Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Náà Ṣeé Yanjú?
Ìwé “Couples in Crisis” sọ pé: “Ó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀ láìronújinlẹ̀, . . . síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ló yẹ kó kẹ́sẹ járí tó sì lè ṣàṣeyọrí bí wọ́n bá ti yanjú ìṣòro wọn.”
ÀKÍYÈSÍ yìí ṣọ̀kan pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí Jésù Kristi fi kọ́ni tipẹ́tipẹ́ nípa ìkọ̀sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sọ pé ẹni tó ṣe olóòótọ́ náà láǹfààní láti gba ìkọ̀sílẹ̀ látàrí ẹ̀sùn àìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó, kò sọ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pọndandan. (Mátíù 19:3-9) Ẹnì kejì tó ṣe olóòótọ́ náà lè ní ìdí tí kò fi ní fẹ́ kí ìgbéyàwó náà tú ká. Ẹni tó ṣàṣìṣe náà ṣì lè nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀.a Ó lè jẹ́ ọkọ tó bìkítà, kó sì jẹ́ bàbá tó ń pèsè fún àìní ìdílé rẹ̀ lójú méjèèjì. Bí ẹni tó ṣe olóòótọ́ náà bá ronú nípa àwọn àìní òun alára àti ti àwọn ọmọ rẹ̀, ó lè pinnu pé kí àwọn yanjú ọ̀rọ̀ náà dípò jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn kókó wo ni a lè gbé yẹ̀ wò, báwo ni a sì ṣe lè ṣàṣeyọrí ní kíkojú àwọn ìpèníjà tó wà nínú mímú ìgbéyàwó kan padà bọ̀ sípò?
Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ sọ ọ́ pé kò sí èyí tó rọrùn nínú jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀ tàbí yíyanjú ọ̀rọ̀ náà. Síwájú sí i, kò jọ pé wíwulẹ̀ dárí ji ẹni tó ṣe panṣágà yóò yanjú àwọn lájorí ìṣòro tó wà nínú ìgbéyàwó. Ó sábà máa ń gba wíwádìí ara rẹ lọ́nà tí ń dunni gan-an, sísọ ojú abẹ níkòó, àti iṣẹ́ àṣekára láti dáàbò bo ìgbéyàwó kan. Àwọn tọkọtaya sábà máa ń fojú kéré iye àkókò àti ìsapá tí yóò gbà láti mú kí ìgbéyàwó tó bà jẹ́ padà bọ̀ sípò. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti forí tì í, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé ìgbéyàwó wọn fẹsẹ̀ múlẹ̀.
Àwọn Ìbéèrè Tí A Ní Láti Dáhùn
Láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu, ẹni tó ṣe olóòótọ́ náà ní láti ṣàlàyé ìmọ̀lára rẹ̀ àti àwọn yíyàn tí ó lè ṣe. Ó lè gbé àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò: Ǹjẹ́ ó fẹ́ padà wá? Ṣé ó ti jáwọ́ pátápátá nínú ṣíṣèṣekúṣe pẹ̀lú obìnrin tọ̀ún, àbí ó ń lọ́ra láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní kánmọ́? Ǹjẹ́ ó ti tọrọ àforíjì? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ó ti ronú pìwà dà ní tòótọ́, kí ó sì kábàámọ̀ ohun tí ó ṣe? Àbí ṣé ó ń di ẹ̀bi àṣìṣe rẹ̀ rù mí ni? Ǹjẹ́ ó kẹ́dùn nítorí ìpalára tó fà ní ti gidi? Àbí, ó ha wulẹ̀ ń bínú pé a ti tú àṣírí àjọṣe aláìbófinmu òun tí a sì dà á rú bí?
