ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ| ÌGBÉYÀWÓ
Ohun Táwọn Tọkọtaya Àgbàlagbà Lè Máa Ṣe Tí Wọn Ò Fi Ní Kọra Wọn Sílẹ̀
Láàárín ọdún 1990 sí 2015, ìlọ́po méjì ni iye àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ ẹni àádọ́ta (50) ọdún sókè tí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀, ìlọ́po mẹ́ta sì ni ìkọ̀sílẹ̀ tó wáyé láàárín àwọn tó ti lé lẹ́ni ọdún márùndínláàádọ́rin (65) fi pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kí ló fà á táwọn àgbàlagbà fi ń kọ ara wọn sílẹ̀? Kí lo lè ṣe kí ìṣòro yìí má bàa tú ìgbéyàwó rẹ ká?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá mọ
Ohun tó ń fa ìkọ̀sílẹ̀ láàárín àwọn àgbàlagbà
Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa ń fà á táwọn tó ti dàgbà fi ń kọ ara wọn sílẹ̀ ní pe ìfẹ́ wọn ti ń dín kù díẹ̀díẹ̀ láìmọ̀. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọkàn àwọn tọkọtaya kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ohun míì tó yàtọ̀ sóhun tí wọ́n jọ máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, ìyẹn sì lè mú kọ́rọ̀ ẹnì kejì wọn má jẹ wọ́n lógún mọ́. Ó sì lè jẹ́ pé lẹ́yìn táwọn ọmọ ti kúrò nílé làwọn tọkọtaya kan ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń mọ̀ pé àwọn ti jìnnà síra àwọn. Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ló ti gbà wọ́n lọ́kàn látọdún yìí wá, wọn ò rí tara wọn rò.
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn táwọn èèyàn kà sí agbani-nímọ̀ràn nípa ìgbéyàwó máa ń sọ fáwọn tọkọtaya pé kí wọ́n máa ṣe ohun tó bá ti tẹ́ wọn lọ́rùn. Wọ́n wá ní káwọn tọkọtaya bi ara wọn pé: ‘Ṣé mò ń láyọ̀ nínú ìgbéyàwó mi?’ ‘Ṣé ó ń jẹ́ kí ìwà mi dáa sí i?’ ‘Ṣé ẹnì kejì mi rí tèmi rò, ṣé ó sì máa ń fìfẹ́ hàn sí mi?’ Àwọn èèyàn gbà pé táwọn ò bá lè dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yẹn, ohun tó yẹ káwọn ṣe ni pé káwọn kọ ẹnì kejì àwọn sílẹ̀, káwọn sì bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun.
Àwọn èèyàn ò ka ìkọ̀sílẹ̀ sí bàbàrà mọ́ lóde òní. Ọ̀gbẹ́ni Eric Klinenberg tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, kí tọkọtaya tó lè kọ ara wọn sílẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ sọ ohun fà á kí wọ́n sì tún ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ lónìí: Tó ò bá láyọ̀ nínú ìgbéyàwó ẹ mọ́, kò sídìí fún ẹ láti dúró torí ohun tọ́pọ̀ èèyàn gbà ni pé nǹkan tó máa fún ẹ láyọ̀ ló yẹ kó o máa ṣe.”a
Òótọ́ kan ni pé, tí tọkọtaya bá kọ ara wọn sílẹ̀, ńṣe ni wọ́n kàn máa ti inú ìṣòro kan bọ́ sí òmíì. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan fi hàn pé “àwọn àgbàlagbà tó máa ń kọ ara wọn sílẹ̀ sábà máa ń níṣòro owó, pàápàá àwọn obìnrin.”
Àmọ́ nǹkan míì wà tó yẹ ká ronú nípa ẹ̀. Ìwé kan tó ń jẹ́ Don’t Divorce sọ pé: “Bó o bá tiẹ̀ fẹ́ ẹlòmíì, ìyẹn ò yí irú ẹni tó o jẹ́ pa dà. Kí làwọn nǹkan tó o ti ṣe kí ọ̀rọ̀ ìwọ àti ẹnì kejì ẹ lè túbọ̀ máa yéra yín? Tí èdèkòyédè bá wáyé, àwọn nǹkan wo lo máa ń ṣe kẹ́ ẹ lè yanjú ẹ̀?”b
Bó ò ṣe ní jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí ẹ
Gbà pé nǹkan máa yí pa dà. Kò sí ìdílé tí nǹkan ò ti lè yí pa dà. Àjọṣe àárín ìwọ àti ẹnì kejì ẹ lè yí pa dà bóyá torí pé àwọn ọmọ yín ti kúrò nílé, tàbí kó jẹ́ pé ohun tẹ́yin méjèèjì nífẹ̀ẹ́ sí ti yàtọ̀ síra. Dípò tí wàá fi máa ronú pé bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀ sàn ju báyìí lọ, ńṣe ni kó o máa ro ohun tó o lè ṣe kí nǹkan lè dáa sí i.
Ìlànà Bíbélì: “Má sọ pé, “Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ àtijọ́ fi sàn ju ti ìgbà yìí lọ?” torí pé kì í ṣe ọgbọ́n ló mú kí o béèrè bẹ́ẹ̀.”—Oníwàásù 7:10.
Ẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ ara yín. Ṣé o lè gbìyànjú láti kọ́ ohun tí ẹnì kejì ẹ nífẹ̀ẹ́ sí, tàbí kó o ní kí òun wá kọ́ nǹkan tíwọ nífẹ̀ẹ́ sí? Ṣé ẹ lè jọ wáyè kọ́ nǹkan túntun tí ẹ̀yin méjèèjì nífẹ̀ẹ́ sí? Ohun tó yẹ kó jẹ ọ́ lógún ni bẹ́ ẹ ṣe máa wà pa pọ̀ kẹ́ ẹ sì máa gbádùn ara yín bíi tọkọtaya, kì í ṣe bíi pé ẹ kàn jọ ń gbélé.
Ìlànà Bíbélì: “Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.
Máa hùwà rere. Ti pé ẹ kì í ṣe àlejò ara yín mọ́ ò ní kẹ́ ẹ má hùwà tó máa pọ́n ara yín lé. Ẹ máa bá ara yín sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, kẹ́ ẹ sì gbìyànjú àtimáa ṣe àwọn nǹkan tẹ́ ẹ máa ń ṣe nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà. Ẹ máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ bíi “jọ̀ọ́” àti “o ṣeun.” Ẹ máa fìfẹ́ hàn síra yín, kẹ́ e sì máa fi hàn pé ẹ moore tí ẹnì kẹjì bá ṣe nǹkan kan tó dáa.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ onínúure sí ara yín, kí ẹ máa ṣàánú.”—Éfésù 4:32.
Máa rántí àwọn ìgbà tẹ́ ẹ ti gbádùn ara yín. Ẹ jọ máa wo àwọn fọ́tò ìgbéyàwó yín, tàbí àwọn fọ́tò míì tẹ́ ẹ jọ yà. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ yín á túbọ̀ lágbára, ẹ̀ẹ́ sì túbọ̀ mọyì ìgbéyàwó yín.
Ìlànà Bíbélì: “Kálukú yín gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; bákan náà, kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—Éfésù 5:33.
a Látinú ìwé náà, Going Solo—The Extraordinary Rise and Surprising Appeal of Living Alone.
b Ohun kan ṣoṣo tí Bíbélì sọ pé ó lè mú kí tọkọtaya kọra wọn sílẹ̀ ni ìṣekúṣe. (Mátíù 19:5, 6, 9) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ǹjẹ́ Bíbélì Fàyè Gba Ìkọ̀sílẹ̀?”