JẸ́ OLÓÒÓTỌ́

Ìwádìí kan fi hàn pé àwọn kan máa ń fura sí ohun tí ẹnì kejì wọn ń ṣe lórí ìkànnì àjọlò, ìyẹn sì máa ń dá ìjà sílẹ̀ láàárín wọn lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn kan jẹ́wọ́ pé àwọn kì í jẹ́ kẹ́nì kejì àwọn róhun táwọn ń gbé sórí ìkànnì.

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ewu púpọ̀ ló wà lórí ìkànnì àjọlò, ó sì lè mú káwọn tọkọtaya tètè ṣe ìṣekúṣe. Abájọ táwọn agbẹjọ́rò tó ń rí sọ́rọ̀ ìkọ̀sílẹ̀ fi sọ pé wàhálà tí ìkannì àjọlò ń dá sílẹ̀ láàárín àwọn tọkọtaya kì í ṣe kékeré, ìyẹn ló sì fà á tí ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya fi ń kọ ara wọn sílẹ̀ lóde òní.

RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣó o máa ń fàwọn ọ̀rọ̀ tó o fi ń ránṣẹ́ sẹ́ni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹ pa mọ́, kí ẹnì kejì ẹ má bàa rí i?​—ÒWE 4:23.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

FI OHUN TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́

Tẹ́nì kan bá wà tí kì í fi bẹ́ẹ̀ jẹun, ara onítọ̀hún ò ní le dáadáa. Bọ́rọ̀ tọkọtaya ṣe rí náà nìyẹn, tí wọn ò bá wáyè láti máa gbọ́ ti ara wọn, wọ́n máa níṣòro.​—Éfésù 5:​28, 29.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”​—FÍLÍPÌ 1:10.

Kí ẹ̀yin ọkọ àti aya jọ jíròrò àwọn tó yẹ kẹ́ ẹ ṣe nínú àwọn àbá yìí tàbí kẹ́ ẹ kọ èyí tẹ́yin fúnra yín ronú kàn, tí kò ní jẹ́ kí ẹ̀rọ ìgbàlódé ba àárín yín jẹ́.

  • A fẹ́ jọ máa jẹun pọ̀, ó kéré tán ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́

  • A fẹ́ ya àwọn àsìkò kan sọ́tọ̀ tá a máa fi wà pa pọ̀, tá ò sì ní lo fóònù tàbí kọ̀ǹpútà wa

  • A fẹ́ ṣètò àwọn ọjọ́ kan táwa méjèèjì á jọ máa jáde láti gbádùn ara wa

  • A ò ní máa fi fóònù wa sí tòsí tá a bá ti fẹ́ sùn lálẹ́

  • A fẹ́ máa pa fóònù tàbí kọ̀ǹpútà wa fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lójúmọ́, ká lè bára wa sọ̀rọ̀ láìsí ìdíwọ́

  • A fẹ́ yan àkókò kan lójúmọ́ tá ò ni máa tan Íńtánẹ́ẹ̀tì wa

ÌBÉÈRÈ TÁWỌN TỌKỌTAYA MÁA DÁHÙN

Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín kọ́kọ́ ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí, lẹ́yìn náà, kẹ́yin méjèèjì wá jọ dáhùn wọn.

  • Àwọn ọ̀nà wo lẹ lè máa gbà lo ẹ̀rọ ìgbàlódé tí àjọṣe yín á fi túbọ̀ máa lágbára?

  • Lérò tìẹ, báwo ni ẹ̀rọ ìgbàlódé ṣe máa ń dí yín lọ́wọ́ tó tẹ́ ẹ bá wà pa pọ̀?

  • Àwọn àtúnṣe wo ló yẹ kẹ́yin méjèèjì ṣe nínú ọ̀nà tẹ́ ẹ̀ ń gbà lo ẹ̀rọ ìgbàlódé?

  • Ṣé ó ṣòro fún ẹ láti fọ̀rọ̀ iṣẹ́ mọ síbi iṣẹ́? Ṣé ẹnì kejì ẹ máa fara mọ́ ohun tó o sọ yìí?

  • Bó o ṣe ń retí pé kí ẹnì kejì ẹ máa wáyè fún ẹ, báwo lo ṣe lè fi hàn pé ò ń gba tiẹ̀ rò?

    ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”​—1 KỌ́RÍŃTÌ 10:24.

Jason àti Alexandra.

“Àtilé ni mo ti ń ṣiṣẹ́, torí náà, mo ti ṣètò ìgbà tí mo máa ń ṣíwọ́ iṣẹ́, kì í sì í yẹ̀. Mo tún ṣètò ìgbà tí mo máa ń pa ohun tó ń jẹ́ kí n mọ̀ pé lẹ́tà ti wọlé sórí fóònù mi. Ìyẹn ń jẹ́ kí n lè fi fóònù mi ṣe nǹkan míì, bíi kí n fi wo aago, láìjẹ́ pé mo tún yà bàrá sídìí iṣẹ́.”​—JASON ÀTI ALEXANDRA ÌYÀWÓ Ẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́