Ọjọ́ iwájú ńkọ́? Ǹjẹ́ ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtúnṣe àwọn ìṣesí àti ìgbésẹ̀ tó tì í sí ṣíṣe panṣágà? Ǹjẹ́ ó ti pinnu ní tòótọ́ láti má ṣe jẹ́ kí àṣìṣe náà wáyé mọ́? Àbí ó ṣì ní ìtẹ̀sí láti máa tage kí ó sì tún kó wọnú ìdè ìmọ̀lára tí kò bófin mu pẹ̀lú ẹ̀yà kejì ni? (Mátíù 5:27, 28) Ǹjẹ́ ó wù ú lọ́kàn rẹ̀ pé kí a mú ìgbéyàwó náà padà bọ̀ sípò? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló ń ṣe nípa rẹ̀? Àwọn ìdáhùn títọ̀nà sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lè jẹ́ ohun tí yóò múni gbà gbọ́ pé ó ṣeé ṣe láti mú ìgbéyàwó náà padà bọ̀ sípò.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Tó Ṣe Pàtàkì
Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” (Òwe 15:22) Bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí gẹ́lẹ́ níyẹn bí ẹni tó ṣe olóòótọ́ náà bá lérò pé ó yẹ kí òun bá ẹnì kejì òun sọ̀rọ̀ nípa ìwà àìṣòótọ́ tó hù. Láìmẹ́nu kan àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó fara sin, wọ́n lè jọ finú konú lọ́nà tí yóò fi òtítọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ hàn kí ó sì mú àṣìlóye kúrò láìsí àbòsí. Nípa bẹ́ẹ̀, èyí kò ní jẹ́ kí tọkọtaya náà jìnnà síra wọn nítorí àṣìlóye àti ìkórìíra tó ti wà lọ́kàn tipẹ́tipẹ́. Lóòótọ́, irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ lè fa ìròra ọkàn fún tọkọtaya. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ti rí i pé wọ́n jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbésẹ̀ tí ń mú kí wọ́n tún lè gbẹ́kẹ̀ lé ara wọn lẹ́ẹ̀kan sí i.
Ìgbésẹ̀ pàtàkì mìíràn tó lè mú kí yíyanjú ọ̀rọ̀ náà ṣeé ṣe ni pé kí a gbìyànjú láti mọ àwọn apá ibi tí ìṣòro wà nínú ìgbéyàwó—ohun tí àwọn tọkọtaya lè ṣiṣẹ́ lé lórí. Zelda West-Meads gbani nímọ̀ràn pé: “Bí ẹ bá ti sọ̀rọ̀ dáadáa nípa ipò aronilára náà, tí ẹ bá ti pinnu pé àjọse ẹ̀yìn òde ìgbéyàwó náà ti parí, pé ẹ ṣì fẹ́ máa bá ìbátan lọ́kọláya yín lọ, ẹ wádìí ohun tó ṣẹlẹ̀ tó kù díẹ̀ káàtó, kí ẹ sì mú ìgbéyàwó [náà] padà bọ̀ sípò.”
Bóyá ńṣe ni ẹ kò ka ara yín kún. Ó lè jẹ́ pé ẹ ti pa àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tì. Bóyá ẹ kì í lo àkókò tó pọ̀ tó pa pọ̀. Bóyá o kò fi ìfẹ́, ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, iyìn, àti ọlá fún ẹnì kejì rẹ tó bó ṣe nílò rẹ̀. Ṣíṣàtúnyẹ̀wò àwọn góńgó àti ìwà ọmọlúwàbí yín pa pọ̀ yóò ṣe púpọ̀ láti mú kí ẹ túbọ̀ sún mọ́ra sí i, yóò sì ràn yín lọ́wọ́ láti dènà àìṣòótọ́ lọ́jọ́ iwájú.
Lílo Ìdáríjì
Bí ó ti wù kí ẹni tí a pa lára náà sapá gidigidi tó, ó lè má rọrùn fún un láti dárí ji ọkọ rẹ̀, ká máà wá sọ ti obìnrin tó bá ṣèṣekúṣe. (Éfésù 4:32) Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣeé ṣe láti máa gbégbèésẹ̀ díẹ̀díẹ̀ láti mú ìkórìíra àti ìbìnújẹ́ kíkorò kúrò lọ́kàn. Ìwé kan gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹnì kejì tó ṣe olóòótọ́ náà ní láti mọ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí wọ́n ní láti gbàgbé ọ̀rọ̀ náà. Ó ṣe pàtàkì láti má ṣe máa mẹ́nu kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kejì rẹ ti ṣẹ̀ sẹ́yìn fún ète àtifi dá [a] lára ní gbogbo ìgbà tí àríyànjiyàn bá ṣẹlẹ̀.”
Ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya ti rí i pé nípa sísapá láti dín ìbínú líle kù, kí wọ́n sì gbé e kúrò lọ́kàn, wọn kò tún ronú gbígbógun ti ẹlẹ́ṣẹ̀ náà mọ́ níkẹyìn. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ìgbésẹ̀ pàtàkì tí a lè gbà mú ìgbéyàwó kan padà bọ̀ sípò.
Kọ́ Láti Tún Fọkàn Tán An
Ìyàwó kan tí ìpayà bá béèrè tẹ̀dùntẹ̀dùn pé: “Ǹjẹ́ a tún lè fọkàn tán ara wa mọ́?” Àníyàn tó ní yìí bẹ́tọ̀ọ́ mu nítorí pé ìwà ẹ̀tàn tí onípanṣágà náà hù ti ba ìfọkàntánni náà jẹ́ pátápátá. Bí àgé òdòdó kan tó ṣeyebíye, ó rọrùn láti fọ́ ìfọkàntánni yángá ṣùgbọ́n ó ṣòro láti tún un ṣe. Ohun tó wà níbẹ̀ ni pé kí ipò ìbátan kan lè máa bá a lọ kí ó sì ní láárí, tọ̀túntòsì ní láti fọkàn tán ara wọn kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn.
Èyí sábà máa ń kan kíkọ́ láti tún fọkàn tán an. Dípò kí ẹni tó ṣàṣìṣe náà máa rinkinkin láìfìmọ̀lára hàn pé kí ẹnì kejì fọkàn tán òun, ó lè sapá láti tún ìfọkàntánni náà gbé ró nípa ṣíṣàìfi ohunkóhun bò nípa ìgbòkègbodò rẹ̀, kí ó má sì ṣàbòsí. A rọ àwọn Kristẹni láti ‘fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí wọ́n sì máa sọ òtítọ́’ pẹ̀lú ara wọn. (Éfésù 4:25) Kí a bàa lè tún máa fọkàn tán ọ lẹ́ẹ̀kan sí i, o lè bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe bí Zelda West-Meads ṣe sọ pé, “sísọ bí wàá ṣe máa rin ìrìn rẹ gẹ́lẹ́ fún [ẹnì kejì] rẹ. Máa dágbére ibi tí o ń lọ fún [ẹnì kejì] rẹ, máa sọ ìgbà tí wàá padà dé, sì rí i dájú pé ibi tí o dá gbére lo lọ.” Bí ìrìn rẹ bá yí padà, jẹ́ kó gbọ́ nípa rẹ̀.
Ó lè pẹ́ díẹ̀, ó sì lè gba ìsapá kí a tó lè ṣàtúnṣe iyì ara ẹni. Ẹni tó jẹ̀bi náà lè ṣèrànwọ́ nípa fífi ìfẹ́ni hàn fàlàlà kí ó sì máa yin aya rẹ̀—kí ó máa sọ fún un léraléra pé òun mọyì rẹ̀, òun sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Olùgbani-nímọ̀ràn nípa ìgbéyàwó tí a bọ̀wọ̀ fún kan sọ pé: “Ẹ yìn ín nítorí gbogbo ohun tó ṣe.” (Òwe 31:31, Today’s English Version) Aya náà lè ṣiṣẹ́ lórí títún ìgbẹ́kẹ̀lé ara ẹni ṣe nípa fífiyèsí àwọn ohun tó mọ̀ ọ́n ṣe dáradára nínú ìgbésí ayé rẹ̀.
O Máa Ń Pẹ́ Díẹ̀
Lójú bí ìrora ọkàn tí ìwà àìṣòótọ́ náà fà ti pọ̀ tó, kò yani lẹ́nu pé lẹ́yìn ọdún púpọ̀, a ṣì lè máa rántí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí gẹ́lẹ́, kí ó sì máa fa ìrora ọkàn. Ṣùgbọ́n bí ìpalára náà ṣe ń sàn díẹ̀díẹ̀, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, sùúrù, àti ìforítì yóò ran tọ̀túntòsì lọ́wọ́ láti tún máa fọkàn tán ara wọn, kí wọ́n sì máa fi ọ̀wọ̀ fún ara wọn.—Róòmù 5:3, 4; 1 Pétérù 3:8, 9.
Ìwé náà, To Love, Honour and Betray, tún mú un dáni lójú pé: “Ìrora ọkàn bíburú jáì tó máa ń báni ní àwọn oṣù díẹ̀ tó ṣáájú kì í tọ́jọ́. Yóò lọ pátápátá níkẹyìn . . . Wàá wá rí i níkẹyìn pé o lè lo ọ̀pọ̀ ọjọ́, ọ̀sẹ̀, oṣù, àti ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá láìronú nípa rẹ̀.” Bí o ti ń bá a lọ láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbéyàwó rẹ, tí o sì ń wá ìbùkún àti ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, kò sọ́gbọ́n tí o kò fi ní rí ipa tí ń tuni lára tó wà nínú “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—Fílípì 4:4-7, 9.
Pedro sọ pé: “Ní ríronú nípa ohun tó ti kọjá, ìrírí náà ti yí ipa ọ̀nà ìgbésí ayé wa padà. A sì ní láti máa ṣe àwọn àtúnṣe díẹ̀díẹ̀ nínú ìgbéyàwó wa lóòrèkóòrè. Ṣùgbọ́n a ti la ìrírí agbonijìgì náà já. A ṣì jẹ́ tọkọtaya. A sì láyọ̀.”
Àmọ́, bí kò bá sí ìdí fún ẹnì kejì tó ṣe olóòótọ́ náà láti dárí ji aláìṣòótọ́ náà ńkọ́? Àbí tó bá dárí ji ẹnì kejì rẹ̀ (débi tí kò fi bínú mọ́) ṣùgbọ́n tí ó ní ìdí pàtàkì láti yan àǹfààní tí Bíbélì fúnni láti jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ ńkọ́?b Kí ni ìkọ̀sílẹ̀ lè béèrè lọ́wọ́ ẹnì kan? A fẹ́ kí o gbé àwọn kókó pàtàkì tí ìkọ̀sílẹ̀ ní nínú yẹ̀ wò, àti bí àwọn kan ṣe kojú rẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti mú kí nǹkan rọrùn, a óò tọ́ka sí ẹni tó ṣe olóòótọ́ náà bí ìyàwó. Àmọ́, àwọn ìlànà tí a jíròrò kan ọkọ tó jẹ́ olóòótọ́ tí aya rẹ̀ jẹ́ aláìṣòótọ́.
b Jọ̀wọ́ wo àpilẹ̀kọ “Ojú Ìwòye Bíbélì: Panṣágà—Ṣé Kí N Dárí Jì Í Tàbí Kí N Máṣe Dárí Jì Í?” nínú Jí!, August 8, 1995.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
ÌTÌLẸ́YÌN TÓ GBÁMÚṢÉ
Níwọ̀n bí ohun púpọ̀ ti wà tí a lè gbé yẹ̀ wò, ó lè ṣàǹfààní láti wá ìrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn tó mọṣẹ́ tí kì í sì í ṣojúsàájú. Fún àpẹẹrẹ, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè bá àwọn alàgbà onínúure tí wọ́n sì jẹ́ oníyọ̀ọ́nú sọ̀rọ̀.—Jákọ́bù 5:13-15.
A máa ń rọ àwọn agbani-nímọ̀ràn, àwọn ọ̀rẹ́, àti àwọn ẹbí pé kí wọ́n má ṣe tẹnu mọ́ èrò tiwọn tàbí kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ gbe jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀ látàrí ohun tí Ìwé Mímọ́ wí tàbí ìlàjà, kí wọ́n má sì ṣe bẹnu àtẹ́ lù ú. Obìnrin Kristẹni kan tó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ rọni pé: “Ẹ ṣáà tì wá lẹ́yìn dáadáa, kí ẹ sì jẹ́ kí a pinnu ohun tí a ó ṣe fúnra wa.”
Orí Bíbélì ló yẹ kí a gbé ìṣílétí tí a fẹ́ fún wọn kà. Ẹnì kan tó jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ dábàá pé: “Ẹ má ṣe sọ fún wọn bó ṣe yẹ kí ìmọ̀lára wọn rí àti bí kò ṣe yẹ kó rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde.” Ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì, ìfẹ́ni ará, àti ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ yóò pẹ̀tù sí ọgbẹ́ burúkú tí ìwà ọ̀dàlẹ̀ nínú ìgbéyàwó náà fà. (1 Pétérù 3:8) Agbani-nímọ̀ràn kan tó mọṣẹ́ sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.”—Òwe 12:18.
Olóòótọ́ ọkọ kan sọ pé: “Lílóye ẹni, ọ̀rọ̀ ìtùnú, àti ìṣírí ni mo nílò lákòókò náà. Ìyàwó mi sì ń fẹ́ àwọn ìdarí tó ṣe pàtó àti ìyìn fún ìsapá rẹ̀—ìtìlẹ́yìn gidi tí kò ní jẹ́ kó bojú wẹ̀yìn.”
Lẹ́yìn tí ẹnì kan bá fẹ̀sọ̀ gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò, tó sì gbàdúrà nípa rẹ̀, tó bá wá pinnu láti jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ tàbí láti máà gbé pọ̀ pẹ̀lú ẹnì kejì mọ́ látàrí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, a kò gbọ́dọ̀ gba irú ẹni bẹ́ẹ̀ nímọ̀ràn lọ́nà tí yóò fi jọ pé a ń dẹ́bi fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè ran ẹni náà lọ́wọ́ láti borí ìmọ̀lára ẹ̀bi àìnídìí tó ń ní.
Ẹnì kan tí ọ̀ràn yìí ṣẹlẹ̀ sí sọ pé: “Bí o bá fẹ́ jẹ́ orísun ìtùnú tó gbámúṣé, má ṣe gbàgbé pé ọ̀ràn náà kan ìmọ̀lára ẹ̀dá lọ́nà tó lágbára.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
ÌDÍ TÍ ÀWỌN KAN ṢÌ FI Ń GBÉ PỌ̀
Ní àwọn àdúgbò púpọ̀, àwọn ìyàwó kan wà tí kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe àyàfi kí wọ́n jókòó ti ọkọ onípanṣágà tí kò ronú pìwà dà. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ìyàwó Kristẹni kan tí ń gbé àwọn àgbègbè tí gbọ́nmisi-omi-ò-to ti balẹ̀ jẹ́ tàbí tí owó iṣẹ́ kò tó nǹkan ti jókòó ti ọkọ kan tí ó jẹ́ aláìṣòótọ́ àmọ́ tí ó ń ṣe ojúṣe rẹ̀ fún agboolé rẹ̀ nínú àwọn ohun mìíràn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máà jẹ́ onígbàgbọ́. Ní àbáyọrí rẹ̀, wọ́n ní ilé, ààbò tó yẹ, owó tí ń wọlé déédéé, àti ìwọ̀nba ìfọ̀kànbalẹ̀ pé àwọn ní ọkọ nílé—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìṣòótọ́ ni. Wọ́n ti ronú pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé jíjókòó tì í kò tẹ́ wọn lọ́rùn, kò sì rọrùn, ó ti jẹ́ kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó dára gan-an ju bí ì bá ṣe rí ká ní wọ́n fẹ́ dàyà dé e láwọn nìkan pàápàá nínú ipò tí wọ́n wà.
Lẹ́yìn tí díẹ̀ lára àwọn ìyàwó wọ̀nyí bá ti forí ti irú ipò bẹ́ẹ̀—nígbà mìíràn fún ọ̀pọ̀ ọdún—ayọ̀ wọn máa ń kún gan-an nígbà tí àwọn ọkọ wọ́n bá yí padà níkẹyìn, tí wọ́n sì di Kristẹni ọkọ tó nífẹ̀ẹ́, tó sì ń ṣòótọ́.—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 7:12-16.
Nítorí náà, a kò gbọ́dọ̀ ṣe lámèyítọ́ àwọn tí wọ́n yàn láti jókòó ti ẹnì kejì wọn nínú ìgbéyàwó bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ronú pìwà dà. Ìpinnu tí wọ́n ṣe náà kò rọrùn, ó sì yẹ kí a ṣe gbogbo ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹ́yìn tí wọ́n bá nílò fún wọn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
TA LÓ LẸ̀BÍ?
Òtítọ́ ni pé nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, àìpé ẹnì kejì tó ṣe olóòótọ́ náà lè dá kún ìṣòro tó ṣẹlẹ̀ láàárín wọn, síbẹ̀, Bíbélì sọ pé, “olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú nǹkan ló lè fà á, “ìfẹ́-ọkàn” ẹnì kan “fúnra rẹ̀” ni lájorí ohun tó mú kó ṣe panṣágà. Bí àwọn àṣìṣe ẹnì kan nínú ìgbéyàwó bá ń dá àwọn ìṣòro sílẹ̀, dájúdájú, ṣíṣe panṣágà kọ́ ni a ó fi yanjú wọn.—Hébérù 13:4.
Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè yanjú àwọn ìṣòro tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó tí tọkọtaya bá ń bá a lọ ní fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Èyí ní “fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì” nínú. Ó yẹ kí wọ́n tún máa bá a lọ ní fífi àwọn ànímọ́ bí “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra” hàn. Ní pàtàkì jù lọ, ó yẹ kí wọ́n “fi ìfẹ́ wọ ara [wọn] láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:12-15.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Gbígbọ́ra ẹni yé lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ láti tún ìgbéyàwó wọn tò